Mak 10:29-30
Mak 10:29-30 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jesu si dahùn, o wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Kò si ẹniti o fi ile silẹ, tabi arakunrin, tabi arabinrin, tabi baba, tabi iya, tabi aya, tabi ọmọ, tabi ilẹ, nitori mi, ati nitori ihinrere, Ṣugbọn nisisiyi li aiye yi on o si gbà ọgọrọrun, ile, ati arakunrin, ati arabinrin, ati iya, ati ọmọ, ati ilẹ, pẹlu inunibini, ati li aiye ti mbọ̀ ìye ainipẹkun
Mak 10:29-30 Yoruba Bible (YCE)
Jesu dáhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, kò sí ẹnìkan tí ó fi ilé tabi arakunrin tabi arabinrin, tabi ìyá, tabi baba, tabi ọmọ, tabi ilẹ̀, sílẹ̀ nítorí mi ati nítorí ìyìn rere, tí kò ní rí ilé, arakunrin ati arabinrin, ìyá ati ọmọ, ati ilẹ̀ gbà ní ọgọrun-un ìlọ́po ní ìgbà ìsinsìnyìí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé pẹlu inúnibíni ni, yóo sì tún rí ìyè ainipẹkun ní ayé tí ń bọ̀.
Mak 10:29-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jesu dáhùn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín pé, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó fi ohunkóhun sílẹ̀ bí: ilé, tàbí àwọn arákùnrin, tàbí àwọn arábìnrin, tàbí ìyá, tàbí baba, tàbí àwọn ọmọ tàbí ohun ìní nítorí mi àti nítorí ìhìnrere, tí a kì yóò fún padà ní ọgọọgọ́rùn-ún àwọn ilé, tàbí arákùnrin, tàbí arábìnrin, tàbí ìyá, tàbí ọmọ, tàbí ilẹ̀, àti inúnibíni pẹ̀lú. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò jẹ́ tirẹ̀ ní ayé yìí àti pé ní ayé tó ń bọ̀ yóò ní ìyè àìnípẹ̀kun.