Mik 4:1-7

Mik 4:1-7 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí ó bá yá, a óo fìdí òkè ilé OLUWA múlẹ̀ bí òkè tí ó ga jùlọ, a óo gbé e ga ju àwọn òkè yòókù lọ, àwọn eniyan yóo sì máa wọ́ wá sibẹ. Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè yóo wá, wọn yóo sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á lọ sórí òkè OLUWA, ẹ jẹ́ kí á lọ sí ilé Ọlọrun Jakọbu, kí ó lè kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, kí á sì lè máa tọ̀ ọ́.” Nítorí pé láti Sioni ni òfin yóo ti máa jáde, ọ̀rọ̀ OLUWA yóo sì máa jáde láti Jerusalẹmu. Yóo ṣe ìdájọ́ láàrin ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, ati láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ó lágbára ní ọ̀nà jíjìn réré; wọn yóo fi idà wọn rọ ọkọ́, wọn yóo sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé; àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́, wọn kò sì ní kọ́ ogun jíjà mọ́. Ṣugbọn olukuluku yóo jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀, ati lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kò sì ní sí ẹni tí yóo dẹ́rùbà wọ́n; nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó sọ bẹ́ẹ̀. Olukuluku orílẹ̀-èdè a máa rìn ní ọ̀nà tí oriṣa rẹ̀ là sílẹ̀, ṣugbọn ọ̀nà OLUWA tí Ọlọrun wa là sílẹ̀ ni àwa yóo máa tọ̀ títí laelae. OLUWA ní, “Nígbà tí ó bá yá, n óo kó gbogbo àwọn arọ jọ, n óo kó àwọn tí mo ti túká jọ, ati àwọn tí mo ti pọ́n lójú. N óo dá àwọn arọ sí, kí wọ́n lè wà lára àwọn eniyan Israẹli tí wọ́n ṣẹ́kù, àwọn tí a túká yóo sì di orílẹ̀-èdè ńlá; OLUWA yóo sì jọba lórí wọn ní òkè Sioni láti ìsinsìnyìí lọ ati títí laelae.”

Mik 4:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ọjọ́ ìkẹyìn a ó fi òkè ilé OLúWA lélẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá, a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèkéé lọ, àwọn ènìyàn yóò sì máa wọ̀ sínú rẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò wá, wọn yóò sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá OLúWA, àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu Òun yóò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.” Òfin yóò jáde láti Sioni wá, àti ọ̀rọ̀ OLúWA láti Jerusalẹmu. Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, yóò sì parí aáwọ̀ fún orílẹ̀-èdè alágbára jíjìn réré. Wọn yóò sì fi idà wọn rọ ohun èlò ìtulẹ̀ àti ọ̀kọ̀ wọn di dòjé orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́. Ṣùgbọ́n olúkúlùkù yóò jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, ẹnìkan kì yóò sì dẹ́rùbà wọ́n, nítorí OLúWA àwọn ọmọ-ogun ti sọ̀rọ̀. Gbogbo àwọn ènìyàn ń rìn, olúkúlùkù ni orúkọ ọlọ́run tirẹ̀, ṣùgbọ́n àwa yóò máa rìn ní orúkọ OLúWA. Ọlọ́run wa láé àti láéláé. OLúWA “Ní ọjọ́ náà,” ni OLúWA wí, “Èmi yóò kó àwọn arọ jọ; èmi yóò sì ṣà àwọn tí a lé kúrò ní ìlú jọ, àti àwọn ẹni tí èmi ti pọ́n lójú. Èmi yóò dá àwọn arọ sí fún èyí tókù, èmi yóò sì sọ àwọn tí a lé kúrò ní ìlú di orílẹ̀-èdè alágbára. OLúWA yóò sì jẹ ọba lórí wọn ní òkè ńlá Sioni láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.