Mak 13:14-37

Mak 13:14-37 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba ri irira isọdahoro nì, ti o duro nibiti ko tọ́, ti a ti ẹnu woli Danieli ṣọ, (ẹnikẹni ti o ba kà a, ki o yé e,) nigbana ni ki awọn ti mbẹ ni Judea sálọ si ori òke: Ki ẹniti mbẹ lori ile ki o máṣe sọkalẹ lọ sinu ile, bẹ̃ni ki o má si ṣe wọ̀ inu rẹ̀, lati mu ohunkohun jade ninu ile rẹ̀: Ati ki ẹniti mbẹ li oko ki o maṣe pada sẹhin wá lati mu aṣọ rẹ̀. Ṣugbọn egbé ni fun awọn ti o lóyun, ati fun awọn ti o nfi ọmu fun ọmọ mu li ọjọ wọnni! Ki ẹ si ma gbadura, ki sisá nyin ki o máṣe bọ́ si igba otutù. Nitori ọjọ wọnni, yio jẹ ọjọ ipọnju irú eyi ti kò si lati igba ọjọ ìwa ti Ọlọrun da, titi fi di akokò yi, irú rẹ̀ ki yio si si. Bi ko si ṣe bi Oluwa ti ke ọjọ wọnni kuru, kò si ẹda ti iba le là: ṣugbọn nitoriti awọn ayanfẹ ti o ti yàn, o ti ke ọjọ wọnni kuru. Nitorina bi ẹnikan ba wi fun nyin pe, wo o, Kristi mbẹ nihinyi; tabi, wo o, o mbẹ lọ́hun; ẹ máṣe gbà a gbọ́: Nitori awọn eke Kristi, ati awọn eke woli yio dide, nwọn o si fi àmi ati ohun iyanu hàn, tobẹ̃ bi o ṣe iṣe, nwọn iba tàn awọn ayanfẹ pãpã. Ṣugbọn ẹ kiyesara: wo o, mo sọ ohun gbogbo fun nyin tẹlẹ. Ṣugbọn li ọjọ wọnni, lẹhin ipọnju na, õrùn yio ṣõkun, oṣupá kì yio si fi imọle rẹ̀ hàn; Awọn irawọ oju ọrun yio já silẹ̀, ati agbara ti mbẹ li ọrun li a o si mì titi. Nigbana ni nwọn o si ri Ọmọ-enia ti yio ma ti oju ọrun bọ̀ ti on ti agbara nla ati ogo. Nigbana ni yio si rán awọn angẹli rẹ̀, yio si kó gbogbo awọn ayanfẹ rẹ̀ lati ori igun mẹrẹrin aiye jọ, lati ikangun aiye titi de ikangun ọrun. Nisisiyi ẹ kọ́ owe lara igi ọpọtọ; Nigbati ẹ̀ka rẹ̀ ba yọ titun, ti o ba si ru ewé, ẹnyin mọ̀ pe igba ẹ̃rùn sunmọ etile: Gẹgẹ bẹ̃ na li ẹnyin, nigbati ẹnyin ba ri nkan wọnyi ti nṣẹ, ki ẹ mọ̀ pe o sunmọ etile tan lẹhin ilẹkun. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Iran yi kì yio rekọja, titi a o fi mu gbogbo nkan wọnyi ṣẹ. Ọrun on aiye yio rekọja: ṣugbọn ọ̀rọ mi kì yio rekọja. Ṣugbọn niti ọjọ ati wakati na, kò si ẹnikan ti o mọ̀ ọ, kò si, ki tilẹ iṣe awọn angẹli ọrun, tabi Ọmọ, bikoṣe Baba mi nikanṣoṣo. Ẹ mã ṣọra, ki ẹ si mã gbadura: nitori ẹnyin ko mọ̀ igbati akokò na yio de. Nitori Ọmọ-enia dabi ọkunrin kan ti o lọ si àjo ti o jìna rére, ẹniti o fi ile rẹ̀ silẹ, ti o si fi aṣẹ fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, ati iṣẹ olukuluku fun u, ti o si fi aṣẹ fun oluṣọna ki o mã ṣọna. Nitorina ẹ mã ṣọna: nitori ẹnyin ko mọ̀ igba ti bãle ile mbọ̀wá, bi li alẹ ni, tabi larin ọganjọ, tabi li akukọ, tabi li owurọ̀: Pe, nigbati o ba de li ojijì, ki o máṣe ba nyin li oju orun. Ohun ti mo wi fun nyin, mo wi fun gbogbo enia, Ẹ mã ṣọna.

