Num 13:1-3
Num 13:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si sọ fun Mose pe, Rán enia, ki nwọn ki o si ṣe amí ilẹ Kenaani, ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli: ọkunrin kan ni ki ẹnyin ki o rán ninu ẹ̀ya awọn baba wọn, ki olukuluku ki o jẹ́ ijoye ninu wọn. Mose si rán wọn lati ijù Parani lọ, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA: gbogbo awọn ọkunrin na jẹ́ olori awọn ọmọ Israeli.

Num 13:1-3 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA sọ fún Mose pé, “Rán amí lọ wo ilẹ̀ Kenaani tí mo fún àwọn ọmọ Israẹli. Ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó bá jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ni kí o rán.” Mose bá rán àwọn ọkunrin tí wọ́n jẹ́ olórí ninu ẹ̀yà wọn lọ, láti aṣálẹ̀ Parani.
Num 13:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA sọ fún Mose pé, “Rán ènìyàn díẹ̀ láti lọ yẹ ilẹ̀ Kenaani wò èyí tí mo ti fún àwọn ọmọ Israẹli. Rán ẹnìkọ̀ọ̀kan, tí ó jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.” Mose sì rán wọn jáde láti Aginjù Parani gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLúWA. Gbogbo wọn jẹ́ olórí àwọn ènìyàn Israẹli.