Àmì-ìdánimọ̀ YouVersion
BíbélìÀwon ètòÀwon Fídíò
Gba ohun èlò náà
Àṣàyàn Èdè
Ṣe Àwárí

Mak 12:38-40

Mak 12:38-40 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si wi fun wọn ninu ẹkọ́ rẹ̀ pe, Ẹ mã kiyesara lọdọ awọn akọwe, ti nwọn fẹ lati mã rìn li aṣọ gigùn, ti nwọn si fẹ ikíni li ọjà, Ati ibujoko ọlá ninu sinagogu, ati ipò ọla ni ibi ase; Awọn ti o jẹ ile awọn opó run, ti nwọn si ngbadura gigun fun aṣehàn: awọn wọnyi ni yio jẹbi pọ̀ju.

Pín
Kà Mak 12

Mak 12:38-40 Yoruba Bible (YCE)

Jesu ń sọ ninu ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣọ́ra fún àwọn amòfin tí wọ́n fẹ́ràn ati máa wọ agbádá ńlá káàkiri òde, kí eniyan máa kí wọn ní ọjà, ati láti gba ìjókòó pataki ní ilé ìpàdé. Wọ́n fẹ́ràn ipò ọlá nínú sinagọgu ati ní ibi àsè. Wọ́n a máa jẹ ilé àwọn opó run. Wọ́n a máa gbadura gígùn nítorí àṣehàn. Ìdájọ́ tí wọn yóo gbà yóo le pupọ.”

Pín
Kà Mak 12

Mak 12:38-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ó sì wí fún wọn nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣọ́ra fun àwọn olùkọ́ òfin tí wọ́n fẹ́ láti máa wọ aṣọ gígùn káàkiri, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọjà, àti ibùjókòó ọlá nínú Sinagọgu àti ipò ọlá níbi àsè. Àwọn tí wọ́n jẹ ilé àwọn opó rún, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígùn fún àṣehàn, nítorí èyí, ìjìyà wọn yóò pọ̀ púpọ̀.”

Pín
Kà Mak 12
YouVersion

Ńgbà ọ́ níyànjú ó ṣì ń pè ọ́ níjà láti súnmọ́ Ọlọ́run lójoojúmọ́.

Iṣẹ́ Ìránṣẹ́

Nípaa

Àwọn iṣẹ́

Oluyọọda

Blọ́ọ̀gì

Tè

Àwọn ojú-ìwé tí ó wúlò

Ìrànlọ́wọ́

Fifún ni

Àwon Èyà Bíbélì

Àwọn Bíbélì àfetígbọ́

Àwọn Èdè Bíbélì

Ẹsẹ̀ Bíbélì t'Òní


Isẹ́ Ìránṣẹ́ orí ẹ̀rọ ìgbàlódé

Life.Church
English (US)

©2025 Life.Church / YouVersion

Ìṣe ìdá kọ́ńkó̩Àwon àdéhùn
Ètò Ìpolongo Àwọn Àìléwu
FacebookTwitterInstagramYouTubePinterest

Ilé

Bíbélì

Àwon ètò

Àwon Fídíò