Mak 5:21-43

Mak 5:21-43 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nigbati Jesu si tun ti inu ọkọ̀ kọja si apa keji, ọ̀pọ enia pejọ tì i: o si wà leti okun. Si wo o, ọkan ninu awọn olori sinagogu, ti a npè ni Jairu, wa sọdọ rẹ̀; nigbati o si ri i, o wolẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀, O si bẹ̀ ẹ gidigidi, wipe, Ọmọbinrin mi kekere wà loju ikú: mo bẹ̀ ọ ki o wá fi ọwọ́ rẹ le e, ki a le mu u larada: on o si yè. O si ba a lọ; ọ̀pọ enia si ntọ̀ ọ lẹhin, nwọn si nhá a li àye. Obinrin kan ti o ti ni isun ẹ̀jẹ li ọdún mejila, Ẹniti oju rẹ̀ si ri ohun pipọ lọdọ ọ̀pọ awọn oniṣegun, ti o si ti ná ohun gbogbo ti o ni tan, ti kò si sàn rara, ṣugbọn kàka bẹ̃ o npọ̀ siwaju. Nigbati o gburo Jesu, o wá sẹhin rẹ̀ larin ọ̀pọ enia, o fọwọ́kàn aṣọ rẹ̀. Nitori o wipe, Bi mo ba sá le fi ọwọ́ mi kàn aṣọ rẹ̀, ara mi yio da. Lọgan ni isun ẹ̀jẹ rẹ̀ si ti gbẹ; on si mọ̀ lara rẹ̀ pe, a mu on larada ninu arun na. Lọgan Jesu si ti mọ̀ ninu ara rẹ̀ pe, aṣẹ ti ara on jade, o yipada larin ọpọ enia, o si wipe, Tali o fi ọwọ́ kàn mi li aṣọ? Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Iwọ ri bi ijọ enia ti nhá ọ li àye, iwọ si nwipe, Tali o fi ọwọ́ tọ́ mi? O si wò yiká lati ri ẹniti o ṣe nkan yi. Ṣugbọn obinrin na ni ibẹ̀ru ati iwarìri, bi o ti mọ̀ ohun ti a ṣe lara on, o wá, o si wolẹ niwaju rẹ̀, o si sọ gbogbo otitọ fun u. O si wi fun u pe, Ọmọbinrin, igbagbọ́ rẹ mu ọ larada; mã lọ li alafia, ki iwọ ki o si sàn ninu arun rẹ. Bi o si ti nsọ̀rọ li ẹnu, awọn kan ti ile olori sinagogu wá ti o wipe, Ọmọbinrin rẹ kú: ẽṣe ti iwọ si fi nyọ olukọni lẹnu? Lojukanna bi Jesu ti gbọ́ ọ̀rọ na ti a sọ, o si wi fun olori sinagogu na pe, Má bẹ̀ru, sá gbagbọ́ nikan. Kò si jẹ ki ẹnikẹni tọ̀ on lẹhin, bikoṣe Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu arakunrin Jakọbu. O si wá si ile olori sinagogu, o si ri ariwo, ati awọn ti nsọkun ti nwọn si npohunrere ẹkún gidigidi. Nigbati o si wọle, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi npariwo, ti ẹ si nsọkun? ọmọ na ko kú, ṣugbọn sisùn li o sùn. Nwọn si fi rẹrin ẹlẹya. Ṣugbọn nigbati o si tì gbogbo wọn jade, o mu baba ati iya ọmọ na, ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀, o si wọ̀ ibiti ọmọ na gbé dubulẹ si. O si mu ọmọ na li ọwọ́, o wi fun u pe, Talita kumi; itumọ eyi ti ijẹ Ọmọbinrin, mo wi fun ọ, Dide. Lọgan ọmọbinrin na si dide, o si nrìn; nitori ọmọ ọdún mejila ni. Ẹ̀ru si ba wọn, ẹnu si yà wọn gidigidi. O si paṣe fun wọn gidigidi pe, ki ẹnikẹni ki o máṣe mọ̀ eyi; o si wipe, ki nwọn ki o fun u li onjẹ.

