Mak 7:31-37
Mak 7:31-37 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si tun lọ kuro li àgbegbe Tire on Sidoni, o wá si okun Galili larin àgbegbe Dekapoli. Nwọn si mu enia kan wá sọdọ rẹ̀ ti etí rẹ̀ di, ti o si nkólolo; nwọn si bẹ̀ ẹ pe, ki o gbé ọwọ́ rẹ̀ le e. O si mu u kuro larin ijọ enia lọ si apakan, o si tẹ ika rẹ̀ bọ̀ ọ li etí, nigbati o tutọ́, o si fi ọwọ́ tọ́ ọ li ahọn; O si gbé oju soke wo ọrun, o kẹdùn, o si wi fun u pe, Efata, eyini ni, Iwọ ṣí. Lojukanna, etì rẹ̀ si ṣí, okùn ahọn rẹ̀ si tú, o si nsọrọ ketekete. O si paṣẹ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe sọ fun ẹnikẹni: ṣugbọn bi o ti npaṣẹ fun wọn to, bẹ̃ ni nwọn si nkokikí rẹ̀ to; Ẹnu si yà wọn gidigidi rekọja, nwọn wipe, O ṣe ohun gbogbo daradara: o mu aditi gbọran, o si mu ki odi fọhun.
Mak 7:31-37 Yoruba Bible (YCE)
Ó tún jáde kúrò ní agbègbè ìlú Tire, ó la ìlú Sidoni kọjá lọ sí òkun Galili ní ọ̀nà ààrin Ìlú Mẹ́wàá. Wọ́n wá gbé adití kan tí ń kólòlò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó fi ọwọ́ lé e. Ó bá mú un bọ́ sí apá kan, kúrò láàrin àwọn ọ̀pọ̀ eniyan, ó ti ìka rẹ̀ bọ ọkunrin náà létí, ó tutọ́, ó fi kan ahọ́n rẹ̀. Ó gbé ojú sí òkè ọ̀run, ó kẹ́dùn, ó bá ní, “Efata,” ìtumọ̀ èyí tí i ṣe, “Ìwọ, ṣí.” Etí ọkunrin náà bá ṣí, okùn ahọ́n rẹ̀ tú, ó bá ń sọ̀rọ̀ gaara. Jesu kìlọ̀ fún wọn pé kí wọn má wí fún ẹnikẹ́ni. Ṣugbọn bí ó ti ń kìlọ̀ fún wọn tó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ròyìn rẹ̀ tó. Ẹnu ya gbogbo wọn kọjá ààlà, wọ́n ń wí pé, “Ó ṣe ohun gbogbo dáradára: ó mú kí adití gbọ́ràn, ó mú kí odi sọ̀rọ̀.”
Mak 7:31-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni Jesu fi agbègbè Tire àti Sidoni sílẹ̀, ó wá si Òkun Galili láàrín agbègbè Dekapoli. Níbẹ̀ ọkùnrin kan tí kò lè sọ̀rọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ Jesu, àwọn ènìyàn sì bẹ Jesu pé kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e. Jesu sì mú ọkùnrin náà kúrò láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn. Ó sì fi àwọn ìka rẹ̀ sí etí ọkùnrin náà, ó tu itọ́ ṣọ́wọ́. Ó sì fi kan ahọ́n rẹ̀. Nígbà náà ni Jesu wòkè ọ̀run, ó sì mí kanlẹ̀, ó sì pàṣẹ wí pé, “Efata!” (èyí ni, “Ìwọ ṣí!”). Lójúkan náà, etí rẹ̀ sì ṣí, okùn ahọ́n rẹ̀ sì tú, ó sì ń sọ̀rọ̀ ketekete. Jesu pàṣẹ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn tó wà níbẹ̀ pé kí wọn má ṣe tan ìròyìn náà ká. Ṣùgbọ́n bí ó ti ń pa wọ́n lẹ́nu mọ́ tó, náà ni wọ́n ń tan ìròyìn náà káàkiri tó. Àwọn ènìyàn sì kún fún ìyanu, wọ́n wí pé, “Ó ṣe ohun gbogbo dáradára, Ó mú kí adití gbọ́rọ̀, odi sì sọ̀rọ̀.”