Num 14:1-24

Num 14:1-24 Bibeli Mimọ (YBCV)

GBOGBO ijọ si gbé ohùn wọn soke, nwọn si ke: awọn enia na si sọkun li oru na. Gbogbo awọn ọmọ Israeli si nkùn si Mose ati si Aaroni: gbogbo ijọ si wi fun wọn pe, Awa iba kuku ti kú ni ilẹ Egipti! tabi awa iba kú li aginjù yi! Nitori kini OLUWA ṣe mú wa wá si ilẹ yi, lati ti ipa idà ṣubu? Awọn aya wa, ati awọn ọmọ wa yio di ijẹ: kò ha san fun wa ki a pada lọ si Egipti? Nwọn si wi fun ara wọn pe, Ẹ jẹ ki a yàn olori, ki a si pada lọ si Egipti. Nigbana ni Mose ati Aaroni doju wọn bolẹ niwaju gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli. Ati Joṣua ọmọ Nuni ati Kalebu ọmọ Jefunne, ti o wà ninu awọn ti o ṣe amí ilẹ na, fà aṣọ wọn ya: Nwọn si sọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, wipe, Ilẹ na ti awa là já lati ṣe amí rẹ̀, ilẹ na dara gidigidi. Bi OLUWA ba fẹ́ wa, njẹ yio mú wa wọ̀ inu ilẹ na yi, yio si fi i fun wa; ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin. Ṣugbọn ẹ máṣe ṣọ̀tẹ si OLUWA, bẹ̃ni ki ẹ máṣe bẹ̀ru awọn enia ilẹ na; nitoripe onjẹ wa ni nwọn; àbo wọn ti fi wọn silẹ, OLUWA si wà pẹlu wa: ẹ máṣe bẹ̀ru wọn. Gbogbo ijọ si wipe ki a sọ wọn li okuta. Ṣugbọn ogo OLUWA hàn ninu agọ́ ajọ niwaju gbogbo awọn ọmọ Israeli. OLUWA si wi fun Mose pe, Awọn enia yi yio ti kẹgàn mi pẹ tó? yio si ti pẹ tó ti nwọn o ṣe alaigbà mi gbọ́, ni gbogbo iṣẹ-àmi ti mo ṣe lãrin wọn? Emi o fi ajakalẹ-àrun kọlù wọn, emi o si gbà ogún wọn lọwọ wọn, emi o si sọ iwọ di orilẹ-ède nla, ati alagbara jù wọn lọ. Mose si wi fun OLUWA pe, Ṣugbọn awọn ara Egipti yio gbọ́; nitoripe nipa agbara rẹ ni iwọ fi mú awọn enia yi jade lati inu wọn wá; Nwọn o si wi fun awọn ara ilẹ yi: nwọn sá ti gbọ́ pe iwọ OLUWA mbẹ lãrin awọn enia yi, nitoripe a ri iwọ OLUWA li ojukoju, ati pe awọsanma rẹ duro lori wọn, ati pe iwọ li o ṣaju wọn, ninu ọwọ̀n awọsanma nigba ọsán, ati ninu ọwọ̀n iná li oru. Njẹ bi iwọ ba pa gbogbo awọn enia yi bi ẹnikan, nigbana li awọn orilẹ-ède ti o ti gbọ́ okikí rẹ yio wipe, Nitoriti OLUWA kò le mú awọn enia yi dé ilẹ ti o ti fi bura fun wọn, nitorina li o ṣe pa wọn li aginjù. Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki agbara OLUWA ki o tobi, gẹgẹ bi iwọ ti sọ rí pe, Olupamọra ati ẹniti o pọ̀ li ãnu li OLUWA, ti ndari ẹ̀ṣẹ ati irekọja jì, ati bi o ti wù ki o ri, ti ki ijẹ ki ẹlẹbi lọ laijìya; a ma bẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn ọmọ, titi dé iran kẹta ati ẹkẹrin. Emi bẹ̀ ọ, dari ẹ̀ṣẹ awọn enia yi jì, gẹgẹ bi titobi ãnu rẹ, ati bi iwọ ti darijì awọn enia yi, lati Egipti titi di isisiyi. OLUWA si wipe, Emi ti darijì gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ: Ṣugbọn nitõtọ, bi mo ti wà, gbogbo aiye yio si kún fun ogo OLUWA; Nitori gbogbo awọn enia wọnyi ti o ti ri ogo mi, ati iṣẹ-àmi mi, ti mo ti ṣe ni Egipti ati li aginjù, ti nwọn si dan mi wò nigba mẹwa yi, ti nwọn kò si fetisi ohùn mi; Nitõtọ nwọn ki yio ri ilẹ na ti mo ti fi bura fun awọn baba wọn, bẹ̃ni ọkan ninu awọn ti o gàn mi ki yio ri i: Ṣugbọn Kalebu iranṣẹ mi, nitoriti o ní ọkàn miran ninu rẹ̀, ti o si tẹle mi mọtimọti, on li emi o múlọ sinu ilẹ na nibiti o ti rè; irú-ọmọ rẹ̀ ni yio si ní i.

