Neh 9:34 - Compare All Versions

Neh 9:34 YBCV (Bibeli Mimọ)

Awọn ọba wa, awọn ijoye wa, awọn alufa wa, ati awọn baba wa, kò pa ofin rẹ mọ, bẹ̃ni nwọn kò fi eti si aṣẹ rẹ, ati ẹri rẹ, ti iwọ fi jẹri gbè wọn.

Neh 9:34 YCE (Yoruba Bible)

Àwọn ọba wa, ati àwọn ìjòyè wa, àwọn alufaa wa ati àwọn baba wa kọ̀, wọn kò pa òfin rẹ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tẹ̀lé ìlànà rẹ, wọn kò sì gbọ́ ìkìlọ̀ rẹ. Pẹlu, bí àwọn nǹkan rere tí o fún wọn ti pọ̀ tó, lórí ilẹ̀ tí ó tóbi tí ó sì dára tí o fún wọn.

Neh 9:34 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Àwọn ọba wa, àwọn olórí wa, àwọn àlùfáà wa, àti àwọn baba wa kò tẹ̀lé òfin rẹ; wọn kò fetísílẹ̀ sí àṣẹ rẹ tàbí àwọn ìkìlọ̀ tí ìwọ fún wọn.