Mak 5:21-43 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí Jesu tún rékọjá lọ sí òdìkejì òkun, ọpọlọpọ eniyan wọ́ jọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀ lẹ́bàá òkun. Ọkunrin kan wà tí ń jẹ́ Jairu, aṣaaju kan ni ní ilé ìpàdé ibẹ̀. Nígbà tí ó rí Jesu, ó dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀ ẹ́. Ó ní, “Ọmọdebinrin mi ń kú lọ, wá gbé ọwọ́ lé e, kí ó lè yè.” Jesu bá bá a lọ. Bí ó ti ń lọ, ọpọlọpọ eniyan ń tẹ̀lé e, wọ́n ń fún un lọ́tùn-ún lósì. Obinrin kan wà láàrin wọn tí nǹkan oṣù rẹ̀ kọ̀ tí kò dá fún ọdún mejila. Ojú rẹ̀ ti rí oríṣìíríṣìí lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn. Gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni ó ti run sórí àìsàn náà. Ṣugbọn kàkà kí ó sàn, ńṣe ni àìsàn náà túbọ̀ ń burú sí i. Nígbà tí obinrin náà gbọ́ nípa Jesu, ó gba ààrin àwọn eniyan dé ẹ̀yìn rẹ̀, ó bá fi ọwọ́ kan aṣọ rẹ̀, nítorí ó sọ ninu ara rẹ̀ pé, “Bí ó bá jẹ́ aṣọ rẹ̀ ni mo lè fi ọwọ́ kàn, ara mi yóo dá.” Lẹsẹkẹsẹ tí ó fọwọ́ kàn án ni ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ bá dá. Ó sì mọ̀ ninu ara rẹ̀ pé a ti mú òun lára dá ninu àìsàn náà. Lójú kan náà Jesu mọ̀ ninu ara rẹ̀ pé agbára ìwòsàn jáde lára òun. Ó bá yipada sí àwọn eniyan, ó bèèrè pé, “Ta ni fọwọ́ kàn mí láṣọ?” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “O rí i bí àwọn eniyan ti ń fún ọ lọ́tùn-ún lósì, o tún ń bèèrè pé ta ni fọwọ́ kàn ọ́?” Ṣugbọn Jesu ń wò yíká láti rí ẹni tí ó fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀. Obinrin náà mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lára òun, ó bá yọ jáde. Ẹ̀rù bà á, ó ń gbọ̀n, ó bá wá kúnlẹ̀ níwájú Jesu, ó sọ gbogbo òtítọ́ ọ̀rọ̀ náà fún un. Jesu wí fún un pé, “Arabinrin, igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní alaafia, o kò ní gbúròó àìsàn náà mọ́.” Kò tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ń sọ, ni àwọn kan bá dé láti ilé olórí ilé ìpàdé tí Jesu ń bá lọ sílé, wọ́n ní, “Ọmọdebinrin rẹ ti kú, kí ni o tún ń yọ olùkọ́ni lẹ́nu sí?” Ṣugbọn Jesu kò pé òun gbọ́ ohun tí wọn ń sọ, ó wí fún ọkunrin náà pé, “Má bẹ̀rù, ṣá ti gbàgbọ́.” Kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tẹ̀lé òun àfi Peteru ati Jakọbu ati Johanu àbúrò Jakọbu. Nígbà tí wọ́n dé ilé olórí ilé ìpàdé náà, Jesu rí bí gbogbo ilé ti dàrú, tí ẹkún ati ariwo ń sọ gèè. Ó bá wọ inú ilé lọ, ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi ń kígbe, tí ẹ̀ ń sunkún bẹ́ẹ̀? Ọmọde náà kò kú; ó sùn ni.” Wọ́n bá ń fi ṣe yẹ̀yẹ́, ó bá lé gbogbo wọn jáde. Ó wá mú baba ati ìyá ọmọ náà pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí ó wà pẹlu rẹ̀, ó wọ yàrá tí ọmọde náà wà lọ. Ó bá fa ọmọde náà lọ́wọ́, ó wí fún un pé, “Talita kumi” ìtumọ̀ èyí tíí ṣe, “Ìwọ ọmọde yìí, mo wí fún ọ, dìde.” Lẹsẹkẹsẹ ọmọdebinrin náà dìde, ó bá ń rìn, nítorí ọmọ ọdún mejila ni. Ìyàlẹ́nu ńlá ni ó jẹ́ fún gbogbo wọn. Jesu wá kìlọ̀ fún wọn gan-an pé kí wọn má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀. Ó ní kí wọn wá oúnjẹ fún ọmọde náà kí ó jẹ.

