Num 11:1-3
Num 11:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
AWỌN enia na nṣe irahùn, nwọn nsọ ohun buburu li etí OLUWA: nigbati OLUWA si gbọ́ ọ, ibinu rẹ̀ si rú; iná OLUWA si ràn ninu wọn, o si run awọn ti o wà li opin ibudó na. Awọn enia na si kigbe tọ̀ Mose lọ; nigbati Mose si gbadura si OLUWA, iná na si rẹlẹ. O si pè orukọ ibẹ̀ na ni Tabera: nitoriti iná OLUWA jó lãrin wọn.
Num 11:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó yá àwọn eniyan náà bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí OLUWA nípa ìṣòro wọn. Nígbà tí OLUWA gbọ́ kíkùn wọn, inú bí i, ó sì fi iná jó wọn; iná náà run gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní òpin ibùdó náà. Àwọn eniyan náà sì ké tọ Mose wá fún ìrànlọ́wọ́. Mose gbadura fún wọn, iná náà sì kú. Wọ́n pe orúkọ ibẹ̀ ní Tabera, nítorí níbẹ̀ ni iná OLUWA ti jó láàrin wọn.
Num 11:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ènìyàn ń ṣe àròyé nípa wàhálà wọn sí etí ìgbọ́ OLúWA. Ìbínú OLúWA sì ru sókè nígbà tí ó gbọ́ àròyé yìí, Nígbà náà ni iná jáde láti ọ̀dọ̀ OLúWA bọ́ sí àárín wọn, ó sì run àwọn tó wà ní òpin ibùdó. Nígbà náà ni àwọn ènìyàn kígbe sí Mose, Mose sì gbàdúrà sí OLúWA iná náà sì kú. Wọ́n sì ń pe ibẹ̀ ní Tabera nítorí pé, iná láti ọ̀dọ̀ OLúWA jó láàrín wọn.