Num 14:11-25

Num 14:11-25 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUWA si wi fun Mose pe, Awọn enia yi yio ti kẹgàn mi pẹ tó? yio si ti pẹ tó ti nwọn o ṣe alaigbà mi gbọ́, ni gbogbo iṣẹ-àmi ti mo ṣe lãrin wọn? Emi o fi ajakalẹ-àrun kọlù wọn, emi o si gbà ogún wọn lọwọ wọn, emi o si sọ iwọ di orilẹ-ède nla, ati alagbara jù wọn lọ. Mose si wi fun OLUWA pe, Ṣugbọn awọn ara Egipti yio gbọ́; nitoripe nipa agbara rẹ ni iwọ fi mú awọn enia yi jade lati inu wọn wá; Nwọn o si wi fun awọn ara ilẹ yi: nwọn sá ti gbọ́ pe iwọ OLUWA mbẹ lãrin awọn enia yi, nitoripe a ri iwọ OLUWA li ojukoju, ati pe awọsanma rẹ duro lori wọn, ati pe iwọ li o ṣaju wọn, ninu ọwọ̀n awọsanma nigba ọsán, ati ninu ọwọ̀n iná li oru. Njẹ bi iwọ ba pa gbogbo awọn enia yi bi ẹnikan, nigbana li awọn orilẹ-ède ti o ti gbọ́ okikí rẹ yio wipe, Nitoriti OLUWA kò le mú awọn enia yi dé ilẹ ti o ti fi bura fun wọn, nitorina li o ṣe pa wọn li aginjù. Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki agbara OLUWA ki o tobi, gẹgẹ bi iwọ ti sọ rí pe, Olupamọra ati ẹniti o pọ̀ li ãnu li OLUWA, ti ndari ẹ̀ṣẹ ati irekọja jì, ati bi o ti wù ki o ri, ti ki ijẹ ki ẹlẹbi lọ laijìya; a ma bẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn ọmọ, titi dé iran kẹta ati ẹkẹrin. Emi bẹ̀ ọ, dari ẹ̀ṣẹ awọn enia yi jì, gẹgẹ bi titobi ãnu rẹ, ati bi iwọ ti darijì awọn enia yi, lati Egipti titi di isisiyi. OLUWA si wipe, Emi ti darijì gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ: Ṣugbọn nitõtọ, bi mo ti wà, gbogbo aiye yio si kún fun ogo OLUWA; Nitori gbogbo awọn enia wọnyi ti o ti ri ogo mi, ati iṣẹ-àmi mi, ti mo ti ṣe ni Egipti ati li aginjù, ti nwọn si dan mi wò nigba mẹwa yi, ti nwọn kò si fetisi ohùn mi; Nitõtọ nwọn ki yio ri ilẹ na ti mo ti fi bura fun awọn baba wọn, bẹ̃ni ọkan ninu awọn ti o gàn mi ki yio ri i: Ṣugbọn Kalebu iranṣẹ mi, nitoriti o ní ọkàn miran ninu rẹ̀, ti o si tẹle mi mọtimọti, on li emi o múlọ sinu ilẹ na nibiti o ti rè; irú-ọmọ rẹ̀ ni yio si ní i. Njẹ awọn ara Amaleki ati awọn ara Kenaani ngbé afonifoji: li ọla ẹ pada, ki ẹ si ṣi lọ si aginjù nipa ọ̀na Okun Pupa.

Num 14:11-25 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA sọ fún Mose pé, “Àwọn eniyan wọnyi yóo ti kọ̀ mí sílẹ̀ pẹ́ tó. Yóo ti pẹ́ tó kí wọ́n tó máa gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrin wọn? N óo rán àjàkálẹ̀ àrùn láti pa gbogbo wọn run, n óo sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀, ṣugbọn n óo sọ ọ́ di baba orílẹ̀-èdè tí yóo pọ̀ ju àwọn wọnyi lọ, tí yóo sì lágbára jù wọ́n lọ.” Mose bá sọ fún OLUWA pé, “Ní ààrin àwọn ará Ijipti ni o ti mú àwọn eniyan wọnyi jáde pẹlu agbára. Nígbà tí wọn bá sì gbọ́ ohun tí o ṣe sí wọn, wọn yóo sọ fún àwọn eniyan tí ń gbé ilẹ̀ yìí. Àwọn eniyan wọnyi sì ti gbọ́ pé ìwọ OLUWA wà pẹlu wa ati pé à máa rí ọ ninu ìkùukùu nígbà tí o bá dúró lókè ibi tí a wà; nígbà tí o bá ń lọ níwájú wa ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu lọ́sàn-án, ati ninu ọ̀wọ̀n iná lóru. Nisinsinyii, bí o bá pa àwọn eniyan yìí bí ẹni tí ó pa ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo, àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti gbọ́ òkìkí rẹ yóo wí pé; o pa àwọn eniyan rẹ ninu aṣálẹ̀ nítorí pé o kò lè kó wọn dé ilẹ̀ tí o ti ṣèlérí fún wọn. Nítorí náà OLUWA, èmi bẹ̀ Ọ́, fi agbára ńlá rẹ hàn gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ pé, ‘OLUWA kì í tètè bínú, àánú rẹ̀ sì pọ̀. A máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ ati àìṣedéédé ji eniyan, ṣugbọn kì í jẹ́ kí ẹlẹ́bi lọ láìjìyà. A máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ títí dé ìran kẹta ati ikẹrin.’ Nisinsinyii OLUWA, mo bẹ̀ Ọ́, ro títóbi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, kí o dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan yìí jì wọ́n bí o ti ń dáríjì wọ́n láti ìgbà tí wọ́n ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.” OLUWA dáhùn pé, “Mo ti dáríjì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bẹ̀ rẹ. Ṣugbọn nítòótọ́, níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè, tí ògo mi sì kún ayé, àwọn eniyan wọnyi, tí wọ́n ti rí ògo mi ati àwọn iṣẹ́ ìyanu tí mo ṣe ní Ijipti ati ninu aṣálẹ̀, ṣugbọn tí wọ́n ti dán mi wò nígbà mẹ́wàá, tí wọ́n sì ṣàìgbọràn sí mi, ẹnikẹ́ni ninu wọn kò ní dé ilẹ̀ tí mo ti ṣe ìlérí fún àwọn baba wọn. Ẹyọ kan ninu àwọn tí wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀ wọnyi kò ní débẹ̀. Ṣugbọn nítorí pé iranṣẹ mi, Kalebu, ní ẹ̀mí tí ó yàtọ̀, ó sì jẹ́ olóòótọ́ sí mi, n óo mú un dé ilẹ̀ tí ó lọ wò, ilẹ̀ náà yóo sì jẹ́ ti àwọn ọmọ rẹ̀. Nítorí pé àwọn Amaleki ati ará Kenaani ń gbé àfonífojì, ní ọ̀la, ẹ gbéra, kí ẹ gba ọ̀nà Òkun Pupa lọ sinu aṣálẹ̀.”

