Num 11:24-30
Num 11:24-30 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mose si jade lọ, o si sọ ọ̀rọ OLUWA fun awọn enia: o si pe ãdọrin ọkunrin ninu awọn àgba enia jọ, o si mu wọn duro yi agọ́ ká. OLUWA si sọkalẹ wá ninu awọsanma, o si bá a sọ̀rọ, o si mú ninu ẹmi ti o wà lara rẹ̀, o si fi i sara awọn ãdọrin àgba na: o si ṣe, nigbati ẹmi na bà lé wọn, nwọn sì sọtẹlẹ ṣugbọn nwọn kò ṣe bẹ̃ mọ́. Ṣugbọn o kù meji ninu awọn ọkunrin na ni ibudó, orukọ ekini a ma jẹ́ Eldadi, orukọ ekeji Medadi: ẹmi na si bà lé wọn; nwọn si mbẹ ninu awọn ti a kà, ṣugbọn nwọn kò jade lọ si agọ́: nwọn si nsọtẹlẹ ni ibudó. Ọmọkunrin kan si súre, o si sọ fun Mose, o si wipe, Eldadi ati Medadi nsọtẹlẹ ni ibudó. Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ Mose, ọkan ninu awọn ọmọkunrin rẹ̀ dahùn, o si wipe, Mose oluwa mi, dá wọn lẹkun. Mose si wi fun u pe, Iwọ njowú nitori mi? gbogbo enia OLUWA iba le jẹ́ wolĩ, ki OLUWA ki o fi ẹmi rẹ̀ si wọn lara! Mose si lọ si ibudó, on ati awọn àgba Israeli.
Num 11:24-30 Yoruba Bible (YCE)
Mose jáde, ó lọ sọ ohun tí OLUWA sọ fún àwọn ọmọ Israẹli; ó sì mú àwọn aadọrin olórí náà wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. OLUWA sọ̀kalẹ̀ ninu ìkùukùu láti bá Mose sọ̀rọ̀. Ó sì mú lára ẹ̀mí tí ó wà lára Mose, ó fi sára àwọn aadọrin olórí náà. Bí ẹ̀mí náà ti bà lé wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀, ṣugbọn wọn kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ mọ́ lẹ́yìn ọjọ́ náà. Meji ninu àwọn olórí náà: Elidadi ati Medadi, kò bá wọn lọ, wọ́n dúró sinu àgọ́ wọn. Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé wọn, wọ́n sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀. Ọmọkunrin kan sáré wá sọ fún Mose pé Elidadi ati Medadi ń sọ àsọtẹ́lẹ̀. Nígbà náà ni Joṣua, ọmọ Nuni, iranṣẹ Mose, ọ̀kan ninu àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ wí fún Mose pé, “Pa wọ́n lẹ́nu mọ́.” Mose dáhùn pé, “Kí ló dé tí o fi ń jowú nítorí mi? Inú mi ìbá dùn bí OLUWA bá lè fún gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ ní ẹ̀mí rẹ̀ kí wọ́n sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀.” Lẹ́yìn náà Mose ati àwọn aadọrin olórí náà pada sí ibùdó.
Num 11:24-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mose sì jáde, ó sọ ohun tí OLúWA wí fún àwọn ènìyàn. Ó mú àwọn àádọ́rin (70) àgbàgbà Israẹli dúró yí àgọ́ ká. Nígbà náà ni OLúWA sọ̀kalẹ̀ nínú ìkùùkuu ó sì bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì mú lára Ẹ̀mí tó wà lára Mose sí ara àwọn àádọ́rin (70) àgbàgbà náà, Ó sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Ẹ̀mí náà bà lé wọn, wọ́n sọtẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí wọn kò sọtẹ́lẹ̀ mọ́. Àwọn ọkùnrin méjì, tí orúkọ wọn ń jẹ́ Eldadi àti Medadi kò kúrò nínú àgọ́. Orúkọ wọn wà lára àádọ́rin (70) àgbàgbà yìí ṣùgbọ́n wọn kò jáde nínú àgọ́ síbẹ̀ Ẹ̀mí náà bà lé wọn, wọ́n sì sọtẹ́lẹ̀ nínú àgọ́. Ọmọkùnrin kan sì sáré lọ sọ fún Mose pé, “Eldadi àti Medadi ń sọtẹ́lẹ̀ nínú àgọ́.” Joṣua ọmọ Nuni tí í ṣe ìránṣẹ́ Mose, láti kékeré tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ dáhùn pé, “Mose olúwa mi, dá wọn lẹ́kun!” Mose sì wí fún un pé, “Àbí ìwọ ń jowú nítorí mi? Ìbá ti wù mí tó, kí gbogbo àwọn ènìyàn OLúWA jẹ́ wòlíì, kí OLúWA sì fi Ẹ̀mí rẹ̀ sí wọn lára!” Mose àti àwọn àgbàgbà Israẹli yìí sì padà sínú àgọ́.