Num 12:1-3
Num 12:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
A TI Miriamu ati Aaroni sọ̀rọ òdi si Mose nitori obinrin ara Etiopia ti o gbé ni iyawo: nitoripe o gbé obinrin ara Etiopia kan ni iyawo. Nwọn si wipe, Nipa Mose nikan ni OLUWA ha sọ̀rọ bi? kò ha ti ipa wa sọ̀rọ pẹlu? OLUWA si gbọ́ ọ. Ṣugbọn ọkunrin na Mose, o ṣe ọlọkàn tutù jù gbogbo enia lọ ti mbẹ lori ilẹ.
Num 12:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Miriamu ati Aaroni sọ̀rọ̀ òdì sí Mose nítorí pé ó fẹ́ ọmọbinrin ará Kuṣi ní iyawo. Wọn ń wí pé, “Ṣé Mose nìkan ni OLUWA ti lò láti bá eniyan sọ̀rọ̀ ni? Ṣé kò ti lo àwa náà rí?” OLUWA sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tí wọn ń sọ. Mose ni ó jẹ́ oníwà ìrẹ̀lẹ̀ jù ninu gbogbo ẹni tí ó wà láyé.
Num 12:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Miriamu àti Aaroni sọ̀rọ̀-òdì sí Mose nítorí pé ó fẹ́ obìnrin ará Etiopia. Wọ́n sì wí pé, “Nípa Mose nìkan ni OLúWA ti sọ̀rọ̀ bí, kò ha ti ipa wa sọ̀rọ̀ bí?” OLúWA sì gbọ́ èyí. (Mose sì jẹ́ ọlọ́kàn tútù ju gbogbo ènìyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé lọ).