Nah 2:1-2
Nah 2:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
ATUNIKA de iwaju rẹ (Ninefe): pa ile-iṣọ mọ, ṣọ ọ̀na na, di àmurè ẹ̀gbẹ rẹ ko le, mura girigiri. Nitori Oluwa tun pada si ọlanla Jakobu, gẹgẹ bi ọlanla Israeli: atunidanù ti tú wọn danù, nwọn si ba ẹka àjara wọn jẹ.
Pín
Kà Nah 2Nah 2:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Atúniká ti gbógun tì ọ́, ìwọ Ninefe. Yan eniyan ṣọ́ ibi ààbò; máa ṣọ́nà, di àmùrè rẹ, kí o sì múra ogun. (Nítorí OLUWA ti ṣetán láti dá ògo Jakọbu pada bí ògo Israẹli, nítorí àwọn tí wọn ń kóni lẹ́rú ti kó wọn, wọ́n sì ti ba àwọn ẹ̀ka wọn jẹ́.)
Pín
Kà Nah 2Nah 2:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn apanirun ti dìde sí ọ, ìwọ Ninefe pa ilé ìṣọ́ mọ́, ṣọ́ ọ̀nà náà di àmùrè, ẹ̀gbẹ́ rẹ kí ó le, múra gírí. OLúWA yóò mú ọláńlá Jakọbu padà sípò gẹ́gẹ́ bí ọláńlá Israẹli bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn apanirun ti pa ibẹ̀ run, tí wọ́n sì ba ẹ̀ka àjàrà wọn jẹ́.
Pín
Kà Nah 2