Mak 5:21-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí Jesu sì ti inú ọkọ̀ rékọjá sí apá kejì Òkun, ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn péjọ yí i ká ní etí Òkun. Ọ̀kan nínú àwọn olórí Sinagọgu tí à ń pè ni Jairu wá sọ́dọ̀ Jesu, nígbà tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó sì bẹ̀ ẹ́ gidigidi pé, “Ọmọbìnrin mi wà lójú ikú, mo bẹ̀ ọ́, wá fi ọwọ́ rẹ lé e, kí ara rẹ̀ lè dá, kí ó sì yè.” Jesu sì ń bá a lọ. Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì ń tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn. Obìnrin kan sì wà láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, tí ó ti ní ìsun ẹ̀jẹ̀ fún odidi ọdún méjìlá. Ẹni tí ojú rẹ̀ sì ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ àwọn oníṣègùn, tí ó sì ti ná gbogbo ohun tí ó ní, síbẹ̀ kàkà kí ó san, ó ń burú sí i. Nígbà tí ó sì gbúròó iṣẹ́ ìyanu tí Jesu ṣe, ìdí nìyìí tí ó fi wá sẹ́yìn rẹ̀, láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó sì fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀. Nítorí ti ó rò ní ọkàn rẹ̀ pé, “Bí mo bá sá à lè fi ọwọ́ kan aṣọ rẹ̀, ara mi yóò dá.” Ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì gbẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, òun sì mọ̀ lára rẹ̀ pé, a mú òun láradá kúrò nínú ààrùn náà. Lọ́gán, Jesu sì mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé agbára jáde lára òun. Ó yípadà láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó sì béèrè, “Ta ni ó fi ọwọ́ kan aṣọ mi?” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ rí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó rọ̀gbà yí ọ ká, ìwọ sì tún ń béèrè ẹni tí ó fi ọwọ́ kàn ọ́?” Síbẹ̀, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí wò yíká láti rí ẹni náà, tí ó fi ọwọ́ kan òun. Nígbà náà, obìnrin náà kún fún ìbẹ̀rù àti ìwárìrì nítorí ó ti mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lára òun. Ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ gbogbo òtítọ́ fún un. Jesu sì wí fún un pé, “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá: Máa lọ ní àlàáfíà, ìwọ sì ti sàn nínú ààrùn rẹ.” Bí Jesu sì ti ń ba obìnrin náà sọ̀rọ̀, àwọn ìránṣẹ́ dé láti ilé Jairu olórí Sinagọgu wá, wọ́n wí fún un pé, ọmọbìnrin rẹ ti kú, àti pé kí wọn má ṣe yọ Jesu lẹ́nu láti wá, nítorí ó ti pẹ́ jù. Ṣùgbọ́n bi Jesu ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún Jairu pé, “Má bẹ̀rù, sá à gbàgbọ́ nìkan.” Nígbà náà, Jesu dá ọ̀pọ̀ ènìyàn náà dúró. Kò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tẹ̀lé òun lẹ́yìn lọ ilé Jairu, bí kò ṣe Peteru, Jakọbu àti Johanu arákùnrin Jakọbu. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, Jesu rí i pé gbogbo nǹkan ti dàrú. Ilé kún fún àwọn tí ń sọkún, àti àwọn tí ń pohùnréré ẹkún. Ó wọ inú ilé lọ, o sì bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, ó béèrè pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń sọkún tí ẹ sì ń pohùnréré ẹkún? Ọmọbìnrin náà kò kú, ó sùn lásán ni.” Wọ́n sì fi í rẹ́rìn-ín. Ṣùgbọ́n ó sọ fún gbogbo wọn láti bọ́ síta, ó mú baba àti ìyá ọmọ náà, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mẹ́ta. Ó sì wọ inú yàrá tí ọmọbìnrin náà gbé dùbúlẹ̀ sí. Ó gbá a ní ọwọ́ mú, ó sì wí pé, “Talita kuumi” (tí ó túmọ̀ sí, ọmọdébìnrin, dìde dúró). Lẹ́sẹ̀kan náà, ọmọbìnrin náà sì dìde. Ó sì ń rìn, ẹ̀rù sì bà wọ́n, ẹnu sì ya àwọn òbí rẹ̀ gidigidi. Jesu sì kìlọ̀ fún wọn gidigidi pé kí wọn má ṣe sọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Ó sì wí fún wọn kí wọn fún ọmọbìnrin náà ní oúnjẹ.