Nah 3:1-19

Nah 3:1-19 Bibeli Mimọ (YBCV)

EGBE ni fun ilu ẹjẹ̀ nì! gbogbo rẹ̀ kun fun eké, ati olè, ijẹ kò kuro; Ariwo pàṣan, ati ariwo kikùn kẹkẹ́, ati ti ijọ awọn ẹṣin, ati ti fifò kẹkẹ́. Ẹlẹṣin ti gbe idà rẹ̀ ti nkọ màna, ati ọkọ̀ rẹ̀ ti ndán yànran si oke: ọ̀pọlọpọ si li awọn ẹniti a pa, ati ọ̀pọlọpọ okú; okú kò si ni opin; nwọn nkọsẹ̀ li ara okú wọn wọnni: Nitori ọ̀pọlọpọ awọn panṣagà àgbere ti o roju rere gbà, iya ajẹ ti o ntà awọn orilẹ-ède nipasẹ̀ panṣaga rẹ̀, ati idile nipasẹ̀ ajẹ rẹ̀. Kiyesi i, emi dojukọ́ ọ, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; emi o si ká aṣọ itẹlẹ̀di rẹ li oju rẹ, emi o si fi ihòho rẹ hàn awọn orilẹ-ède, ati itiju rẹ hàn awọn ilẹ̀ ọba. Emi o da ẹgbin ti o ni irira si ọ lara, emi o si sọ ọ di alaimọ́, emi o si gbe ọ kalẹ bi ẹni ifiṣẹlẹyà. Yio si ṣe pe, gbogbo awọn ti o wò ọ yio sa fun ọ, nwọn o si wipe, A ti fi Ninefe ṣòfo: tani yio kẹdùn rẹ̀? nibo ni emi o ti wá olutùnu fun ọ? Iwọ ha sàn jù No-ammoni, eyiti o wà lãrin odò ti omi yika kiri, ti agbara rẹ̀ jẹ okun, ti odi rẹ̀ si ti inu okun jade wá? Etiopia ati Egipti li agbara rẹ̀, kò si li opin; Puti ati Lubimu li awọn olùranlọwọ rẹ. Sibẹ̀sibẹ̀ a kó o lọ, o lọ si oko-ẹrú: awọn ọmọ wẹ́wẹ rẹ̀ li a fi ṣánlẹ̀ pẹlu li ori ita gbogbo; nwọn si di ibò nitori awọn ọlọla rẹ̀ ọkunrin, gbogbo awọn ọlọla rẹ̀ li a si fi ẹwọ̀n dì. Iwọ pẹlu o si yó ọti; a o si fi ọ pamọ, iwọ pẹlu o si ma ṣe afẹri ãbò nitori ti ọta na. Gbogbo ile-iṣọ agbara rẹ yio dabi igi ọpọ̀tọ pẹlu akọpọn ọpọ̀tọ: bi a ba gbọ̀n wọn, nwọn o si bọ si ẹnu ọjẹun. Kiye si i, obinrin li awọn enia rẹ lãrin rẹ: oju ibodè ilẹ rẹ li a o ṣi silẹ gbaguda fun awọn ọta rẹ: iná yio jo ikere rẹ. Iwọ pọn omi de ihamọ, mu ile iṣọ rẹ le: wọ̀ inu amọ̀, ki o si tẹ̀ erupẹ̀, ki o si ṣe ibiti a nsun okuta-amọ̀ ki o le. Nibẹ̀ ni iná yio jo ọ run; idà yio ké ọ kuro, yio si jẹ ọ bi kòkoro: sọ ara rẹ di pupọ̀ bi kòkoro, si sọ ara rẹ di pupọ̀ bi ẽṣu. Iwọ ti sọ awọn oniṣòwo rẹ di pupọ̀ jù iràwọ oju ọrun lọ: kokòro nà ara rẹ̀, o si fò lọ. Awọn alade rẹ dabi eṣú, awọn ọgagun rẹ si dabi ẹlẹngà nla, eyiti ndó sinu ọgbà la ọjọ otutù, ṣugbọn nigbati õrùn là, nwọn sa lọ, a kò si mọ̀ ibiti wọn gbe wà. Awọn olùṣọ agùtan rẹ ntõgbe, Iwọ ọba Assiria: awọn ọlọla rẹ yio ma gbe inu ekuru: awọn enia rẹ si tuka lori oke-nla, ẹnikan kò si kó wọn jọ. Kò si ipajumọ fun ifarapa rẹ; ọgbẹ rẹ kún fun irora, gbogbo ẹniti o gbọ́ ihin rẹ yio pàtẹwọ le ọ lori, nitori li ori tani ìwa-buburu rẹ kò ti kọja nigbagbogbo?

