Num 14:26-45

Num 14:26-45 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, Emi o ti mu sũru pẹ to fun ijọ enia buburu yi ti nkùn si mi? Emi ti gbọ́ kikùn awọn ọmọ Israeli, ti nwọn kùn si mi. Wi fun wọn pe, OLUWA wipe, Bi mo ti wà nitõtọ, bi ẹnyin ti sọ li etí mi, bẹ̃li emi o ṣe si nyin: Okú nyin yio ṣubu li aginjù yi; ati gbogbo awọn ti a kà ninu nyin, gẹgẹ bi iye gbogbo nyin, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jú bẹ̃ lọ, ti ẹ kùn si mi, Ẹnyin ki yio dé inu ilẹ na, ti mo ti bura lati mu nyin gbé inu rẹ̀, bikoṣe Kalebu ọmọ Jefunne, ati Joṣua ọmọ Nuni. Ṣugbọn awọn ọmọ wẹ́wẹ nyin, ti ẹnyin wipe yio di ijẹ, awọn li emi o muwọ̀ ọ, awọn ni yio si mọ̀ ilẹ na ti ẹnyin gàn. Ṣugbọn ẹnyin, okú nyin yio ṣubu li aginjú yi. Awọn ọmọ nyin yio si ma rìn kiri li aginjù li ogoji ọdún, nwọn o si ma rù ìwa-àgbere nyin, titi okú nyin yio fi ṣòfo tán li aginjù. Gẹgẹ bi iye ọjọ́ ti ẹnyin fi rìn ilẹ na wò, ani ogoji ọjọ́, ọjọ́ kan fun ọdún kan, li ẹnyin o rù ẹ̀ṣẹ nyin, ani ogoji ọdún, ẹnyin o si mọ̀ ibà ileri mi jẹ́. Emi OLUWA ti sọ, Emi o ṣe e nitõtọ si gbogbo ijọ buburu yi, ti nwọn kójọ pọ̀ si mi: li aginjù yi ni nwọn o run, nibẹ̀ ni nwọn o si kú si. Ati awọn ọkunrin na ti Mose rán lọ lati rìn ilẹ na wò, ti nwọn pada, ti nwọn si mu gbogbo ijọ kùn si i, ni mimú ìhin buburu ilẹ na wá, Ani awọn ọkunrin na ti o mú ìhin buburu ilẹ na wá, nwọn ti ipa àrun kú niwaju OLUWA. Ṣugbọn Joṣua ọmọ Nuni, ati Kalebu ọmọ Jefunne, ninu awọn ọkunrin na ti o rìn ilẹ na lọ, wà lãye. Mose si sọ ọ̀rọ wọnyi fun gbogbo awọn ọmọ Israeli: awọn enia na si kãnu gidigidi. Nwọn si dide ni kùtukutu owurọ̀, nwọn si gùn ori òke nì lọ, wipe, Kiyesi i, awa niyi, awa o si gòke lọ si ibiti OLUWA ti ṣe ileri: nitoripe awa ti ṣẹ̀. Mose si wipe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nre aṣẹ OLUWA kọja? kì yio sa gbè nyin. Ẹ máṣe gòke lọ, nitoriti OLUWA kò sí lãrin nyin, ki a má ba lù nyin bolẹ niwaju awọn ọtá nyin. Nitoriti awọn ara Amaleki ati awọn ara Kenaani mbẹ niwaju nyin, ẹnyin o si ti ipa idà ṣubu: nitoriti ẹnyin ti yipada kuro lẹhin OLUWA, nitorina OLUWA ki yio si pẹlu nyin. Ṣugbọn nwọn fi igberaga gòke lọ sori òke na: ṣugbọn apoti ẹrí OLUWA, ati Mose, kò jade kuro ni ibudò. Nigbana li awọn ara Amaleki sọkalẹ wá, ati awọn ara Kenaani ti ngbé ori-òke na, nwọn si kọlù wọn nwọn si ṣẹ́ wọn titi dé Horma.

