Nah 1:7-11
Nah 1:7-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Rere li Oluwa, ãbo li ọjọ ipọnju; on si mọ̀ awọn ti o gbẹkẹ̀le e. Ṣugbọn ikún omi akunrekọja li on fi ṣe iparun ibẹ̀ na de opin, okùnkun yio si ma lepa awọn ọta rẹ̀. Kili ẹnyin ngbirò si Oluwa? on o ṣe iparun de opin, ipọnju kì yio dide lẹrinkeji. Nitori sã ti a ba ká wọn jọ bi ẹ̀gun, ati sã ti wọn iba mu amupara bi ọmùti, a o run wọn gẹgẹ bi koriko ti o ti gbẹ de opin. Ẹnikan ti ọdọ rẹ jade wá, ti o ngbirò ibi si Oluwa, olugbìmọ buburu.
Nah 1:7-11 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ṣeun, òun ni ibi ààbò ní ọjọ́ ìdààmú; ó sì mọ àwọn tí wọn ń sálọ sọ́dọ̀ rẹ̀ fún ààbò. Bí odò tí ó kún bo bèbè rẹ̀ ni yóo ṣe mú ìparun bá àwọn ọ̀tá rẹ̀; yóo sì lépa àwọn ọ̀tá rẹ̀ bọ́ sí inú òkùnkùn. Èrò ibi wo ni ẹ̀ ń gbà sí OLUWA? Yóo wulẹ̀ pa yín run patapata ni; kò sì sí ẹni tí OLUWA yóo gbẹ̀san lára rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan tí yóo lè ṣẹ̀ ẹ́ lẹẹkeji. Wọn yóo jóná bí igbó ẹlẹ́gùn-ún tí ó dí, àní bíi koríko gbígbẹ. Ṣebí ọ̀kan ninu yín ni ó ń gbìmọ̀ burúkú sí OLUWA, tí ó sì ń fúnni ní ìmọ̀ràn burúkú?
Nah 1:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Rere ni OLúWA, òun ni ààbò ní ọjọ́ ìpọ́njú. Òun sì tọ́jú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e, Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìkún omi ńlá ní òun yóò fi ṣe ìparun láti ibẹ̀ dé òpin; òkùnkùn yóò sì máa lépa àwọn ọ̀tá rẹ̀. Kí ni ẹ̀yìn ń gbìmọ̀ lòdì sí OLúWA? Òun yóò fi òpin sí i, ìpọ́njú kì yóò wáyé ní ìgbà kejì Wọn yóò sì lọ́lù papọ̀ bí ẹ̀gún òṣùṣú wọn yóò sì mu àmupara nínú ọtí wáìnì wọn a ó sì run wọn gẹ́gẹ́ bi àgékù koríko gbígbẹ Láti ọ̀dọ̀ rẹ, ìwọ Ninefe, ni ẹnìkan ti jáde wá tí ó ń gbèrò ibi sí OLúWA ti ó sì ń gbìmọ̀ búburú.