Num 14:11-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

OLúWA sọ fún Mose pé, “Fún ìgbà wo ni àwọn ènìyàn yìí yóò ti kẹ́gàn mi tó? Báwo ni yóò ti pẹ́ tó tí wọ́n ó fi kọ̀ jálẹ̀ láti gbà mí gbọ́, pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ ààmì tí mo ṣe láàrín wọn? Èmi ó kọlù wọ́n pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn, èmi ó gba ogún wọn lọ́wọ́ wọn, èmi ó sì pa wọ́n run ṣùgbọ́n èmi ó sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá tó sì lágbára jù wọ́n lọ.” Ṣùgbọ́n Mose sọ fún OLúWA pé, “Nígbà náà ni àwọn ará Ejibiti yóò gbọ́; Nítorí pé nípa agbára rẹ ni ìwọ fi mú àwọn ènìyàn wọ̀nyí jáde kúrò láàrín wọn. Wọ́n ó sì sọ fún àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí. Àwọn tó ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé ìwọ OLúWA wà láàrín àwọn ènìyàn wọ̀nyí àti pé wọ́n rí ìwọ, OLúWA, ní ojúkojú, àti pé ìkùùkuu àwọsánmọ̀ rẹ dúró lórí wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì ń lọ níwájú wọn pẹ̀lú ìkùùkuu àwọsánmọ̀ ní ọ̀sán àti pẹ̀lú ọ̀wọ́n iná ní òru. Bí ìwọ bá pa àwọn ènìyàn wọ̀nyí lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, àwọn orílẹ̀-èdè tó bá gbọ́ ìròyìn yìí nípa rẹ yóò wí pé, ‘Nítorí pé OLúWA kò le è mú àwọn ènìyàn wọ̀nyí dé ilẹ̀ tí ó ṣèlérí fún wọn; torí èyí ló ṣe pa wọ́n sínú aginjù yìí.’ “Báyìí, mo gbàdúrà, jẹ́ kí agbára Olúwa tóbi gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti sọ pé: ‘OLúWA lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ tó dúró ṣinṣin, tí ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ àti ìrékọjá jì. Bẹ́ẹ̀ ni kì í jẹ́ kí ẹlẹ́bi lọ láìjìyà; tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ títí dé ìran kẹta àti ìran kẹrin.’ Dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn yìí jì wọ́n, mo bẹ̀ ọ́, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ńlá rẹ, bí o ti ṣe ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n láti ìgbà tí o ti kó wọn kúrò ní Ejibiti di ìsin yìí.” OLúWA sì dáhùn pé: “Mo ti dáríjì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ; Ṣùgbọ́n nítòótọ́ bí mo ti wà láààyè, gbogbo ayé yóò kún fún ògo OLúWA. Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn tó rí ògo mi àti àwọn iṣẹ́ ààmì tí mo ṣe ní ilẹ̀ Ejibiti àti nínú aginjù ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí mi, tí wọn sì dán mi wò ní ìgbà mẹ́wàá yìí, Ọ̀kan nínú wọn kò ní rí ilẹ̀ náà tí mo ṣe ìlérí ní ìbúra láti fún baba ńlá wọn. Kò sí ọ̀kan nínú àwọn tó kẹ́gàn mi tí yóò rí ilẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n nítorí pé Kalebu ìránṣẹ́ mi ní ẹ̀mí ọ̀tọ̀, tí ó sì tún tẹ̀lé mi tọkàntọkàn, èmi ó mu dé ilẹ̀ náà tó lọ yẹ̀ wò, irú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì jogún rẹ̀. Níwọ́n ìgbà tí àwọn ará Amaleki àti àwọn ará Kenaani ń gbé ní Àfonífojì, ẹ yípadà lọ́la kí ẹ sì dojúkọ aginjù lọ́nà Òkun Pupa.”