Mik 6:8-9
Mik 6:8-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
A ti fi hàn ọ, Iwọ enia, ohun ti o dara; ati ohun ti Oluwa bère lọwọ rẹ, bikoṣe ki o ṣe otitọ, ki o si fẹ ãnu, ati ki o rìn ni irẹ̀lẹ pẹlu Ọlọrun rẹ? Ohùn Oluwa kigbe si ilu na, ọlọgbọ́n yio si ri orukọ rẹ; ẹ gbọ́ ọ̀pa na, ati ẹniti o yàn a?
Mik 6:8-9 Yoruba Bible (YCE)
A ti fi ohun tí ó dára hàn ọ́, ìwọ eniyan. Kí ni OLUWA fẹ́ kí o ṣe, ju pé kí o jẹ́ olótìítọ́ lọ, kí o máa ṣàánú eniyan, kí o sì máa rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹlu Ọlọrun rẹ? Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ará, ati àpéjọ gbogbo ìlú; ohun tí ó ti dára ni pé kí eniyan bẹ̀rù OLUWA
Mik 6:8-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó ti fihàn ọ́, ìwọ ènìyàn, ohun tí ó dára, àti ohun tí OLúWA ń béèrè lọ́wọ́ rẹ? Bí kò ṣe láti ṣe òtítọ́, kí o sì fẹ́ràn àánú, àti kí o rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run rẹ̀. Gbọ́! Ohùn OLúWA kígbe sí ìlú ńlá náà, láti jẹ ọlọ́gbọ́n ni láti bẹ̀rù orúkọ rẹ. “Ẹ kíyèsi ọ̀pá rẹ̀ gbọ́ ọ̀pá àti Ẹni náà tí ó yàn án