Mak 7:7-11
Mak 7:7-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn lasan ni nwọn ntẹriba fun mi, ti nwọn nfi ofin enia kọ́ni fun ẹkọ́. Nitoriti ẹnyin fi ofin Ọlọrun si apakan, ẹnyin nfiyesi ofin atọwọdọwọ ti enia, bi irú wiwẹ̀ ohun-èlo ati ago: ati irú ohun miran pipọ bẹ̃ li ẹnyin nṣe. O si wi fun wọn pe, Lõtọ li ẹnyin kọ̀ ofin Ọlọrun silẹ, ki ẹnyin ki o le pa ofin atọwọdọwọ ti nyin mọ́. Mose sá wipe, Bọ̀wọ fun baba on iya rẹ; ati Ẹnikẹni ti o ba sọrọ baba tabi iya rẹ̀ ni buburu, ẹ jẹ ki o kú ikú rẹ̀ na: Ṣugbọn ẹnyin wipe, Bi enia ba wi fun baba tabi iya rẹ̀ pe, ohunkohun ti iwọ iba fi jère lara mi, Korbani ni, eyini ni Ẹbùn, o bọ́.
Mak 7:7-11 Yoruba Bible (YCE)
asán ni sísìn tí wọn ń sìn mí, ìlànà eniyan ni wọ́n fi ń kọ́ni bí òfin Ọlọrun.’ “Ẹ fi àṣẹ Ọlọrun sílẹ̀, ẹ wá dìmọ́ àṣà eniyan.” Jesu tún wí fún wọn pé, “Òtítọ́ ni pé ẹ pa àṣẹ Ọlọrun tì, kí ẹ lè mú àṣẹ ìbílẹ̀ yín ṣẹ. Nítorí Mose wí pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ’ ati pé, ‘Kí á pa ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ àbùkù sí baba tabi ìyá rẹ̀.’ Ṣugbọn ẹ̀yin wí pé, ‘Bí eniyan bá wí fún baba tabi ìyá rẹ̀ pé ohunkohun tí n bá fun yín, Kobani ni,’ (èyí ni pé ẹ̀bùn fún Ọlọrun ni)
Mak 7:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìsìn wọn jẹ́ lásán, ìkọ́ni wọ́n jẹ́ kìkìdá òfin tí àwọn ènìyàn fi ń kọ́ni.’ Nítorí tí ẹ̀yin fi òfin Ọlọ́run sí apá kan, ẹ̀yin ń tẹ̀lé àṣà àwọn ènìyàn.” Ó si wí fún wọn: “Ẹ̀yin sá à mọ̀ bí ẹ ti ń gbé òfin Ọlọ́run jù sẹ́yìn kí ẹ lè mú òfin tiyín ṣẹ. Mose fún un yín ní òfin yìí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún baba òun ìyá rẹ.’ Ó tún sọ pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ aburú sí baba tàbí ìyá rẹ̀ ní láti kú ni.’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wá sọ pé ó dára bákan náà fún ọkùnrin kan bí kó bá tilẹ̀ pèsè fún àìní àwọn òbí rẹ̀, ṣùgbọ́n kí o sọ fún wọn pé, ‘Ẹ má ṣe bínú baba tàbí ìyá mi, n kò lè ràn yín lọ́wọ́ nísinsin yìí,’ nítorí tí mo ti fi ẹ̀bùn tí ǹ bá fi fún un yín fún Ọlọ́run.