Neh 6:1-9

Neh 6:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)

O SI ṣe, nigbati Sanballati, ati Tobiah, ati Geṣemu, ara Arabia, ati awọn ọta wa iyokù, gbọ́ pe, mo ti mọ odi na, ati pe, kò kù ibi yiya kan ninu rẹ̀, (bi emi kò tilẹ iti gbe ilẹkùn wọnni ro ni ibode li akoko na;) Ni Sanballati ati Geṣemu ranṣẹ si mi, wipe, Wá, jẹ ki a jọ pade ninu ọkan ninu awọn ileto ni pẹtẹlẹ Ono. Ṣugbọn nwọn ngbero ati ṣe mi ni ibi. Mo si ran onṣẹ si wọn pe, Emi nṣe iṣẹ nla kan, emi kò le sọkalẹ wá: ẽṣe ti iṣẹ na yio fi duro nigbati mo ba fi i silẹ, ti mo ba si sọkalẹ tọ̀ nyin wá? Sibẹ nwọn ranṣẹ si mi nigba mẹrin bayi; mo si da wọn lohùn bakanna. Nigbana ni Sanballati rán ọmọ-ọdọ rẹ̀ si mi bakanna nigba karun ti on ti iwe ṣíṣi lọwọ rẹ̀. Ninu rẹ̀ li a kọ pe, A nrohin lãrin awọn keferi, Gaṣimu si wi pe, iwọ ati awọn ara Juda rò lati ṣọ̀tẹ: nitori idi eyi ni iwọ ṣe mọ odi na, ki iwọ le jẹ ọba wọn, gẹgẹ bi ọ̀rọ wọnyi. Iwọ pẹlu si ti yan awọn woli lati kede rẹ ni Jerusalemu wipe, Ọba wà ni Juda: nisisiyi ni a o si rò o fun ọba gẹgẹ bi ọ̀rọ wọnyi. Njẹ wá nisisiyi, ki a jọ gbimọ̀ pọ̀. Nigbana ni mo ranṣẹ si i wipe, A kò ṣe iru eyi, ti iwọ sọ, ṣugbọn iwọ rò wọn li ọkàn ara rẹ ni. Nitori gbogbo wọn mu wa bẹ̀ru, wipe, Ọwọ wọn yio rọ ninu iṣẹ na, ki a má le ṣe e. Njẹ nisisiyi, Ọlọrun, mu ọwọ mi le.

Neh 6:1-9 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí wọ́n sọ fún Sanbalati ati Tobaya ati Geṣemu ará Arabia ati àwọn ọ̀tá wa yòókù pé a ti tún odi náà mọ, ati pé kò sí àlàfo kankan mọ́ (lóòótọ́ n kò tíì ṣe ìlẹ̀kùn sí àwọn ẹnubodè). Sanbalati ati Geṣemu ranṣẹ sí mi, wọ́n ní “Wá, jẹ́ kí á pàdé ní ọ̀kan ninu àwọn ìletò tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ono.” Ṣugbọn wọ́n ti pète láti ṣe mí ní ibi. Mo bá ranṣẹ pada sí wọn pé, mò ń ṣe iṣẹ́ pataki kan lọ́wọ́, kò ní jẹ́ kí n lè wá. Kò sì ní yẹ kí n dá iṣẹ́ náà dúró nítorí àtiwá rí wọn. Ìgbà mẹrin ni wọ́n ranṣẹ pè mí bẹ́ẹ̀, èsì kan náà sì ni mo fún wọn ní ìgbà mẹrẹẹrin. Ní ìgbà karun-un, Sanbalati rán iranṣẹ rẹ̀ kan sí mi, ó kọ lẹta ṣugbọn kò fi òǹtẹ̀ lu lẹta náà. Ohun tí ó kọ sinu lẹta náà ni pé: “A fi ẹ̀sùn kàn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, Geṣemu náà sì jẹ́rìí sí i pé, ìwọ ati àwọn Juu ń pète láti dìtẹ̀, nítorí náà ni ẹ fi ń mọ odi yín. Ìwọ ni o sì ń gbèrò láti jọba lé wọn lórí, ati pé o tilẹ̀ ti yan àwọn wolii láti máa kéde nípa rẹ ní Jerusalẹmu pé, ‘Ọba kan wà ní Juda.’ Ó pẹ́ ni, ó yá ni, ọba yóo gbọ́ ìròyìn yìí. Nítorí náà, wá kí á jọ jíròrò nípa ọ̀rọ̀ náà.” Mo ranṣẹ pada sí i pé, “Ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rárá, o kàn sọ ohun tí o rò lọ́kàn ara rẹ ni.” Nítorí pé gbogbo wọn fẹ́ dẹ́rù bà wá, wọ́n lérò pé a óo jáwọ́ kúrò ninu iṣẹ́ náà, a kò sì ní lè parí rẹ̀ mọ́. Ṣugbọn adura mi nisinsinyii ni, “Kí Ọlọrun, túbọ̀ fún mi ní okun.”