Num 14:26-45 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé, “Yóo ti pẹ́ tó tí àwọn eniyan burúkú wọnyi yóo fi máa kùn sí mi? Mo ti gbọ́ gbogbo kíkùn tí wọn ń kùn sí mi. Nisinsinyii, sọ fún wọn pé, ‘Bí mo tì wà láàyè, n óo ṣe yín gẹ́gẹ́ bí ẹ ti wí. Ẹ óo kú ninu aṣálẹ̀ yìí; gbogbo yín; ohun tí ó ṣẹ̀ láti ẹni ogún ọdún lọ sókè, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kùn sí mi. Ẹnikẹ́ni ninu yín kò ní wọ ilẹ̀ tí mo ti búra pé yóo jẹ́ ibùgbé yín, àfi Kalebu ọmọ Jefune ati Joṣua, ọmọ Nuni. Ṣugbọn àwọn ọmọ yín tí ẹ sọ pé ogun yóo kó, ni n óo mú dé ilẹ̀ náà; ilẹ̀ tí ẹ kọ̀ sílẹ̀ yóo sì jẹ́ tiwọn. Ṣugbọn ní tiyín, ẹ ó kú ninu aṣálẹ̀ níhìn-ín. Àwọn ọmọ yín yóo rìn káàkiri ninu aṣálẹ̀ fún ogoji ọdún, gẹ́gẹ́ bí ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún aiṣododo yín, títí gbogbo yín yóo fi kú tán. Ẹ óo sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín fún ogoji ọdún. Ọdún kọ̀ọ̀kan yóo dípò ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ninu ogoji ọjọ́ tí àwọn amí fi wo ilẹ̀ náà. Ẹ óo rí ibinu mi. Mo ti ṣe ìlérí pé n óo ṣe àwọn nǹkan wọnyi sí ẹ̀yin eniyan burúkú, tí ẹ̀ ń lòdì sí mi wọnyi. Gbogbo yín ni yóo kú ninu aṣálẹ̀ yìí. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ” OLUWA bá mú àwọn tí Mose rán lọ wo ilẹ̀ náà tí wọ́n sì mú ìròyìn burúkú wá, àwọn tí wọ́n mú kí àwọn eniyan náà kùn sí Mose, ó bá fi àrùn burúkú pa wọ́n. Joṣua ọmọ Nuni ati Kalebu ọmọ Jefune nìkan ni wọ́n yè ninu àwọn amí mejila náà. Nígbà tí Mose sọ ohun tí OLUWA sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n káàánú gidigidi. Wọ́n bá gbéra ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, wọ́n lọ sí agbègbè olókè, wọ́n sì wí pé, “Nítòótọ́ a ti dẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn nisinsinyii a ti ṣetán láti lọ gba ilẹ̀ náà tí OLUWA ti sọ nípa rẹ̀ fún wa.” Mose dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe àìgbọràn sí àṣẹ OLUWA nisinsinyii? Ohun tí ẹ fẹ́ ṣe yìí kò ní yọrí sí rere. Ẹ má lọ nítorí OLUWA kò ní wà pẹlu yín, àwọn ọ̀tá yín yóo sì ṣẹgun yín. Ẹ óo kú nígbà tí ẹ bá ń bá àwọn ará Amaleki ati Kenaani jagun. OLUWA kò ní wà pẹlu yín nítorí pé ẹ ti ṣe àìgbọràn sí i.” Sibẹsibẹ àwọn eniyan náà lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Àpótí Majẹmu OLUWA tabi Mose kò kúrò ní ibùdó. Àwọn ará Amaleki ati Kenaani tí ń gbé ibẹ̀ bá wọn jagun, wọ́n ṣẹgun àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì lé wọn títí dé Horima.

