Mak 14:23-24 - Compare All Versions

Mak 14:23-24 YBCV (Bibeli Mimọ)

O si gbe ago, nigbati o si sure tan, o fifun wọn: gbogbo nwọn si mu ninu rẹ̀. O si wi fun wọn pe, Eyi li ẹ̀jẹ mi ti majẹmu titun, ti a ta silẹ fun ọ̀pọ enia.

Mak 14:23-24 YCE (Yoruba Bible)

Ó tún mú ife, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó bá gbé e fún wọn. Gbogbo wọn mu ninu rẹ̀. Ó wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí a fi dá majẹmu, ẹ̀jẹ̀ tí a ta sílẹ̀ fún ọpọlọpọ eniyan.

Mak 14:23-24 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Bákan náà, ó sì mú ago wáìnì, ó dúpẹ́ fún un, ó sì gbé e fún wọn. Gbogbo wọn sì mu nínú rẹ̀. Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí májẹ̀mú tuntun, tí a ta sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.