Neh 6:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí Sanballati, Tobiah Geṣemu ará Arabia àti àwọn ọ̀tá wa tókù gbọ́ pé, mo ti tún odi náà mọ, kò sì sí àlàfo kankan tí ó ṣẹ́kù nínú rẹ̀—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò ì tí ì ri àwọn ìlẹ̀kùn ibodè ní àkókò náà. Sanballati àti Geṣemu rán iṣẹ́ yìí sí mi pé: “Wá jẹ́ kí a jọ pàdé pọ̀ nínú ọ̀kan lára àwọn ìletò ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ono.” Ṣùgbọ́n wọ́n ń gbèrò láti ṣe mí ní ibi; Bẹ́ẹ̀ ni mo rán oníṣẹ́ padà pẹ̀lú èsì yìí pé; “Èmi ń ṣe iṣẹ́ ńlá kan, èmi kò le è sọ̀kalẹ̀ wá. Èéṣe tí iṣẹ́ náà yóò fi dúró, nígbà tí mo bá fi í sílẹ̀ tí mo sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá?” Wọ́n rán iṣẹ́ náà sí mi nígbà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, mo sì fún wọn ní èsì bákan náà fún ìgbà kọ̀ọ̀kan. Ní ìgbà karùn-ún, Sanballati rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sí mi pẹ̀lú irú iṣẹ́ kan náà, lẹ́tà kan tí a kò fi sínú àpò ìwé wà ní ọwọ́ rẹ̀ tí a kọ sínú un rẹ̀ pé: “A ròyìn rẹ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè—Geṣemu sì sọ pé, òtítọ́ ni, pé—ìwọ àti àwọn Júù ń gbèrò láti ṣọ̀tẹ̀, nítorí náà ni ẹ ṣe ń mọ odi. Síwájú sí i, gẹ́gẹ́ bí ìròyìn yìí, ìwọ sì ń gbèrò láti di ọba wọn àti pé ó ti yan àwọn wòlíì kí wọn lè kéde nípa rẹ̀ ní Jerusalẹmu: ‘ọba kan wà ní Juda!’ Nísinsin yìí, ìròyìn yìí yóò padà sí ọ̀dọ̀ ọba; nítorí náà wá, jẹ́ kí a bá ara wa sọ̀rọ̀.” Mo dá èsì yìí padà sí i pé: “Kò sí ohun kan nínú irú ohun tí ìwọ sọ tí ó ṣẹlẹ̀; ìwọ kàn rò wọ́n ní orí ara rẹ ni.” Gbogbo wọn múra láti dẹ́rùbà wá, wọ́n ń rò ó wí pé, “Ọwọ́ wọn kò ní ran iṣẹ́ náà, àti wí pé wọn kò ní parí rẹ̀.” Ṣùgbọ́n mo gbàdúrà pé, “Nísinsin yìí Ọlọ́run fi agbára fún ọwọ́ mi.”