Mak 3:31-35
Mak 3:31-35 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana li awọn arakunrin rẹ̀ ati iya rẹ̀ wá, nwọn duro lode, nwọn si ranṣẹ si i, nwọn npè e. Awọn ọ̀pọ enia si joko lọdọ rẹ̀, nwọn si wi fun u pe, Wò o, iya rẹ ati awọn arakunrin rẹ nwá ọ lode. O si da wọn lohùn, wipe, Tani iṣe iya mi, tabi awọn arakunrin mi? O si wò gbogbo awọn ti o joko lọdọ rẹ̀ yiká, o si wipe, Wò iya mi ati awọn arakunrin mi: Nitori ẹnikẹni ti o ba ṣe ifẹ Ọlọrun, on na li arakunrin mi, ati arabinrin mi, ati iya mi.
Mak 3:31-35 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó yá ìyá rẹ̀ ati àwọn arakunrin rẹ̀ wá, wọ́n dúró lóde, wọ́n bá ranṣẹ pè é. Àwọn eniyan jókòó yí i ká, wọ́n bá sọ fún un pé, “Gbọ́ ná, ìyá rẹ ati àwọn arakunrin rẹ ń bèèrè rẹ lóde.” Ó dá wọn lóhùn pé, “Ta ni ìyá mi ati arakunrin mi?” Nígbà tí ó wo gbogbo àwọn tí ó jókòó yí i ká lọ́tùn-ún lósì, ó ní, “Ẹ̀yin ni ìyá mi ati arakunrin mi. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ohun tí ó wu Ọlọrun, òun ni arakunrin mi, ati arabinrin mi, ati ìyá mi.”
Mak 3:31-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni àwọn arákùnrin rẹ̀ àti ìyá wá, wọ́n dúró lóde, wọ́n sì ránṣẹ́ sí i, wọ́n ń pè é. Àwọn ènìyàn tí wọ́n jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Ìyá àti àwọn arákùnrin rẹ wà lóde.” Ṣùgbọ́n ó dá wọn lóhùn wí pé, “Ta ni í ṣe ìyá mi tàbí àwọn arákùnrin mi?” Ó sì wò gbogbo àwọn tí ó jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀ yíká, ó sì wí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi: Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, òun ni arákùnrin mi àti arábìnrin mi àti ìyá mi.”