Mik 6:1-8

Mik 6:1-8 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ gbọ́ ohun tí Ọlọrun sọ: Ẹ dìde, kí ẹ ro ẹjọ́ yín níwájú àwọn òkè ńlá, kí ẹ sì jẹ́ kí àwọn òkè kéékèèké gbọ́ ohùn yín. Ẹ̀yin òkè, ati ẹ̀yin ìpìlẹ̀ ayérayé, ẹ gbọ́ ẹjọ́ OLUWA, nítorí ó ń bá àwọn eniyan rẹ̀ rojọ́, yóo sì bá Israẹli jà. Ọlọrun ní, “Ẹ̀yin eniyan mi, kí ni mo fi ṣe yín? Kí ni mo ṣe tí ọ̀rọ̀ mi fi su yín? Ẹ dá mi lóhùn. Èmi ni mo sá mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, tí mo rà yín pada kúrò lóko ẹrú; tí mo rán Mose, Aaroni ati Miriamu láti ṣáájú yín. Ẹ̀yin eniyan mi, ẹ ranti ète tí Balaki, ọba Moabu pa si yín, ati ìdáhùn tí Balaamu, ọmọ Beori, fún un. Ẹ ranti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ninu ìrìn àjò yín láti Ṣitimu dé Giligali, kí ẹ lè mọ iṣẹ́ ìgbàlà tí OLUWA ṣe.” Kí ni n óo mú wá fún OLUWA, tí n óo fi rẹ ara mi sílẹ̀ níwájú Ọlọrun, ẹni gíga? Ṣé kí n wá siwaju rẹ̀ pẹlu ẹbọ sísun ni tabi pẹlu ọ̀dọ́ mààlúù ọlọ́dún kan? Ǹjẹ́ inú OLUWA yóo dùn bí mo bá mú ẹgbẹẹgbẹrun aguntan wá, pẹlu ẹgbẹgbaarun-un garawa òróró olifi? Ṣé kí n fi àkọ́bí mi ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ mi, àní kí n fi ọmọ tí mo bí rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mi? A ti fi ohun tí ó dára hàn ọ́, ìwọ eniyan. Kí ni OLUWA fẹ́ kí o ṣe, ju pé kí o jẹ́ olótìítọ́ lọ, kí o máa ṣàánú eniyan, kí o sì máa rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹlu Ọlọrun rẹ?

Mik 6:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ fi etí sí ohun tí OLúWA wí: “Dìde dúró, bẹ ẹ̀bẹ̀ fún ẹjọ́ rẹ níwájú òkè ńlá; sì jẹ́ kí àwọn òkè kéékèèkéé gbọ́ ohun tí ó fẹ́ wí. “Gbọ́, ìwọ òkè ńlá, ẹ̀sùn OLúWA; gbọ́, ìwọ ìpìlẹ̀ ilé ayérayé. Nítorí OLúWA ń bá àwọn ènìyàn rẹ̀ wíjọ́; òun yóò sì bá Israẹli rojọ́. “Ẹ̀yin ènìyàn mi, kí ni mo ṣe fún yín? Àti nínú kí ni mo ti dá yin lágara? Dá mi lóhùn. Nítorí èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá, mo sì rà yín padà láti ilẹ̀ ẹrú wá. Mo rán Mose láti darí yín, bákan náà mo rán Aaroni àti Miriamu síwájú rẹ̀. Ìwọ ènìyàn mi, rántí ohun tí Balaki ọba Moabu gbèrò àti ohun tí Balaamu ọmọ Beori dáhùn. Rántí ìrìnàjò rẹ̀ láti Ṣittimu dé Gilgali, kí ìwọ ba le mọ òdodo OLúWA.” Kí ni èmi yóò ha mú wá síwájú OLúWA tí èmi ó fi tẹ ara mi ba níwájú Ọlọ́run gíga? Kí èmi ha wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun, pẹ̀lú ọmọ màlúù ọlọ́dún kan? Ǹjẹ́ OLúWA yóò ní inú dídùn sí ẹgbẹgbàarùn-ún àgbò, tàbí sí ẹgbẹgbàarùn-ún ìṣàn òróró? Èmi yóò ha fi àkọ́bí mi sílẹ̀ fún ìré-òfin-kọjá mi, èso inú ara mi fún ẹ̀ṣẹ̀ ọkàn mi? Ó ti fihàn ọ́, ìwọ ènìyàn, ohun tí ó dára, àti ohun tí OLúWA ń béèrè lọ́wọ́ rẹ? Bí kò ṣe láti ṣe òtítọ́, kí o sì fẹ́ràn àánú, àti kí o rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run rẹ̀.