Num 10:1-10

Num 10:1-10 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA sọ fún Mose pé, “Fi fadaka tí wọ́n fi òòlù lù ṣe fèrè meji fún pípe àwọn ọmọ Israẹli jọ ati títú ibùdó palẹ̀. Nígbà tí àwọn afọnfèrè bá fọn fèrè mejeeji, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli yóo wá sọ́dọ̀ rẹ ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé fèrè kan ni wọ́n fọn, àwọn olórí ẹ̀yà Israẹli nìkan ni yóo wá sọ́dọ̀ rẹ. Nígbà tí ẹ bá kọ́ fọn fèrè ìdágìrì, àwọn tí wọ́n pa àgọ́ sí ìhà ìlà oòrùn Àgọ́ yóo ṣí, wọn yóo sì tẹ̀síwájú. Bí ẹ bá fọn fèrè ìdágìrì lẹẹkeji, àwọn tí wọ́n pàgọ́ sí ìhà gúsù yóo ṣí, wọn yóo sì tẹ̀síwájú. Ìgbàkúùgbà tí ẹ bá fẹ́ tẹ̀síwájú ni kí ẹ máa fọn fèrè ìdágìrì. Nígbà tí ẹ bá fẹ́ pe àwọn ọmọ Israẹli jọ ẹ óo máa fọn fèrè, ṣugbọn kò ní jẹ́ ti ìdágìrì. Àwọn alufaa, ọmọ Aaroni ni yóo máa fọn fèrè náà. “Fèrè yìí yóo sì jẹ́ ìlànà fún ìrandíran yín. Nígbà tí ẹ bá ń lọ bá àwọn ọ̀tá yín jà lójú ogun láti gba ara yín lọ́wọ́ àwọn tí ń ni yín lára, ẹ óo fọn fèrè ìdágìrì. OLUWA Ọlọrun yín yóo sì ranti yín, yóo sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín. Ẹ óo máa fọn àwọn fèrè náà ní ọjọ́ ayọ̀, ní àwọn ọjọ́ àjọ̀dún yín ati ní ọjọ́ kinni oṣù. Ẹ óo máa fọn wọ́n nígbà tí ẹ bá mú ọrẹ ẹbọ sísun ati ọrẹ ẹbọ alaafia yín wá fún Ọlọrun. Yóo jẹ́ àmì ìrántí fun yín níwájú Ọlọrun yín. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.”

Num 10:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

OLúWA sọ fún Mose pé: Ṣe fèrè fàdákà méjì pẹ̀lú fàdákà lílù, kí o máa lò ó láti máa fi pe ìjọ ènìyàn àti láti máa fi darí ìrìnàjò lọ sí ibùdó yín. Nígbà tí o bá fọn méjèèjì gbogbo ìjọ ènìyàn yóò pé síwájú rẹ ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. Bí ó bá jẹ́ ọ̀kan ni o fọn, nígbà náà ni àwọn olórí ẹ̀yà Israẹli yóò péjọ síwájú rẹ. Nígbà tí o bá fun ìpè ìdágìrì, àwọn ẹ̀yà tó pa ibùdó sí ìhà ìlà-oòrùn ni yóò gbéra. Nígbà tí o bá fun ìpè ìdágìrì kejì, ibùdó tó wà ní ìhà gúúsù ni yóò gbéra. Ìpè ìdágìrì yìí ni yóò jẹ́ ààmì fún gbígbéra. Nígbà tí o bá fẹ́ pe ìjọ ènìyàn jọ, fun fèrè nìkan, má ṣe fun ti ìdágìrì pẹ̀lú rẹ̀. “Àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ni kí ó máa fun fèrè. Èyí yóò jẹ́ ìlànà láéláé fún yín àti fún ìran tó ń bọ̀. Nígbà tí ẹ bá lọ jagun pẹ̀lú àwọn ọ̀tá tó ń ni yín lára ní ilẹ̀ yín, ẹ fun ìpè ìdágìrì pẹ̀lú fèrè. A ó sì rántí yín níwájú OLúWA, Ọlọ́run yín yóò sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín. Bẹ́ẹ̀ náà ni ní ọjọ́ ayọ̀ yín, ní gbogbo àjọ̀dún tí a yàn àti ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yín, ni kí ẹ máa fun fèrè lórí ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà yín, wọn yóò sì jẹ́ ìrántí fún yín níwájú Ọlọ́run. Èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín.”