Mak 15:27-47 - Compare All Versions
Mak 15:27-47 YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si kàn awọn olè meji mọ agbelebu pẹlu rẹ̀; ọkan li ọwọ́ ọtún, ati ekeji li ọwọ́ òsi rẹ̀. Iwe-mimọ si ṣẹ, ti o wipe, A si kà a mọ awọn arufin. Awọn ti nrekọja lọ si nfi i ṣe ẹlẹyà, nwọn si nmì ori wọn, wipe, A, Iwọ ti o wó tẹmpili, ti o si kọ́ ọ ni ijọ mẹta, Gbà ara rẹ, ki o si sọkalẹ lati ori agbelebu wá. Gẹgẹ bẹ̃li awọn olori alufa pẹlu, nwọn nsin i jẹ ninu ara wọn pẹlu awọn akọwe, wipe, O gbà awọn ẹlomiran là; kò le gbà ara rẹ̀. Jẹ ki Kristi, Ọba Israeli, sọkalẹ lati ori agbelebu wá nisisiyi, ki awa ki o le ri i, ki a si le gbagbọ́. Awọn ti a kàn mọ agbelebu pẹlu rẹ̀ si nkẹgan rẹ̀. Nigbati o di wakati kẹfa, òkunkun si ṣú bò gbogbo ilẹ titi o fi di wakati kẹsan. Ni wakati kẹsan ni Jesu si kigbe soke li ohùn rara, wipe, Eloi, Eloi, lama sabaktani? itumọ eyi ti ijẹ, Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, ẽṣe ti iwọ fi kọ̀ mi silẹ? Nigbati awọn kan ninu awọn ti o duro nibẹ̀ gbọ́ eyi, nwọn wipe, Wò o, o npè Elijah. Ẹnikan si sare, o fi sponge bọ ọti kikan, o fi le ori ọpá iyè, o fifun u mu, wipe, Ẹ jọwọ rẹ̀ si; ẹ jẹ ki a ma wò bi Elijah yio wá gbé e sọkalẹ. Jesu si kigbe soke li ohùn rara, o jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ. Aṣọ ikele tẹmpili si ya si meji lati oke de isalẹ. Nigbati balogun ọrún, ti o duro niha ọdọ rẹ̀ ri ti o kigbe soke bayi, ti o si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, o wipe, Lõtọ Ọmọ Ọlọrun li ọkunrin yi iṣe. Awọn obinrin pẹlu si wà li òkere nwọn nwò: ninu awọn ẹniti Maria Magdalene wà, ati Maria iya Jakọbu kekere, ati ti Jose ati Salome; (Awọn ẹniti, nigbati o wà ni Galili, ti nwọn ntọ̀ ọ lẹhin, ti nwọn si nṣe iranṣẹ fun u;) ati ọ̀pọ obinrin miran pẹlu, ti o ba a goke wá si Jerusalemu. Nigbati alẹ si lẹ, nitoriti iṣe ọjọ ipalẹmọ, eyini ni, ọjọ ti o ṣiwaju ọjọ isimi, Josefu ara Arimatea, ọlọlá ìgbimọ, ẹniti on tikalarẹ̀ pẹlu nreti ijọba Ọlọrun, o wá, o si wọle tọ̀ Pilatu lọ laifòya, o si tọrọ okú Jesu. Ẹnu si yà Pilatu gidigidi, bi o ti kú na: o si pè balogun ọrún, o bi i lẽre bi igba ti o ti kú ti pẹ diẹ. Nigbati o si mọ̀ lati ọdọ balọgun ọrún na, o si fi okú na fun Josefu. O si rà aṣọ ọgbọ wá, o si sọ̀ ọ kalẹ, o si fi aṣọ ọgbọ na dì i, o si tẹ́ ẹ sinu ibojì ti a gbẹ́ ninu apata, o si yi okuta kan di ẹnu-ọ̀na ibojì na. Ati Maria Magdalene, ati Maria iya Jose, ri ibi ti a gbé tẹ́ ẹ si.
