Neh 6:15-16 - Compare All Versions

Neh 6:15-16 YBCV (Bibeli Mimọ)

Bẹ̃li a pari odi na li ọjọ kẹ̃dọgbọn oṣù Eluli, ni ọjọ mejilelãdọta. O si ṣe, nigbati gbogbo awọn ọta wa gbọ́, gbogbo awọn keferi àgbegbe wa si bẹ̀ru, nwọn si rẹ̀wẹsi pupọ li oju ara wọn, nitori nwọn woye pe, lati ọwọ Ọlọrun wá li a ti ṣe iṣẹ wọnyi.

Neh 6:15-16 YCE (Yoruba Bible)

A mọ odi náà parí ní ọjọ́ kẹẹdọgbọn oṣù Eluli. Ó gbà wá ní ọjọ́ mejilelaadọta. Nígbà tí àwọn ọ̀tá wa, ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká gbọ́ nípa rẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n, ìtìjú sì mú wọn, nítorí wọ́n mọ̀ pé nípa ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun ni iṣẹ́ náà fi ṣeéṣe.

Neh 6:15-16 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Bẹ́ẹ̀ ni a parí odi náà ní ọjọ́ kẹẹdọ́gbọ̀n oṣù Eluli, láàrín ọjọ́ méjìléláàádọ́ta. Nígbà tí àwọn ọ̀tá wa gbọ́ èyí, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká bẹ̀rù jìnnìjìnnì sì mú wọn, nítorí wọ́n wòye pé iṣẹ́ yìí di ṣíṣe pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run wa.