Nah 1:2-8
Nah 1:2-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọlọrun njowu, Oluwa si ngbẹsan; Oluwa ngbẹsan, o si kún fun ibinu; Oluwa ngbẹsan li ara awọn ọta rẹ̀, o si fi ibinu de awọn ọta rẹ̀. Oluwa lọra lati binu, o si tobi li agbara, ni didasilẹ̀ kì yio da enia buburu silẹ: Oluwa ni ọ̀na rẹ̀ ninu ãjà ati ninu ìji, awọsanma si ni ekuru ẹsẹ̀ rẹ̀. O ba okun wi, o si mu ki o gbẹ, o si sọ gbogbo odò di gbigbẹ: Baṣani di alailera, ati Karmeli, itànna Lebanoni si rọ. Awọn oke-nla mì nitori rẹ̀, ati awọn oke kékèké di yiyọ́, ilẹ aiye si joná niwaju rẹ̀, ani aiye ati gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ̀. Tani o le duro niwaju ibinu rẹ̀? tani o si le duro gba gbigboná ibinu rẹ̀? a dà ibinu rẹ̀ jade bi iná, on li o si fọ́ awọn apata. Rere li Oluwa, ãbo li ọjọ ipọnju; on si mọ̀ awọn ti o gbẹkẹ̀le e. Ṣugbọn ikún omi akunrekọja li on fi ṣe iparun ibẹ̀ na de opin, okùnkun yio si ma lepa awọn ọta rẹ̀.
Nah 1:2-8 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA tíí jowú tíí sìí máa gbẹ̀san ni Ọlọrun. OLUWA a máa gbẹ̀san, a sì máa bínú. OLUWA a máa gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀, a sì máa fi ìrúnú rẹ̀ pamọ́ de àwọn ọ̀tá rẹ̀. OLUWA kì í tètè bínú; ó lágbára lọpọlọpọ, kì í sìí dá ẹni tí ó bá jẹ̀bi láre. Ipa ọ̀nà rẹ̀ wà ninu ìjì ati ẹ̀fúùfù líle, awọsanma sì ni eruku ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó bá òkun wí, ó mú kí ó gbẹ, ó sì mú kí gbogbo odò gbẹ pẹlu; koríko ilẹ̀ Baṣani ati ti òkè Kamẹli gbẹ, òdòdó ilẹ̀ Lẹbanoni sì rẹ̀. Àwọn òkè ńláńlá mì tìtì níwájú rẹ̀, àwọn òkè kéékèèké sì yọ́. Ilẹ̀ di asán níwájú rẹ̀, ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ di òfo. Bí ó bá ń bínú ta ló lè dúró? Ta ló lè farada ibinu gbígbóná rẹ̀? Ìrúnú rẹ̀ a máa ru jáde bí ahọ́n iná, a sì máa fọ́ àwọn àpáta níwájú rẹ̀. OLUWA ṣeun, òun ni ibi ààbò ní ọjọ́ ìdààmú; ó sì mọ àwọn tí wọn ń sálọ sọ́dọ̀ rẹ̀ fún ààbò. Bí odò tí ó kún bo bèbè rẹ̀ ni yóo ṣe mú ìparun bá àwọn ọ̀tá rẹ̀; yóo sì lépa àwọn ọ̀tá rẹ̀ bọ́ sí inú òkùnkùn.
Nah 1:2-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọlọ́run ń jẹ owú, ó sì ń gbẹ̀san. OLúWA ń gbẹ̀san, ó sì kún fún ìbínú OLúWA ń gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀, Ìbínú rẹ̀ kò sì yí padà lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀ OLúWA lọ́ra láti bínú, ó sì tóbi ní agbára; OLúWA kì yóò fi àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀ láìjìyà. Ọ̀nà rẹ̀ wà nínú afẹ́fẹ́ àti nínú ìjì, Ìkùùkuu sánmọ̀ sì ni eruku ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó bá Òkun wí, ó sì mú kí ó gbẹ; Ó sìsọ gbogbo odò di gbígbẹ. Baṣani àti Karmeli sì rọ, Ìtànná Lebanoni sì rẹ̀ sílẹ̀. Àwọn òkè ńlá wárìrì níwájú rẹ̀, àwọn òkè kéékèèkéé sì di yíyọ́, ilẹ̀ ayé sì jóná níwájú rẹ̀, àní ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀. Ta ni ó lé dúró níwájú ìbínú rẹ̀? Ta ni ó lé faradà gbígbóná ìbínú rẹ̀? Ìbínú rẹ̀ tú jáde bí iná; àwọn àpáta sì fọ́ túútúú níwájú rẹ̀. Rere ni OLúWA, òun ni ààbò ní ọjọ́ ìpọ́njú. Òun sì tọ́jú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e, Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìkún omi ńlá ní òun yóò fi ṣe ìparun láti ibẹ̀ dé òpin; òkùnkùn yóò sì máa lépa àwọn ọ̀tá rẹ̀.