Mak 15:27-47 YCE (Yoruba Bible)
Ní àkókò kan náà, wọ́n kan àwọn ọlọ́ṣà meji kan mọ́ agbelebu, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, ọ̀kan ní ọwọ́ òsì rẹ̀. [ Báyìí ni àkọsílẹ̀ kan ṣẹ tí ó wí pé, “A kà á kún àwọn arúfin.”] Àwọn tí ń kọjá lọ ń sọ ìsọkúsọ sí i, wọ́n ń já apá mọ́nú, wọ́n ń wí pé, “Kò tán an! Ìwọ tí yóo wó Tẹmpili, tí yóo tún kọ́ ọ ní ọjọ́ mẹta, gba ara rẹ là, sọ̀kalẹ̀ láti orí agbelebu.” Bákan náà ni àwọn olórí alufaa pẹlu àwọn amòfin ń fi ṣe ẹlẹ́yà láàrin ara wọn, wọ́n ń wí pé, “Àwọn ẹlòmíràn ni ó le gbà là, kò lè gba ara rẹ̀ là. Kí Kristi ọba Israẹli sọ̀kalẹ̀ láti orí agbelebu nisinsinyii, kí á rí i, kí á lè gbàgbọ́.” Àwọn tí a kàn mọ́ agbelebu pẹlu rẹ̀ náà ń bu ẹ̀tẹ́ lù ú. Láti agogo mejila ọ̀sán ni òkùnkùn ti bo gbogbo ilẹ̀, títí di agogo mẹta ọ̀sán. Nígbà tí ó di agogo mẹta ọ̀sán, Jesu kígbe tòò, ó ní, “Eloi, Eloi, lema sabakitani?” Ìtumọ̀ èyí ni, “Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀?” Nígbà tí àwọn kan ninu àwọn tí ó dúró níbẹ̀ gbọ́, wọ́n ń wí pé, “Ẹ gbọ́! Ó ń pe Elija!” Ẹnìkan bá sáré, ó ti kinní kan bíi kànìnkànìn bọ inú ọtí kíkan, ó fi sí orí ọ̀pá láti fún un mu, ó ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á máa wò ó bí Elija yóo wá gbé e sọ̀kalẹ̀!” Ṣugbọn Jesu kígbe tòò, ó mí kanlẹ̀ ó bá dákẹ́. Aṣọ ìkélé tí ó wà ninu Tẹmpili bá ya sí meji láti òkè dé ilẹ̀. Nígbà tí ọ̀gágun tí ó dúró lọ́kàn-ánkán rẹ̀ rí bí ó ti dákẹ́ lẹ́yìn tí ó ti kígbe, ó ní, “Dájúdájú, ọmọ Ọlọrun ni ọkunrin yìí.” Àwọn obinrin kan wà ní òkèèrè tí wọn ń wo gbogbo ohun tí ń ṣẹlẹ̀. Ninu wọn ni Maria Magidaleni wà, ati Maria ìyá Jakọbu kékeré ati ìyá Josẹfu, ati Salomi. Àwọn wọnyi ti ń tẹ̀lé e láti ìgbà tí ó ti wà ní Galili, tí wọn ń ṣe iranṣẹ fún un. Ọpọlọpọ àwọn obinrin mìíràn wà níbẹ̀ tí wọ́n bá a gòkè wá sí Jerusalẹmu. Ọjọ́ náà jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ tíí ṣe ọ̀sẹ̀ ku ọ̀la. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, Josẹfu ará Arimatia, ọlọ́lá kan ninu àwọn ìgbìmọ̀, wá. (Ó ń retí àkókò ìjọba Ọlọrun), ó bá fi ìgboyà tọ Pilatu lọ láti bèèrè òkú Jesu. Ṣugbọn ẹnu ya Pilatu pé Jesu ti yára kú! Ó pe ọ̀gágun, ó bèèrè bí Jesu ti kú tipẹ́. Nígbà tí ó gbọ́ ìròyìn ọ̀gágun náà, ó yọ̀ǹda òkú Jesu fún Josẹfu. Josẹfu bá ra aṣọ funfun kan, ó sọ òkú Jesu kalẹ̀, ó fi aṣọ náà wé e, ó tẹ́ ẹ sí ibojì tí wọ́n gbẹ́ sí inú àpáta, lẹ́yìn náà ó yí òkúta dí ẹnu ibojì náà. Maria Magidaleni ati Maria ìyá Josẹfu ń wo ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.