Num 12:1-16

Num 12:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)

A TI Miriamu ati Aaroni sọ̀rọ òdi si Mose nitori obinrin ara Etiopia ti o gbé ni iyawo: nitoripe o gbé obinrin ara Etiopia kan ni iyawo. Nwọn si wipe, Nipa Mose nikan ni OLUWA ha sọ̀rọ bi? kò ha ti ipa wa sọ̀rọ pẹlu? OLUWA si gbọ́ ọ. Ṣugbọn ọkunrin na Mose, o ṣe ọlọkàn tutù jù gbogbo enia lọ ti mbẹ lori ilẹ. OLUWA si sọ fun Mose, ati fun Aaroni, ati fun Miriamu li ojiji pe, Ẹnyin mẹtẹta ẹ jade wá si agọ́ ajọ. Awọn mẹtẹta si jade. OLUWA si sọkalẹ wá ninu ọwọ̀n awọsanma, o si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ na, o si pè Aaroni ati Miriamu: awọn mejeji si jade wá. O si wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ mi nisisiyi: bi wolĩ OLUWA ba mbẹ ninu nyin, emi OLUWA yio farahàn fun u li ojuran, emi o si bá a sọ̀rọ li oju-alá. Mose iranṣẹ mi kò ri bẹ̃, olõtọ ni ninu gbogbo ile mi. On li emi mbá sọ̀rọ li ẹnu ko ẹnu, ati ni gbangba, ki si iṣe li ọ̀rọ ti o ṣe òkunkun; apẹrẹ OLUWA li on o si ri: njẹ nitori kili ẹnyin kò ṣe bẹ̀ru lati sọ̀rọ òdi si Mose iranṣẹ mi? Ibinu OLUWA si rú si wọn; o si lọ. Awọsanma si lọ kuro lori Agọ́ na; si kiyesi i, Miriamu di adẹ̀tẹ, o fun bi òjo didì; Aaroni si wò Miriamu, si kiyesi i, o di adẹ̀tẹ. Aaroni si wi fun Mose pe, Yẽ, oluwa mi, emi bẹ̀ ọ, máṣe kà ẹ̀ṣẹ na si wa lọrùn, eyiti awa fi wère ṣe, ati eyiti awa ti dẹ̀ṣẹ. Emi bẹ̀ ọ máṣe jẹ ki o dabi ẹniti o kú, ẹniti àbọ ara rẹ̀ run tán nigbati o ti inu iya rẹ̀ jade. Mose si kigbe pè OLUWA, wipe, Ọlọrun, emi bẹ̀ ọ, mu u lara dá nisisiyi. OLUWA si wi fun Mose pe, Bi baba rẹ̀, tilẹ tu itọ si i li oju, njẹ oju ki ba tì i ni ijọ́ meje? Ki a sé e mọ́ ẹhin ibudó ni ijọ́ meje, lẹhin eyinì ki a gbà a sinu rẹ̀. A si sé Miriamu mọ́ ẹhin ibudó ni ijọ́ meje: awọn enia kò si ṣí titi a fi gbà Miriamu pada. Lẹhin eyinì li awọn enia si ṣí kuro ni Haserotu, nwọn si dó si ijù Parani.

Num 12:1-16 Yoruba Bible (YCE)

