Num 1:1-2
Num 1:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si sọ fun Mose ni ijù Sinai, ninu agọ́ ajọ, li ọjọ́ kini oṣù keji, li ọdún keji, ti nwọn jade lati ilẹ Egipti wá, wipe, Ẹ kaye gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, olukuluku ọkunrin, nipa ori wọn
Num 1:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kinni oṣù keji, ní ọdún keji tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, OLUWA sọ fún Mose ninu Àgọ́ Àjọ, tí ó wà ninu aṣálẹ̀ Sinai, pé, “Ẹ ka iye àwọn ọmọ Israẹli, ní agbo-ilé agbo-ilé, ati ìdílé-ìdílé; kí ẹ sì kọ orúkọ gbogbo àwọn ọkunrin sílẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.
Num 1:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA bá Mose sọ̀rọ̀ ní aginjù Sinai nínú àgọ́ àjọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì ní ọdún kejì tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ó wí pé: “Ka gbogbo àgbájọ ènìyàn Israẹli nípa ẹbí wọn, àti nípa ìdílé baba wọn, to orúkọ wọn olúkúlùkù ọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.