Num 13:3-6
Num 13:3-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mose si rán wọn lati ijù Parani lọ, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA: gbogbo awọn ọkunrin na jẹ́ olori awọn ọmọ Israeli. Orukọ wọn si ni wọnyi: ninu ẹ̀ya Reubeni, Ṣammua ọmọ Sakuru. Ninu ẹ̀ya Simeoni, Ṣafati ọmọ Hori. Ninu ẹ̀ya Juda, Kalebu ọmọ Jefunne.
Pín
Kà Num 13Num 13:3-6 Yoruba Bible (YCE)
Mose bá rán àwọn ọkunrin tí wọ́n jẹ́ olórí ninu ẹ̀yà wọn lọ, láti aṣálẹ̀ Parani. Orúkọ wọn nìwọ̀nyí: láti inú ẹ̀yà Reubẹni, ó rán Ṣamua ọmọ Sakuri; láti inú ẹ̀yà Simeoni, ó rán Ṣafati ọmọ Hori; láti inú ẹ̀yà Juda, ó rán Kalebu, ọmọ Jefune
Pín
Kà Num 13Num 13:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mose sì rán wọn jáde láti Aginjù Parani gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLúWA. Gbogbo wọn jẹ́ olórí àwọn ènìyàn Israẹli. Orúkọ wọn nìwọ̀nyí: láti inú ẹ̀yà Reubeni Ṣammua ọmọ Sakkuri; láti inú ẹ̀yà Simeoni, Ṣafati ọmọ Hori; láti inú ẹ̀yà Juda, Kalebu ọmọ Jefunne
Pín
Kà Num 13