Nah 3:2-7
Nah 3:2-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ariwo pàṣan, ati ariwo kikùn kẹkẹ́, ati ti ijọ awọn ẹṣin, ati ti fifò kẹkẹ́. Ẹlẹṣin ti gbe idà rẹ̀ ti nkọ màna, ati ọkọ̀ rẹ̀ ti ndán yànran si oke: ọ̀pọlọpọ si li awọn ẹniti a pa, ati ọ̀pọlọpọ okú; okú kò si ni opin; nwọn nkọsẹ̀ li ara okú wọn wọnni: Nitori ọ̀pọlọpọ awọn panṣagà àgbere ti o roju rere gbà, iya ajẹ ti o ntà awọn orilẹ-ède nipasẹ̀ panṣaga rẹ̀, ati idile nipasẹ̀ ajẹ rẹ̀. Kiyesi i, emi dojukọ́ ọ, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; emi o si ká aṣọ itẹlẹ̀di rẹ li oju rẹ, emi o si fi ihòho rẹ hàn awọn orilẹ-ède, ati itiju rẹ hàn awọn ilẹ̀ ọba. Emi o da ẹgbin ti o ni irira si ọ lara, emi o si sọ ọ di alaimọ́, emi o si gbe ọ kalẹ bi ẹni ifiṣẹlẹyà. Yio si ṣe pe, gbogbo awọn ti o wò ọ yio sa fun ọ, nwọn o si wipe, A ti fi Ninefe ṣòfo: tani yio kẹdùn rẹ̀? nibo ni emi o ti wá olutùnu fun ọ?
Nah 3:2-7 Yoruba Bible (YCE)
Pàṣán ń ró, ẹṣin ń yan, kẹ̀kẹ́ ogun ń pariwo! Àwọn ẹlẹ́ṣin ti múra ìjà pẹlu idà ati ọ̀kọ̀ tí ń kọ mànà. Ọpọlọpọ ni wọ́n ti pa sílẹ̀, òkítì òkú kúnlẹ̀ lọ kítikìti; òkú sùn lọ bẹẹrẹ láìníye, àwọn eniyan sì ń kọlu àwọn òkú bí wọn tí ń lọ! Nítorí ọpọlọpọ ìwà àgbèrè Ninefe, tí wọ́n fanimọ́ra, ṣugbọn tí wọ́n kún fún òògùn olóró, ni gbogbo ìjìyà yìí ṣe dé bá a; nítorí ó ń fi ìwà àgbèrè rẹ̀ tan àwọn orílẹ̀-èdè jẹ, ó sì ń fi òògùn rẹ̀ mú àwọn eniyan. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní: “Wò ó! Mo ti gbógun tì ọ́, Ninefe, n óo ká aṣọ kúrò lára rẹ, n óo fi bò ọ́ lójú; n óo tú ọ sí ìhòòhò lójú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn yóo rí ìhòòhò rẹ ojú yóo sì tì ọ́. N óo mú ẹ̀gbin bá ọ n óo fi àbùkù kàn ọ́; n óo sì sọ ọ́ di ẹlẹ́yà ati ẹni àpéwò. Ẹnu yóo ya gbogbo àwọn tí ó bá wò ọ́, wọn yóo máa wí pé: ‘Ninefe ti di ahoro; ta ni yóo dárò rẹ̀? Níbo ni n óo ti rí olùtùnú fún ọ?’ ”
Nah 3:2-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ariwo pàṣán àti ariwo kíkùn kẹ̀kẹ́ ogun àti jíjó ẹṣin àti gbígbọn kẹ̀kẹ́ ogun jìgìjìgì! Ológun orí ẹṣin ń fi ìgbónára ju idà wọn mọ̀nàmọ́ná ọ̀kọ̀ rẹ̀ ti ń dán yanran sí òkè! Ọ̀pọ̀lọpọ̀ si ní àwọn ẹni tí a pa, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òkú; òkú kò sì ni òpin; àwọn ènìyàn sì ń kọsẹ̀ lára àwọn òkú. Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ panṣágà àgbèrè tí ó rójú rere gbà, Ìyá àjẹ́ tí ó ṣọ́ àwọn orílẹ̀-èdè di ẹrú nípa àgbèrè rẹ̀ àti àwọn ìdílé nípa ìṣe àjẹ́ rẹ̀. “Èmi dojúkọ ọ́,” ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. “Èmi ó si ká aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ ní ojú rẹ, Èmi yóò sì fi ìhòhò rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè àti ìtìjú rẹ̀ han àwọn ilẹ̀ ọba. Èmi yóò da ẹ̀gbin tí ó ni ìríra sí ọ ní ara, èmi yóò sì sọ ọ́ di aláìmọ́, èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹlẹ́yà. Gbogbo àwọn tí ó ba sì wò ọ́ yóò sì káàánú fún ọ, wọn yóò sì wí pé, ‘Ninefe ṣòfò: Ta ni yóò kẹ́dùn rẹ?’ Níbo ni èmi o ti wá olùtùnú fún ọ?”