Num 14:26-45 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

OLúWA sọ fún Mose àti Aaroni pé: “Báwo ni yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ìjọ ènìyàn búburú yìí yóò fi máa kùn sí mi? Mo ti gbọ́ kíkùn tí àwọn ọmọ Israẹli ń kùn sí mi. Sọ fún wọn, Bí mo ti wà láààyè nítòótọ́ ni OLúWA wí, gẹ́gẹ́ bí ohun tí ẹ wí létí mi ni èmi ó ṣe fún un yín. Nínú aginjù yìí ni ẹ ó kú sí, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kùn láti ọmọ ogún ọdún ó lé àní gbogbo ẹ̀yin tí a kà. Ọ̀kan nínú yín kò ní í dé ilẹ̀ tí mo búra nípa ìgbọ́wọ́sókè láti fi ṣe ibùgbé yín, bí kò ṣe Kalebu ọmọ Jefunne àti Joṣua ọmọ Nuni. Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ọmọ yín tí ẹ wí pé wọn ó di ìjẹ, àwọn ni n ó mú dé bẹ̀ láti gbádùn ilẹ̀ tí ẹ kọ̀sílẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, òkú yín yóò ṣubú ní aginjù yìí. Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ yín yóò sì máa rin kiri nínú aginjù fun ogójì ọdún (40) wọn ó máa jìyà nítorí àìnígbàgbọ́ yín, títí tí ọkàn gbogbo yín yóò fi ṣòfò tán ní aginjù. Fún ogójì ọdún èyí jẹ́ ọdún kan fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ogójì ọjọ́ tí ẹ fi yẹ ilẹ̀ náà wò ẹ̀yin ó sì jìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ ó sì mọ bí ó ti rí láti lòdì sí mi. Èmi, OLúWA, lo sọ bẹ́ẹ̀; Èmi ó sì ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí ìjọ ènìyàn búburú yìí tí wọ́n kó ra wọn jọ lòdì sí mi. Nínú aginjù yìí ni òpin yóò dé bá wọn, ibẹ̀ ni wọn yóò kú sí.” Àwọn ọkùnrin tí Mose rán láti yẹ ilẹ̀ wò, tí wọ́n sì mú gbogbo ìjọ kùn sí i nípa ìròyìn búburú tí wọ́n mú wá nípa ilẹ̀ náà; OLúWA sì kọlu àwọn ọkùnrin tó mú ìròyìn búburú wá nípa ilẹ̀ náà, àjàkálẹ̀-ààrùn sì pa wọ́n níwájú OLúWA. Nínú gbogbo àwọn tó lọ yẹ ilẹ̀ náà wò, Joṣua ọmọ Nuni àti Kalebu ọmọ Jefunne ló yè é. Nígbà tí Mose sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fún àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì sọkún gidigidi. Wọ́n dìde ní àárọ̀ ọjọ́ kejì wọ́n sì gòkè lọ sí ìlú orí òkè, wọ́n wí pé, “Àwa ti ṣẹ̀, Àwa yóò lọ sí ibi tí OLúWA ṣèlérí fún wa.” Mose sì dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ṣẹ̀ sí òfin OLúWA? Èyí kò le yọrí sí rere! Ẹ má ṣe gòkè lọ nítorí pé OLúWA kò sí láàrín yín. Ki á má ba à lù yín bolẹ̀ níwájú àwọn ọ̀tá yín. Nítorí pé àwọn ará Amaleki àti àwọn ará Kenaani ń bẹ níwájú yín, ẹ̀yin yóò sì ti ipa idà ṣubú. Nítorí pé, ẹ ti yà kúrò ní ọ̀nà OLúWA, OLúWA kò sì ní í wà pẹ̀lú yín.” Síbẹ̀síbẹ̀, pẹ̀lú àìfarabalẹ̀ wọn, wọ́n gòkè lọ sórí òkè náà, láìjẹ́ pé àpótí ẹ̀rí OLúWA tàbí Mose kúrò nínú ibùdó. Àwọn ará Amaleki àti àwọn ará Kenaani tó ń gbé lórí òkè sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n, wọ́n bá wọn jà, wọ́n sì lé wọn títí dé Horma.