Mak 13:14-37 Yoruba Bible (YCE)

“Ṣugbọn nígbà tí ẹ bá rí ẹ̀gbin burúkú náà tí ó dúró níbi tí kò yẹ– (kí ó yé ẹni tí ń ka ìwé yìí)– nígbà náà, kí àwọn tí ó wà ní ilẹ̀ Judia sálọ sí orí òkè. Nígbà tí ẹni tí ó wà ní òkè ilé bá sọ̀kalẹ̀, kí ó má ṣe wọ ilé lọ láti mú ohunkohun jáde. Kí alágbàro ní oko má ṣe dúró mú ẹ̀wù rẹ̀ tí ó bọ́ sílẹ̀. Ọjọ́ ìṣòro ni ọjọ́ náà yóo jẹ́ fún àwọn aboyún ati àwọn tí ó ń fún ọmọ lọ́mú ní àkókò náà. Kí ẹ gbadura kí ó má jẹ́ àkókò tí òtútù mú pupọ. Nítorí ìpọ́njú yóo wà ní àkókò náà, irú èyí tí kò sí rí láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé, láti ìgbà tí Ọlọrun ti dá ohun gbogbo títí di àkókò yìí, kò sì ní sí irú rẹ̀ mọ́ lae. Bí kò bá jẹ́ pé Oluwa dín àkókò náà kù, ẹ̀dá kankan kì bá tí kù láàyè. Ṣugbọn nítorí àwọn àyànfẹ́ tí Ọlọrun yàn, ó dín àkókò rẹ̀ kù. “Bí ẹnikẹ́ni bá wí fun yín pé. ‘Wo Kristi níhìn-ín,’ tabi ‘Wò ó lọ́hùn-ún,’ ẹ má gbàgbọ́. Nítorí àwọn Kristi èké ati àwọn wolii èké yóo dìde, wọn yóo máa ṣe iṣẹ́ àmì ati iṣẹ́ ìyanu láti tan eniyan jẹ. Wọn óo tan àwọn àyànfẹ́ pàápàá jẹ, bí ó bá ṣeéṣe. Ṣugbọn ẹ̀yin, ní tiyín, ẹ ṣọ́ra. Mo ti sọ ohun gbogbo fun yín tẹ́lẹ̀. “Ní àkókò náà, lẹ́yìn ìpọ́njú yìí oòrùn yóo ṣókùnkùn, òṣùpá kò ní tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀. Àwọn ìràwọ̀ yóo máa já bọ́ láti ojú ọ̀run, a óo wá mi gbogbo àwọn ogun ọ̀run. Nígbà náà ni wọn yóo rí Ọmọ-Eniyan tí yóo máa bọ̀ ninu awọsanma pẹlu agbára ńlá ati ògo. Yóo wá rán àwọn angẹli láti lọ kó àwọn àyànfẹ́ jọ láti igun mẹrẹẹrin ayé, láti òpin ayé títí dé òpin ọ̀run. “Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ lára igi ọ̀pọ̀tọ́. Nígbà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ, tí ó rú ewé, ẹ mọ̀ pé àkókò ẹ̀ẹ̀rùn súnmọ́ ìtòsí. Bákan náà nígbà tí ẹ bá rí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi, kí ẹ mọ̀ pé Ọmọ-Eniyan wà nítòsí, ó fẹ́rẹ̀ dé. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, àwọn eniyan ìran yìí kò ní tíì kú tán tí gbogbo nǹkan wọnyi yóo fi ṣẹ. Ọ̀run ati ayé yóo kọjá lọ, ṣugbọn ọ̀rọ̀ mi kò ní kọjá lọ. “Ṣugbọn ní ti ọjọ́ ati wakati náà, kò sí ẹni tí ó mọ̀, àwọn angẹli kò mọ̀, Ọmọ pàápàá kò mọ̀, àfi Baba. Ẹ ṣọ́ra, ẹ máa fojú sọ́nà nítorí ẹ kò mọ wakati náà. Ó dàbí kí ọkunrin kan máa lọ sí ìdálẹ̀, kí ó fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, kí ó fi àṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀, kí ó fi iṣẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan fún un, kí ó wá pàṣẹ fún olùṣọ́nà pé kí ó ṣọ́nà. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ máa ṣọ́nà nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí baálé ilé náà yóo dé: bí ní ìrọ̀lẹ́ ni, tabi ní ọ̀gànjọ́, tabi ní àkùkọ ìdájí, tabi ní àfẹ̀mọ́jú. Bí ó bá dé lójijì, kí ó má baà ba yín lójú oorun. Ohun tí mò ń wí fun yín ni mò ń wí fún gbogbo eniyan: ẹ máa ṣọ́nà.”