Nah 3:1-19 Yoruba Bible (YCE)

Ìlú tí ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ gbé! Ìlú tí ó kún fún irọ́ ati ìkógun, tí àwọn adigunjalè kò fi ìgbà kan dáwọ́ dúró níbẹ̀! Pàṣán ń ró, ẹṣin ń yan, kẹ̀kẹ́ ogun ń pariwo! Àwọn ẹlẹ́ṣin ti múra ìjà pẹlu idà ati ọ̀kọ̀ tí ń kọ mànà. Ọpọlọpọ ni wọ́n ti pa sílẹ̀, òkítì òkú kúnlẹ̀ lọ kítikìti; òkú sùn lọ bẹẹrẹ láìníye, àwọn eniyan sì ń kọlu àwọn òkú bí wọn tí ń lọ! Nítorí ọpọlọpọ ìwà àgbèrè Ninefe, tí wọ́n fanimọ́ra, ṣugbọn tí wọ́n kún fún òògùn olóró, ni gbogbo ìjìyà yìí ṣe dé bá a; nítorí ó ń fi ìwà àgbèrè rẹ̀ tan àwọn orílẹ̀-èdè jẹ, ó sì ń fi òògùn rẹ̀ mú àwọn eniyan. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní: “Wò ó! Mo ti gbógun tì ọ́, Ninefe, n óo ká aṣọ kúrò lára rẹ, n óo fi bò ọ́ lójú; n óo tú ọ sí ìhòòhò lójú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn yóo rí ìhòòhò rẹ ojú yóo sì tì ọ́. N óo mú ẹ̀gbin bá ọ n óo fi àbùkù kàn ọ́; n óo sì sọ ọ́ di ẹlẹ́yà ati ẹni àpéwò. Ẹnu yóo ya gbogbo àwọn tí ó bá wò ọ́, wọn yóo máa wí pé: ‘Ninefe ti di ahoro; ta ni yóo dárò rẹ̀? Níbo ni n óo ti rí olùtùnú fún ọ?’ ” Ṣé ìwọ Ninefe sàn ju ìlú Tebesi lọ, ìlú tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ odò Naili, tí omi yíká, tí ó fi òkun ṣe ààbò, tí ó sì fi omi ṣe odi rẹ̀? Etiopia ati Ijipti ni agbára rẹ̀ tí kò lópin; Puti ati Libia sì ni olùrànlọ́wọ́ rẹ̀. Sibẹsibẹ àwọn ọ̀tá kó o lọ sí ìgbèkùn, wọ́n ṣán àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀, wọ́n pa wọ́n ní ìpakúpa ní gbogbo àwọn ìkóríta wọn. Wọ́n ṣẹ́ gègé lórí àwọn ọlọ́lá ibẹ̀, wọ́n sì fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ de àwọn eniyan pataki wọn. Ninefe, ìwọ pàápàá yóo mu ọtí yó, o óo máa ta gbọ̀n- ọ́ngbọ̀n-ọ́n; o óo sì máa wá ààbò nítorí àwọn ọ̀tá rẹ. Gbogbo ibi ààbò rẹ yóo dàbí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí àkọ́so èso rẹ̀ pọ́n bí wọn bá ti gbọ̀n ọ́n, bẹ́ẹ̀ ni èso rẹ̀ yóo máa jábọ́ sí ẹnu ẹni tí yóo jẹ ẹ́. Wò ó! Àwọn ọmọ ogun rẹ dàbí obinrin! Gbogbo ẹnubodè rẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ; iná sì ti jó gbogbo ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn bodè rẹ. Ẹ pọn omi sílẹ̀ de àkókò tí ogun yóo dótì yín, ẹ ṣe ibi ààbò yín kí ó lágbára; ẹ lọ sí ibi ilẹ̀ alámọ̀, ẹ gún amọ̀, kí ẹ fi ṣe bíríkì! Ibẹ̀ ni iná yóo ti jó yín run, idà yóo pa yín lọ bí eṣú. Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ pọ̀ bí eṣú! O ti wá kún àwọn oníṣòwò rẹ, wọ́n sì pọ̀ ju ìràwọ̀ ojú ọ̀run lọ! Ṣugbọn wọ́n ti na ìyẹ́ wọn bí eṣú, wọ́n sì fò lọ. Àwọn olórí yín dàbí tata, àwọn akọ̀wé yín sì dàbí ọ̀wọ́ eṣú, tíí bà sórí odi nígbà òtútù, nígbà tí oòrùn bá yọ wọn a fò lọ; kò sì ní sí ẹni tí yóo mọ ibi tí wọ́n lọ. Àwọn olùṣọ́ rẹ ń sùn, ìwọ ọba Asiria, àwọn ọlọ́lá rẹ sì ń tòògbé; Àwọn eniyan rẹ fọ́nká lórí àwọn òkè, láìsí ẹni tí yóo gbá wọn jọ. Kò sí ẹni tí yóo wo ọgbẹ́ rẹ sàn nítorí egbò rẹ pọ̀. Àwọn tí wọ́n bá gbọ́ ìròyìn rẹ yóo pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí, nítorí kò sí ẹni tí kò tíì faragbá ninu ìwà burúkú rẹ.

