Neh 5:12 - Compare All Versions

Neh 5:12 YBCV (Bibeli Mimọ)

Nwọn si wipe, Awa o fi fun wọn pada, awa kì yio si bere nkankan lọwọ wọn; bẹ̃li awa o ṣe bi iwọ ti wi. Nigbana ni mo pe awọn alufa, mo si mu wọn bura pe, nwọn o ṣe gẹgẹ bi ileri yi.

Neh 5:12 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Wọ́n wí pé, “Àwa yóò dá a padà. Àwa kì yóò sì béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ wọn mọ́. Àwa yóò ṣe bí o ti wí.” Nígbà náà mo pe àwọn àlùfáà, mo sì mú kí àwọn ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè búra láti jẹ́ kí wọ́n ṣe ohun tí wọ́n ti ṣe ìlérí.

Neh 5:12 YCE (Yoruba Bible)

Wọ́n sì dáhùn pé, “A óo dá gbogbo rẹ̀ pada, a kò sì ní gba nǹkankan lọ́wọ́ wọn mọ́. A óo ṣe bí o ti wí.” Mo bá pe àwọn alufaa, mo sì mú kí wọ́n jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ṣe ohun tí wọ́n ṣèlérí pé àwọn yóo ṣe.