Miriamu ati Aaroni sọ̀rọ̀ òdì sí Mose nítorí pé ó fẹ́ ọmọbinrin ará Kuṣi ní iyawo. Wọn ń wí pé, “Ṣé Mose nìkan ni OLUWA ti lò láti bá eniyan sọ̀rọ̀ ni? Ṣé kò ti lo àwa náà rí?” OLUWA sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tí wọn ń sọ. Mose ni ó jẹ́ oníwà ìrẹ̀lẹ̀ jù ninu gbogbo ẹni tí ó wà láyé. Lójijì, OLUWA sọ fún Mose, Aaroni, ati Miriamu pé, “Ẹ wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.” OLUWA sì dúró ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu, ó sì pe Aaroni ati Miriamu, àwọn mejeeji sì jáde siwaju. OLUWA sì sọ fún wọn pé, “Ẹ gbọ́ ohun tí n óo sọ yìí: Nígbà tí àwọn wolii wà láàrin yín, èmi a máa fi ara hàn wọ́n ninu ìran, èmi a sì máa bá wọn sọ̀rọ̀ lójú àlá. Ṣugbọn ti Mose, iranṣẹ mi yàtọ̀. Mo ti fi ṣe alákòóso àwọn eniyan mi. Lojukooju ni èmi í máa bá a sọ̀rọ̀; ọ̀rọ̀ ketekete sì ni, kì í ṣe àdììtú ọ̀rọ̀. Kódà, òun a máa rí ìrísí OLUWA. Kí ló dé tí ẹ kò fi bẹ̀rù ati sọ̀rọ̀ òdì sí i?” Inú sì bí OLUWA sí àwọn mejeeji, ó sì kúrò lọ́dọ̀ wọn. Bí ọ̀wọ̀n ìkùukùu tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ ti gbéra sókè ni ẹ̀tẹ̀ bo Miriamu, ó sì funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Nígbà tí Aaroni wo Miriamu ó ri wí pé ó ti di adẹ́tẹ̀. Aaroni sì wí fún Mose pe, “Olúwa mi, jọ̀wọ́ má jẹ́ kí á jìyà ẹ̀ṣẹ̀ ìwà àìgbọ́n wa. Má jẹ́ kí ó dàbí ọmọ tí ó ti kú kí á tó bí i, tí apákan ara rẹ̀ sì ti jẹrà.” Mose ké pe Ọlọrun kí ó wò ó sàn. OLUWA sì dáhùn pé, “Bí baba rẹ̀ bá tutọ́ sí i lójú, ṣé ìtìjú rẹ̀ kò ha ní wà lára rẹ̀ fún ọjọ́ meje ni? Nítorí náà, jẹ́ kí wọ́n fi sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọ̀sẹ̀ kan, lẹ́yìn náà, kí wọ́n mú un pada.” Wọ́n sì fi Miriamu sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ meje, àwọn eniyan náà kò sì kúrò níbẹ̀ títí di ìgbà tí wọ́n mú un pada. Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣí kúrò ni Haserotu, wọ́n sì pa àgọ́ wọn sí aṣálẹ̀ Parani.

Num 12:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Miriamu àti Aaroni sọ̀rọ̀-òdì sí Mose nítorí pé ó fẹ́ obìnrin ará Etiopia. Wọ́n sì wí pé, “Nípa Mose nìkan ni OLúWA ti sọ̀rọ̀ bí, kò ha ti ipa wa sọ̀rọ̀ bí?” OLúWA sì gbọ́ èyí. (Mose sì jẹ́ ọlọ́kàn tútù ju gbogbo ènìyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé lọ). Lẹ́ẹ̀kan náà ni OLúWA sọ fún Mose, Aaroni àti Miriamu pé, “Ẹ̀yin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, jáde wá sínú àgọ́ ìpàdé.” Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì jáde síta. Nígbà náà ni OLúWA sọ̀kalẹ̀ nínú ọ̀wọ́n ìkùùkuu, ó sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, ó ké sí Aaroni àti Miriamu. Àwọn méjèèjì sì bọ́ síwájú, Ó wí pé, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi: “Bí wòlíì OLúWA bá wà láàrín yín Èmi OLúWA a máa fi ara à mi hàn án ní ojúran, Èmi a máa bá a sọ̀rọ̀ nínú àlá. Ṣùgbọ́n èyí kò rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Mose ìránṣẹ́ mi: ó jẹ́ olóòtítọ́ nínú gbogbo ilé mi. Mo sì ń bá a sọ̀rọ̀ ní ojúkojú, ọ̀rọ̀ yékéyéké tí kì í ṣe òwe, ó rí àwòrán OLúWA Kí ló wá dé tí ẹ̀yin kò ṣe bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀-òdì sí Mose ìránṣẹ́ mi?” Ìbínú OLúWA sì ru sókè sí wọn OLúWA sì fi wọ́n sílẹ̀. Nígbà tí ìkùùkuu kúrò lórí àgọ́ lójijì ni Miriamu di adẹ́tẹ̀, ó funfun bí i yìnyín. Aaroni sì padà wo Miriamu ó sì rí i pé ó ti di adẹ́tẹ̀, Aaroni sì wí fún Mose pé, “Jọ̀wọ́ olúwa mi, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀, èyí tí a fi ìwà òmùgọ̀ dá sí wa lọ́rùn. Má ṣe jẹ́ kí ó dàbí òkú ọmọ tí a bí, tí ìdajì ara rẹ̀ ti rà dànù.” Torí èyí Mose sì kígbe sí OLúWA, “ỌLọ́RUN, jọ̀wọ́, mú un láradá!” OLúWA sì dá Mose lóhùn, “Bí baba rẹ̀ bá tutọ́ sí i lójú, ojú kò wa ní í tì í fún ọjọ́ méje? Dá a dúró sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ méje, lẹ́yìn èyí ki a tó ó le mú wọlé.” Miriamu sì dúró sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ méje, àwọn ènìyàn kò sì tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò wọn títí tí Miriamu fi wọ inú ibùdó padà. Lẹ́yìn èyí, àwọn ènìyàn kúrò ní Haserotu, wọ́n sì pa ibùdó sí Aginjù Parani.