Num 14:22-30
Num 14:22-30 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori gbogbo awọn enia wọnyi ti o ti ri ogo mi, ati iṣẹ-àmi mi, ti mo ti ṣe ni Egipti ati li aginjù, ti nwọn si dan mi wò nigba mẹwa yi, ti nwọn kò si fetisi ohùn mi; Nitõtọ nwọn ki yio ri ilẹ na ti mo ti fi bura fun awọn baba wọn, bẹ̃ni ọkan ninu awọn ti o gàn mi ki yio ri i: Ṣugbọn Kalebu iranṣẹ mi, nitoriti o ní ọkàn miran ninu rẹ̀, ti o si tẹle mi mọtimọti, on li emi o múlọ sinu ilẹ na nibiti o ti rè; irú-ọmọ rẹ̀ ni yio si ní i. Njẹ awọn ara Amaleki ati awọn ara Kenaani ngbé afonifoji: li ọla ẹ pada, ki ẹ si ṣi lọ si aginjù nipa ọ̀na Okun Pupa. OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, Emi o ti mu sũru pẹ to fun ijọ enia buburu yi ti nkùn si mi? Emi ti gbọ́ kikùn awọn ọmọ Israeli, ti nwọn kùn si mi. Wi fun wọn pe, OLUWA wipe, Bi mo ti wà nitõtọ, bi ẹnyin ti sọ li etí mi, bẹ̃li emi o ṣe si nyin: Okú nyin yio ṣubu li aginjù yi; ati gbogbo awọn ti a kà ninu nyin, gẹgẹ bi iye gbogbo nyin, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jú bẹ̃ lọ, ti ẹ kùn si mi, Ẹnyin ki yio dé inu ilẹ na, ti mo ti bura lati mu nyin gbé inu rẹ̀, bikoṣe Kalebu ọmọ Jefunne, ati Joṣua ọmọ Nuni.
Num 14:22-30 Yoruba Bible (YCE)
àwọn eniyan wọnyi, tí wọ́n ti rí ògo mi ati àwọn iṣẹ́ ìyanu tí mo ṣe ní Ijipti ati ninu aṣálẹ̀, ṣugbọn tí wọ́n ti dán mi wò nígbà mẹ́wàá, tí wọ́n sì ṣàìgbọràn sí mi, ẹnikẹ́ni ninu wọn kò ní dé ilẹ̀ tí mo ti ṣe ìlérí fún àwọn baba wọn. Ẹyọ kan ninu àwọn tí wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀ wọnyi kò ní débẹ̀. Ṣugbọn nítorí pé iranṣẹ mi, Kalebu, ní ẹ̀mí tí ó yàtọ̀, ó sì jẹ́ olóòótọ́ sí mi, n óo mú un dé ilẹ̀ tí ó lọ wò, ilẹ̀ náà yóo sì jẹ́ ti àwọn ọmọ rẹ̀. Nítorí pé àwọn Amaleki ati ará Kenaani ń gbé àfonífojì, ní ọ̀la, ẹ gbéra, kí ẹ gba ọ̀nà Òkun Pupa lọ sinu aṣálẹ̀.” OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé, “Yóo ti pẹ́ tó tí àwọn eniyan burúkú wọnyi yóo fi máa kùn sí mi? Mo ti gbọ́ gbogbo kíkùn tí wọn ń kùn sí mi. Nisinsinyii, sọ fún wọn pé, ‘Bí mo tì wà láàyè, n óo ṣe yín gẹ́gẹ́ bí ẹ ti wí. Ẹ óo kú ninu aṣálẹ̀ yìí; gbogbo yín; ohun tí ó ṣẹ̀ láti ẹni ogún ọdún lọ sókè, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kùn sí mi. Ẹnikẹ́ni ninu yín kò ní wọ ilẹ̀ tí mo ti búra pé yóo jẹ́ ibùgbé yín, àfi Kalebu ọmọ Jefune ati Joṣua, ọmọ Nuni.
Num 14:22-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn tó rí ògo mi àti àwọn iṣẹ́ ààmì tí mo ṣe ní ilẹ̀ Ejibiti àti nínú aginjù ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí mi, tí wọn sì dán mi wò ní ìgbà mẹ́wàá yìí, Ọ̀kan nínú wọn kò ní rí ilẹ̀ náà tí mo ṣe ìlérí ní ìbúra láti fún baba ńlá wọn. Kò sí ọ̀kan nínú àwọn tó kẹ́gàn mi tí yóò rí ilẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n nítorí pé Kalebu ìránṣẹ́ mi ní ẹ̀mí ọ̀tọ̀, tí ó sì tún tẹ̀lé mi tọkàntọkàn, èmi ó mu dé ilẹ̀ náà tó lọ yẹ̀ wò, irú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì jogún rẹ̀. Níwọ́n ìgbà tí àwọn ará Amaleki àti àwọn ará Kenaani ń gbé ní Àfonífojì, ẹ yípadà lọ́la kí ẹ sì dojúkọ aginjù lọ́nà Òkun Pupa.” OLúWA sọ fún Mose àti Aaroni pé: “Báwo ni yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ìjọ ènìyàn búburú yìí yóò fi máa kùn sí mi? Mo ti gbọ́ kíkùn tí àwọn ọmọ Israẹli ń kùn sí mi. Sọ fún wọn, Bí mo ti wà láààyè nítòótọ́ ni OLúWA wí, gẹ́gẹ́ bí ohun tí ẹ wí létí mi ni èmi ó ṣe fún un yín. Nínú aginjù yìí ni ẹ ó kú sí, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kùn láti ọmọ ogún ọdún ó lé àní gbogbo ẹ̀yin tí a kà. Ọ̀kan nínú yín kò ní í dé ilẹ̀ tí mo búra nípa ìgbọ́wọ́sókè láti fi ṣe ibùgbé yín, bí kò ṣe Kalebu ọmọ Jefunne àti Joṣua ọmọ Nuni.