Mik 7:1-6
Mik 7:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
EGBE ni fun mi! nitori emi dàbi ikojọpọ̀ eso ẹ̃rùn, bi ẽṣẹ́ ikorè eso àjara: kò si ití kan lati jẹ: akọso ti ọkàn mi fẹ. Oninurere ti run kuro li aiye: kò si si olotitọ kan ninu enia: gbogbo wọn ba fun ẹ̀jẹ, olukuluku wọn nfi àwọn dẹ arakunrin rẹ̀. Ọwọ́ wọn ti mura tan lati ṣe buburu, olori mbère, onidajọ si mbère fun ẹsan; ẹni-nla nsọ ìro ika rẹ̀, nwọn si nyi i po. Ẹniti o sànjulọ ninu wọn dàbi ẹ̀gun: ìduroṣiṣin julọ mú jù ẹgún ọgbà lọ: ọjọ awọn olùṣọ rẹ ati ti ìbẹwo rẹ de; nisisiyi ni idãmu wọn o de. Ẹ má gba ọrẹ́ kan gbọ́, ẹ má si gbẹkẹ̀le amọ̀na kan: pa ilẹkùn ẹnu rẹ mọ fun ẹniti o sùn ni õkan-àiya rẹ. Nitori ọmọkunrin nṣàibọ̀wọ fun baba, ọmọbinrin dide si ìya rẹ̀, aya-ọmọ si iyakọ rẹ̀; ọta olukuluku ni awọn ara ile rẹ̀.
Mik 7:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Mo gbé! Nítorí pé, mo dàbí ìgbà tí wọn ti kórè èso àkókò ẹ̀ẹ̀rùn tán, tí wọ́n ti ká èso àjàrà tán; tí kò sí èso àjàrà mọ́ fún jíjẹ, tí kò sì sí àkọ́so èso ọ̀pọ̀tọ́ tí mo fẹ́ràn mọ́. Olóòótọ́ ti tán lórí ilẹ̀ ayé, kò sí olódodo mọ́ láàrin àwọn eniyan; gbogbo wọn ń wá ọ̀nà ìpànìyàn, olukuluku ń fi àwọ̀n dọdẹ arakunrin rẹ̀. Wọ́n mọ iṣẹ́ ibi í ṣe dáradára; àwọn ìjòyè ati àwọn onídàájọ́ wọn ń bèèrè àbẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn eniyan ńlá ń sọ èrò burúkú tí ó wà lọ́kàn wọn jáde; wọ́n sì ń pa ìmọ̀ wọn pọ̀. Ẹni tí ó sàn jùlọ ninu wọn dàbí ẹ̀gún, ẹni tí ó jẹ́ olódodo jùlọ láàrin wọn sì dàbí ẹ̀gún ọ̀gàn. Ọjọ́ ìjìyà tí àwọn wolii wọn kéde ti dé; ìdàrúdàpọ̀ wọn sì ti kù sí dẹ̀dẹ̀. Má gbára lé aládùúgbò rẹ, má sì ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rẹ́; ṣọ́ra nípa ohun tí o óo máa bá iyawo rẹ sọ. Nítorí ọmọkunrin ń tàbùkù baba rẹ̀, ọmọbinrin sì ń dìde sí ìyá rẹ̀, iyawo ń gbógun ti ìyá ọkọ rẹ̀; àwọn ará ilé ẹni sì ni ọ̀tá ẹni.
Mik 7:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ègbé ni fún mi! Nítorí èmi sì dàbí ẹni tí ń kó èso ẹ̀ẹ̀rùn jọ, ìpèsè ọgbà àjàrà; kò sì ṣí odidi àjàrà kankan láti jẹ, kò sì ṣí àkọ́so ọ̀pọ̀tọ́ nítorí tí ebi ń pa mí. Àwọn olódodo sì ti kúrò ní ilẹ̀ náà, kò sì ṣí ẹnìkan tí ó ṣẹ́kù tí ó jọ olóòtítọ́; gbogbo wọn sì ń purọ́ ní dídúró nítorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀, olúkúlùkù wọ́n sì ń fi àwọ̀n de arákùnrin rẹ̀. Ọwọ́ wọn méjèèjì ti múra tán láti ṣe búburú; àwọn alákòóso ń béèrè fún ẹ̀bùn, àwọn onídàájọ́ sì ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ alágbára sì ń pàṣẹ ohun tí wọ́n fẹ́, gbogbo wọn sì jùmọ̀ ń dìtẹ̀. Ẹni tí ó sàn jùlọ nínú wọn sì dàbí ẹ̀gún, ẹni tí ó jẹ́ olódodo jùlọ burú ju ẹ̀gún ọgbà lọ. Ọjọ́ àwọn olùṣọ́ rẹ̀ ti dé, àti ọjọ́ tí Ọlọ́run bẹ̀ ọ́ wò. Nísinsin yìí ní àkókò ìdààmú wọn. Ẹ má ṣe gba ọ̀rẹ́ kan gbọ́; ẹ má sì ṣe gbẹ́kẹ̀lé amọ̀nà kankan. Pa ìlẹ̀kùn ẹnu rẹ fún ẹni tí ó sùn ní oókan àyà rẹ. Nítorí tí ọmọkùnrin kò bọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀, ọmọbìnrin sì dìde sí ìyá rẹ̀, aya ọmọ sí ìyá ọkọ rẹ̀, ọ̀tá olúkúlùkù ni àwọn ará ilé rẹ̀.