Num 14:1-24 Yoruba Bible (YCE)

Gbogbo àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí ké, wọn sì fi gbogbo òru ọjọ́ náà sọkún. Gbogbo wọn ń kùn sí Mose ati Aaroni pé, “Ó sàn fún wa kí á kúkú kú sí Ijipti tabi ní aṣálẹ̀ yìí. Kí ló dé tí OLUWA fi ń mú wa lọ sí ilẹ̀ náà kí àwọn ọ̀tá wa lè pa wá, kí wọ́n sì kó àwọn aya ati àwọn ọmọ wa lẹ́rú. Ǹjẹ́ kò ní sàn fún wa kí á pada sí Ijipti?” Wọ́n sọ fún ara wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á yan olórí, kí á pada sí Ijipti.” Mose ati Aaroni bá dojúbolẹ̀ níwájú àwọn eniyan náà. Joṣua ọmọ Nuni ati Kalebu ọmọ Jefune tí wọ́n wà lára àwọn amí fa aṣọ wọn ya láti fi ìbànújẹ́ wọn hàn. Wọ́n sọ fún ìjọ eniyan Israẹli pé, “Ilẹ̀ tí a lọ wò náà jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára lọpọlọpọ. Bí inú OLUWA bá dùn sí wa, yóo mú wa dé ilẹ̀ náà, yóo sì fún wa; àní ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati fún oyin, ilẹ̀ ọlọ́ràá tí ó lẹ́tù lójú. Ẹ má lòdì sí OLUWA, ẹ má sì bẹ̀rù àwọn eniyan tí ń gbé ilẹ̀ náà. A óo ṣẹgun wọn, nítorí kò sí ààbò fún wọn mọ́. OLUWA wà pẹlu wa, ẹ má bẹ̀rù.” Bí àwọn eniyan náà ti ń gbèrò láti sọ wọ́n lókùúta pa ni wọ́n rí i tí ògo OLUWA fara hàn ní Àgọ́ Àjọ. OLUWA sọ fún Mose pé, “Àwọn eniyan wọnyi yóo ti kọ̀ mí sílẹ̀ pẹ́ tó. Yóo ti pẹ́ tó kí wọ́n tó máa gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrin wọn? N óo rán àjàkálẹ̀ àrùn láti pa gbogbo wọn run, n óo sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀, ṣugbọn n óo sọ ọ́ di baba orílẹ̀-èdè tí yóo pọ̀ ju àwọn wọnyi lọ, tí yóo sì lágbára jù wọ́n lọ.” Mose bá sọ fún OLUWA pé, “Ní ààrin àwọn ará Ijipti ni o ti mú àwọn eniyan wọnyi jáde pẹlu agbára. Nígbà tí wọn bá sì gbọ́ ohun tí o ṣe sí wọn, wọn yóo sọ fún àwọn eniyan tí ń gbé ilẹ̀ yìí. Àwọn eniyan wọnyi sì ti gbọ́ pé ìwọ OLUWA wà pẹlu wa ati pé à máa rí ọ ninu ìkùukùu nígbà tí o bá dúró lókè ibi tí a wà; nígbà tí o bá ń lọ níwájú wa ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu lọ́sàn-án, ati ninu ọ̀wọ̀n iná lóru. Nisinsinyii, bí o bá pa àwọn eniyan yìí bí ẹni tí ó pa ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo, àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti gbọ́ òkìkí rẹ yóo wí pé; o pa àwọn eniyan rẹ ninu aṣálẹ̀ nítorí pé o kò lè kó wọn dé ilẹ̀ tí o ti ṣèlérí fún wọn. Nítorí náà OLUWA, èmi bẹ̀ Ọ́, fi agbára ńlá rẹ hàn gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ pé, ‘OLUWA kì í tètè bínú, àánú rẹ̀ sì pọ̀. A máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ ati àìṣedéédé ji eniyan, ṣugbọn kì í jẹ́ kí ẹlẹ́bi lọ láìjìyà. A máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ títí dé ìran kẹta ati ikẹrin.’ Nisinsinyii OLUWA, mo bẹ̀ Ọ́, ro títóbi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, kí o dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan yìí jì wọ́n bí o ti ń dáríjì wọ́n láti ìgbà tí wọ́n ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.” OLUWA dáhùn pé, “Mo ti dáríjì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bẹ̀ rẹ. Ṣugbọn nítòótọ́, níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè, tí ògo mi sì kún ayé, àwọn eniyan wọnyi, tí wọ́n ti rí ògo mi ati àwọn iṣẹ́ ìyanu tí mo ṣe ní Ijipti ati ninu aṣálẹ̀, ṣugbọn tí wọ́n ti dán mi wò nígbà mẹ́wàá, tí wọ́n sì ṣàìgbọràn sí mi, ẹnikẹ́ni ninu wọn kò ní dé ilẹ̀ tí mo ti ṣe ìlérí fún àwọn baba wọn. Ẹyọ kan ninu àwọn tí wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀ wọnyi kò ní débẹ̀. Ṣugbọn nítorí pé iranṣẹ mi, Kalebu, ní ẹ̀mí tí ó yàtọ̀, ó sì jẹ́ olóòótọ́ sí mi, n óo mú un dé ilẹ̀ tí ó lọ wò, ilẹ̀ náà yóo sì jẹ́ ti àwọn ọmọ rẹ̀.

Num 14:1-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Gbogbo ìjọ ènìyàn sì gbóhùn sókè, wọ́n sì sọkún ní òru ọjọ́ náà. Gbogbo ọmọ Israẹli sì kùn sí Mose àti Aaroni, gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli sì wí fún wọn pé; “Àwa ìbá kúkú ti kú ní ilẹ̀ Ejibiti. Tàbí kí a kúkú kú sínú aginjù yìí. Kí ló dé tí OLúWA fi mú wa wá sí ilẹ̀ yìí láti fi idà pa wá? Àwọn ìyàwó wa, àwọn ọmọ wa yóò sì di ìjẹ. Ǹjẹ́ kò wa, ní í dára fún wa bí a bá padà sí Ejibiti?” Wọ́n sì sọ fún ara wọn pé “Ẹ jẹ́ kí á yan olórí kí á sì padà sí Ejibiti.” Nígbà náà ni Mose àti Aaroni dojúbolẹ̀ níwájú gbogbo ìjọ ọmọ Israẹli. Joṣua ọmọ Nuni àti Kalebu ọmọ Jefunne, tí wọ́n wà lára àwọn to lọ yẹ ilẹ̀ wò sì fa aṣọ wọn ya. Wọ́n sì sọ fún gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli pé, “Ilẹ̀ tí a là kọjá láti yẹ̀ wò náà jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀. Bí inú OLúWA bá dùn sí wa, yóò mú wa dé ilẹ̀ náà, ilẹ̀ tó ń sàn fún wàrà àti fún oyin, yóò fún wa ní ilẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí OLúWA. Kí ẹ sì má bẹ̀rù àwọn ènìyàn ìlú náà, nítorí pé a ó gbé wọn mì, ààbò wọn ti fi wọ́n sílẹ̀, OLúWA sì wà pẹ̀lú àwa, Ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn.” Ṣùgbọ́n gbogbo ìjọ ènìyàn sì ń sọ pé àwọn yóò sọ wọ́n lókùúta pa. Nígbà náà ni ògo OLúWA fi ara hàn ní àgọ́ ìpàdé níwájú àwọn ọmọ Israẹli. OLúWA sọ fún Mose pé, “Fún ìgbà wo ni àwọn ènìyàn yìí yóò ti kẹ́gàn mi tó? Báwo ni yóò ti pẹ́ tó tí wọ́n ó fi kọ̀ jálẹ̀ láti gbà mí gbọ́, pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ ààmì tí mo ṣe láàrín wọn? Èmi ó kọlù wọ́n pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn, èmi ó gba ogún wọn lọ́wọ́ wọn, èmi ó sì pa wọ́n run ṣùgbọ́n èmi ó sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá tó sì lágbára jù wọ́n lọ.” Ṣùgbọ́n Mose sọ fún OLúWA pé, “Nígbà náà ni àwọn ará Ejibiti yóò gbọ́; Nítorí pé nípa agbára rẹ ni ìwọ fi mú àwọn ènìyàn wọ̀nyí jáde kúrò láàrín wọn. Wọ́n ó sì sọ fún àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí. Àwọn tó ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé ìwọ OLúWA wà láàrín àwọn ènìyàn wọ̀nyí àti pé wọ́n rí ìwọ, OLúWA, ní ojúkojú, àti pé ìkùùkuu àwọsánmọ̀ rẹ dúró lórí wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì ń lọ níwájú wọn pẹ̀lú ìkùùkuu àwọsánmọ̀ ní ọ̀sán àti pẹ̀lú ọ̀wọ́n iná ní òru. Bí ìwọ bá pa àwọn ènìyàn wọ̀nyí lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, àwọn orílẹ̀-èdè tó bá gbọ́ ìròyìn yìí nípa rẹ yóò wí pé, ‘Nítorí pé OLúWA kò le è mú àwọn ènìyàn wọ̀nyí dé ilẹ̀ tí ó ṣèlérí fún wọn; torí èyí ló ṣe pa wọ́n sínú aginjù yìí.’ “Báyìí, mo gbàdúrà, jẹ́ kí agbára Olúwa tóbi gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti sọ pé: ‘OLúWA lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ tó dúró ṣinṣin, tí ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ àti ìrékọjá jì. Bẹ́ẹ̀ ni kì í jẹ́ kí ẹlẹ́bi lọ láìjìyà; tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ títí dé ìran kẹta àti ìran kẹrin.’ Dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn yìí jì wọ́n, mo bẹ̀ ọ́, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ńlá rẹ, bí o ti ṣe ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n láti ìgbà tí o ti kó wọn kúrò ní Ejibiti di ìsin yìí.” OLúWA sì dáhùn pé: “Mo ti dáríjì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ; Ṣùgbọ́n nítòótọ́ bí mo ti wà láààyè, gbogbo ayé yóò kún fún ògo OLúWA. Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn tó rí ògo mi àti àwọn iṣẹ́ ààmì tí mo ṣe ní ilẹ̀ Ejibiti àti nínú aginjù ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí mi, tí wọn sì dán mi wò ní ìgbà mẹ́wàá yìí, Ọ̀kan nínú wọn kò ní rí ilẹ̀ náà tí mo ṣe ìlérí ní ìbúra láti fún baba ńlá wọn. Kò sí ọ̀kan nínú àwọn tó kẹ́gàn mi tí yóò rí ilẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n nítorí pé Kalebu ìránṣẹ́ mi ní ẹ̀mí ọ̀tọ̀, tí ó sì tún tẹ̀lé mi tọkàntọkàn, èmi ó mu dé ilẹ̀ náà tó lọ yẹ̀ wò, irú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì jogún rẹ̀.