Nah 2:1-4
Nah 2:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
ATUNIKA de iwaju rẹ (Ninefe): pa ile-iṣọ mọ, ṣọ ọ̀na na, di àmurè ẹ̀gbẹ rẹ ko le, mura girigiri. Nitori Oluwa tun pada si ọlanla Jakobu, gẹgẹ bi ọlanla Israeli: atunidanù ti tú wọn danù, nwọn si ba ẹka àjara wọn jẹ. A sọ asà awọn ọkunrin alagbara rẹ̀ di pupa, awọn akin wọn wọ̀ odòdó: kẹkẹ́ ogun yio ma kọ bi iná li ọjọ ipèse rẹ̀, igi firi li a o si mì tìti. Ariwo kẹkẹ́ ni igboro, nwọn o si ma gbún ara wọn ni ọ̀na gbigbòro, nwọn o dabi etùfu, nwọn o kọ́ bi mànamána.
Nah 2:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Atúniká ti gbógun tì ọ́, ìwọ Ninefe. Yan eniyan ṣọ́ ibi ààbò; máa ṣọ́nà, di àmùrè rẹ, kí o sì múra ogun. (Nítorí OLUWA ti ṣetán láti dá ògo Jakọbu pada bí ògo Israẹli, nítorí àwọn tí wọn ń kóni lẹ́rú ti kó wọn, wọ́n sì ti ba àwọn ẹ̀ka wọn jẹ́.) Pupa ni asà àwọn akọni rẹ̀, ẹ̀wù pupa ni àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wọ̀ Kẹ̀kẹ́ ogun wọn ń kọ mànà bí ọwọ́ iná; nígbà tí wọ́n tò wọ́n jọ, àwọn ẹṣin wọn ń yan. Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ń dà wọ ìgboro pẹlu ariwo, wọ́n ń sáré sókè sódò ní gbàgede; wọ́n mọ́lẹ̀ yòò bí iná ìtùfù, wọ́n ń kọ mànà bí mànàmáná.
Nah 2:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn apanirun ti dìde sí ọ, ìwọ Ninefe pa ilé ìṣọ́ mọ́, ṣọ́ ọ̀nà náà di àmùrè, ẹ̀gbẹ́ rẹ kí ó le, múra gírí. OLúWA yóò mú ọláńlá Jakọbu padà sípò gẹ́gẹ́ bí ọláńlá Israẹli bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn apanirun ti pa ibẹ̀ run, tí wọ́n sì ba ẹ̀ka àjàrà wọn jẹ́. Asà àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sì di pupa; àwọn ológun wọn sì wọ aṣọ òdòdó. Idẹ tí ó wà lórí kẹ̀kẹ́ ogun ń kọ mọ̀nàmọ́ná ní ọjọ́ tí a bá pèsè wọn sílẹ̀ tán; igi firi ni a ó sì mì tìtì. Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun yóò ya bo àwọn pópónà, wọn yóò sì máa sáré síwá àti sẹ́yìn ní àárín ìgboro. Wọn sì dàbí ètùfù iná; tí ó sì kọ bí i mọ̀nàmọ́ná.