Mak 13:14-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ṣùgbọ́n nígba tí ẹ̀yin bá rí ìríra ìsọdahoro, tí ó dúró níbí tí kò yẹ, tí a tí ẹnu wòlíì Daniẹli sọ, (ẹnikẹ́ni tí ó bá kà á ki í ó yé e) nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ni Judea sálọ sí orí òkè. Kí ẹni ti ń bẹ lórí ilé má ṣe sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ilé, bẹ́ẹ̀ ni kí ó má sì ṣe wọ inú rẹ̀, láti mú ohunkóhun jáde nínú ilé rẹ̀. Kí ẹni tí ó wà lóko má ṣe padà sẹ́yìn láti wá mú aṣọ rẹ̀. Ègbé ní fún àwọn tí ó lóyún, àti fún obìnrin tí ń fún ọ́mọ lọ́mú ní ọjọ́ wọ̀nyí. Kí ẹ sì máa gbàdúrà pé èyí ṣẹlẹ̀ ní àkókò òtútù. Nítorí ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì yóò jẹ́ àkókò ìpọ́njú, irú èyí tí kò ì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá Ọlọ́run. Irú rẹ̀ kò sì ni ṣẹlẹ̀ mọ́. “Àfi tí Olúwa bá gé àkókò ìjìyà náà kúrú, ẹyọ ẹ̀mí kan ní ayé kì yóò là. Ṣùgbọ́n nítorí àwọn tí Ọlọ́run yàn, ni yóò ṣe dín àwọn ọjọ́ náà kù. Nígbà náà, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún un yín pé, ‘Ẹ wò ó, Kristi wa níbi yìí!’ tàbí, sọ fún un yín pé, ‘Ẹ wò ó, ó wà lọ́hùn ún nì!’ Ẹ má ṣe gbà wọ́n gbọ́. Nítorí àwọn èké Kristi àti àwọn wòlíì èké ni yóò wá, wọn yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu tí yóò tan ènìyàn jẹ hàn. Bí ó bá ṣe é ṣe, wọn yóò tan àwọn àyànfẹ́ pàápàá jẹ. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra. Mo ti kìlọ̀ fún un yín ṣáájú tó! “Ṣùgbọ́n ni ọjọ́ wọ̀nyí lẹ́yìn ìpọ́njú tí mo sọ yìí, “ ‘oòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá kò ní tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀. Àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú yóò já lulẹ̀ láti ojú ọ̀run, àti agbára tí ń bẹ ní ọ̀run ni a ó sì mì tìtì.’ “Nígbà náà ni gbogbo ayé yóò sì rí i tí Èmi Ọmọ Ènìyàn yóò máa bọ̀ wá láti inú àwọsánmọ̀ pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá. Nígbà náà ni yóò sì rán àwọn angẹli rẹ̀ láti kó àwọn àyànfẹ́ ní gbogbo ayé jọ láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé láti ìkangun ayé títí dé ìkangun ọ̀run. “Nísinsin yìí, ẹ kọ́ òwe lára igi ọ̀pọ̀tọ́, nígbà tí ẹ̀ka rẹ bá ń yọ tuntun, tí ó bá sì ń rú ewé, èyí fihàn pé àkókò ẹ̀rùn ti dé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí ẹ ba ri àwọn ohun wọ̀nyí ti n ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ó súnmọ́ etílé tán, bi ìgbà tí ó wà lẹ́yìn ìlẹ̀kùn. Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, ìran yìí kì yóò rékọjá títí a ó fi mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí ṣẹ Ọ̀run àti ayé yóò kọjá lọ, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ mi dúró dájú títí ayé àìnípẹ̀kun. “Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́ tàbí wákàtí tí nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀. Àwọn angẹli ọ̀run pàápàá kò mọ̀. Àní, èmi pẹ̀lú kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe baba nìkan. Ẹ máa ṣọ́ra, ẹ dúró wámú, kí ẹ sì máa gbàdúrà: nítorí ẹ̀yin kò mọ ìgbà tí àkókò ná yóò dé. Ó dà bí ọkùnrin kan tí ó lọ sí ìrìnàjò tí ó jìnnà rere: Ẹni tí ó fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì fi àṣẹ fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti iṣẹ́ tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò ṣe, ó sì fi àṣẹ fún ẹni tó dúró lẹ́nu-ọ̀nà láti máa ṣọ́nà. “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ̀yin pẹ̀lú ní láti máa fi ìrètí ṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ àkókò tí baálé ilé yóò dé. Bóyá ní ìrọ̀lẹ́ ni o, tàbí ní ọ̀gànjọ́ òru, tàbí nígbà tí àkùkọ máa ń kọ, tàbí ní òwúrọ̀. Àti wí pé nígbà tí ó bá dé lójijì, kó má ṣe bá yín lójú oorun. Ohun tí mo wí fún un yín, mo wí fun gbogbo ènìyàn: ‘Ẹ máa ṣọ́nà!’ ”