Nah 3:1-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ègbé ni fún ìlú ẹ̀jẹ̀ nì, gbogbo rẹ̀ kún fún èké, ó kún fún olè, ìjẹ kò kúrò! Ariwo pàṣán àti ariwo kíkùn kẹ̀kẹ́ ogun àti jíjó ẹṣin àti gbígbọn kẹ̀kẹ́ ogun jìgìjìgì! Ológun orí ẹṣin ń fi ìgbónára ju idà wọn mọ̀nàmọ́ná ọ̀kọ̀ rẹ̀ ti ń dán yanran sí òkè! Ọ̀pọ̀lọpọ̀ si ní àwọn ẹni tí a pa, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òkú; òkú kò sì ni òpin; àwọn ènìyàn sì ń kọsẹ̀ lára àwọn òkú. Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ panṣágà àgbèrè tí ó rójú rere gbà, Ìyá àjẹ́ tí ó ṣọ́ àwọn orílẹ̀-èdè di ẹrú nípa àgbèrè rẹ̀ àti àwọn ìdílé nípa ìṣe àjẹ́ rẹ̀. “Èmi dojúkọ ọ́,” ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. “Èmi ó si ká aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ ní ojú rẹ, Èmi yóò sì fi ìhòhò rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè àti ìtìjú rẹ̀ han àwọn ilẹ̀ ọba. Èmi yóò da ẹ̀gbin tí ó ni ìríra sí ọ ní ara, èmi yóò sì sọ ọ́ di aláìmọ́, èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹlẹ́yà. Gbogbo àwọn tí ó ba sì wò ọ́ yóò sì káàánú fún ọ, wọn yóò sì wí pé, ‘Ninefe ṣòfò: Ta ni yóò kẹ́dùn rẹ?’ Níbo ni èmi o ti wá olùtùnú fún ọ?” Ǹjẹ́ ìwọ ha sàn ju Tebesi lọ, èyí tí ó wà ní ibi odò, Naili tí omi sì yí káàkiri? Odò náà sì jẹ́ ààbò rẹ̀, omi si jẹ́ odi rẹ̀. Etiopia àti Ejibiti ni agbára rẹ, kò sí ní òpin; Puti àti Libia ni àwọn olùgbèjà rẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀ a kó o ní ìgbèkùn o sì lọ sí oko ẹrú. Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ̀ ni a ó fọ́ mọ́lẹ̀ ní orí ìta gbogbo ìgboro. Wọ́n sì di ìbò nítorí àwọn ọlọ́lá rẹ̀ ọkùnrin, gbogbo àwọn ọlọ́lá rẹ ni a sì fi ẹ̀wọ̀n dè Ìwọ pẹ̀lú yóò sì mu àmupara; a ó sì fi ọ́ pamọ́ ìwọ pẹ̀lú yóò máa ṣe àfẹ́rí ààbò nítorí ti ọ̀tá náà. Gbogbo ilé ìṣọ́ agbára rẹ yóò dàbí igi ọ̀pọ̀tọ́ pẹ̀lú àkọ́pọ́n èso wọn; Nígbà tí wọ́n bá ń gbọ̀n wọ́n, ọ̀pọ̀tọ́ yóò sì bọ́ sí ẹnu àwọn ọ̀jẹun. Kíyèsi gbogbo àwọn jagunjagun! Obìnrin ni gbogbo wọn. Ojú ibodè rẹ ní a ó ṣí sílẹ̀ gbagada, fún àwọn ọ̀tá rẹ; iná yóò jó ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn ibodè rẹ. Pọn omi nítorí ìhámọ́, mú ilé ìṣọ́ rẹ lágbára sí i wọ inú amọ̀ kí o sì tẹ erùpẹ̀, kí ó sì tún ibi tí a ti ń sun bíríkì-amọ̀ ṣe kí ó le. Níbẹ̀ ni iná yóò ti jó ọ́ run; idà yóò sì ké ọ kúrò, yóò sì jẹ ọ́ bí i kòkòrò, yóò sì sọ ara rẹ̀ di púpọ̀ bí i tata, àní, di púpọ̀ bí eṣú! Ìwọ ti sọ àwọn oníṣòwò rẹ di púpọ̀ títí wọn yóò fi pọ̀ ju ìràwọ̀ ojú ọ̀run lọ Ṣùgbọ́n bi eṣú ni wọn yóò sọ ilẹ̀ náà di ahoro, wọn yóò sì fò lọ. Àwọn aládé rẹ̀ dàbí eṣú, àwọn ọ̀gágun rẹ dàbí ẹlẹ́ǹgà ńlá, èyí tí ń dó sínú ọgbà ni ọjọ́ òtútù, ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn jáde, wọ́n sálọ ẹnìkan kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé wà. Ìwọ ọba Asiria, àwọn olùṣọ́-àgùntàn rẹ̀ ń tòògbé; àwọn ọlọ́lá rẹ dùbúlẹ̀ láti sinmi. Àwọn ènìyàn rẹ fọ́nká lórí àwọn òkè ńlá, tí ẹnikẹ́ni kò sì kó wọn jọ. Kò sì sí ohun tí ó lè wo ọgbẹ́ ẹ̀ rẹ sàn; ọgbẹ́ rẹ kún fún ìrora Gbogbo ẹni tí ó bá sì gbọ́ ìròyìn rẹ yóò pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí, nítorí ta ni kò ní pín nínú ìwà búburú rẹ ti kò ti lópin.