Num 14:1-10

Num 14:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Gbogbo ìjọ ènìyàn sì gbóhùn sókè, wọ́n sì sọkún ní òru ọjọ́ náà. Gbogbo ọmọ Israẹli sì kùn sí Mose àti Aaroni, gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli sì wí fún wọn pé; “Àwa ìbá kúkú ti kú ní ilẹ̀ Ejibiti. Tàbí kí a kúkú kú sínú aginjù yìí. Kí ló dé tí OLúWA fi mú wa wá sí ilẹ̀ yìí láti fi idà pa wá? Àwọn ìyàwó wa, àwọn ọmọ wa yóò sì di ìjẹ. Ǹjẹ́ kò wa, ní í dára fún wa bí a bá padà sí Ejibiti?” Wọ́n sì sọ fún ara wọn pé “Ẹ jẹ́ kí á yan olórí kí á sì padà sí Ejibiti.” Nígbà náà ni Mose àti Aaroni dojúbolẹ̀ níwájú gbogbo ìjọ ọmọ Israẹli. Joṣua ọmọ Nuni àti Kalebu ọmọ Jefunne, tí wọ́n wà lára àwọn to lọ yẹ ilẹ̀ wò sì fa aṣọ wọn ya. Wọ́n sì sọ fún gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli pé, “Ilẹ̀ tí a là kọjá láti yẹ̀ wò náà jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀. Bí inú OLúWA bá dùn sí wa, yóò mú wa dé ilẹ̀ náà, ilẹ̀ tó ń sàn fún wàrà àti fún oyin, yóò fún wa ní ilẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí OLúWA. Kí ẹ sì má bẹ̀rù àwọn ènìyàn ìlú náà, nítorí pé a ó gbé wọn mì, ààbò wọn ti fi wọ́n sílẹ̀, OLúWA sì wà pẹ̀lú àwa, Ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn.” Ṣùgbọ́n gbogbo ìjọ ènìyàn sì ń sọ pé àwọn yóò sọ wọ́n lókùúta pa. Nígbà náà ni ògo OLúWA fi ara hàn ní àgọ́ ìpàdé níwájú àwọn ọmọ Israẹli.