Mik 2:1-13
Mik 2:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
EGBE ni fun awọn ti ngbìmọ aiṣedede, ti nṣiṣẹ ibi lori akete wọn! nigbati ojumọ́ mọ́ nwọn nṣe e, nitoripe o wà ni agbara ọwọ́ wọn. Nwọn si nṣe ojukòkoro oko, nwọn si nfi ipá gbà a: ati ile, nwọn a si mu wọn lọ: nwọn si ni enia lara ati ile rẹ̀, ani enia ati ini rẹ̀. Nitorina bayi ni Oluwa wi; Kiyesi i, emi ngbimọ̀ ibi si idile yi, ninu eyiti ọrùn nyin kì yio le yọ; bẹni ẹnyin kì yio fi igberaga lọ: nitori akokò ibi ni yi. Li ọjọ na ni ẹnikan yio pa owe kan si nyin, yio si pohunrere-ẹkun kikorò pe, Ni kikó a kó wa tan? on ti pin iní enia mi: bawo ni o ti ṣe mu u kuro lọdọ mi! o ti pin oko wa fun awọn ti o yapa. Nitorina iwọ kì yio ni ẹnikan ti yio ta okùn nipa ìbo ninu ijọ enia Oluwa. Nwọn ni, ẹ máṣe sọtẹlẹ, nwọn o sọtẹlẹ, bi nwọn kò ba sọtẹlẹ bayi, itiju kì yio kuro. Iwọ ẹniti anpe ni ile Jakobu, Ẹmi Oluwa ha bùkù bi? iṣe rẹ̀ ha ni wọnyi? ọ̀rọ mi kò ha nṣe rere fun ẹni ti nrin dẽde bi? Ati nijelo awọn enia mi dide bi ọta si mi: ẹnyin ti bọ́ ẹ̀wu ati aṣọ ibora kuro lọdọ awọn ti nkọja li ailewu, bi awọn ẹniti o kọ̀ ogun silẹ. Obinrin awọn enia mi li ẹnyin ti le jade kuro ninu ile wọn daradara; ẹnyin ti gbà ogo mi kuro lọwọ awọn ọmọ wọn lailai. Ẹ dide, ki ẹ si ma lọ; nitoripe eyi kì iṣe ibi isimi: nitoriti o jẹ alaimọ́, yio pa nyin run, ani iparun kikorò? Bi enia kan ti nrin ninu ẹmi ati itanjẹ ba ṣeke, wipe, emi o sọ asọtẹlẹ̀ ti ọti-waini ati ọti-lile fun ọ; on ni o tilẹ ṣe woli awọn enia yi. Ni kikó emi o kó nyin jọ, iwọ Jakobu, gbogbo nyin; ni gbigbá emi o gbá iyokù Israeli jọ; emi o si tò wọn jọ pọ̀ gẹgẹ bi agutan Bosra, gẹgẹ bi ọwọ́ ẹran ninu agbo wọn: nwọn o si pariwo nla nitori ọ̀pọlọpọ enia. Ẹniti nfọ́ni ti dide niwaju wọn: nwọn ti fọ́, nwọn kọja lãrin bode, nwọn si ti jade lọ nipa rẹ̀: ọba wọn o si kọja lọ niwaju wọn, Oluwa ni yio si ṣe olori wọn.
Mik 2:1-13 Yoruba Bible (YCE)
Ègbé ni fún àwọn tí wọn ń gbìmọ̀ ìkà, tí wọ́n sì ń gbèrò ibi lórí ibùsùn wọn. Nígbà tí ilẹ̀ bá sì mọ́, wọn á ṣe ibi tí wọn ń gbèrò. Nítorí pé ó wà ní ìkáwọ́ wọn láti ṣe é. Bí ilẹ̀ kan bá wọ̀ wọ́n lójú, wọn á gbà á lọ́wọ́ onílẹ̀; bí ilé kan ló bá sì wù wọ́n, wọn á fi ipá gbà á lọ́wọ́ onílé; wọ́n ń fìyà jẹ eniyan ati ilé rẹ̀, àní eniyan ati ohun ìní rẹ̀. Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí; ó ní, “Wò ó, mò ń gbèrò ibi kan sí ìdílé yìí; tí ẹ kò ní lè bọ́rí ninu rẹ̀; ẹ kò ní rìn pẹlu ìgbéraga, nítorí pé àkókò burúkú ni yóo jẹ́. Ní ọjọ́ náà, wọn yóo máa fi yín kọrin ẹlẹ́yà, wọn yóo sì sọkún le yín lórí tẹ̀dùntẹ̀dùn. Wọn yóo wí pé, ‘A ti parun patapata; ó ti pa ìpín àwọn eniyan mi dà; ẹ wò bí ó ti yí i kúrò lọ́dọ̀ mi, ó pín ilẹ̀ wa fún àwọn tí wọ́n ṣẹgun wa.’ ” Nítorí náà kò ní sí ìpín fún ẹnikẹ́ni ninu yín mọ́ nígbà tí a bá dá ilẹ̀ náà pada fún àwọn eniyan Ọlọrun. Àwọn eniyan náà ń pàrọwà fún mi pé, “Má waasu fún wa. Kò yẹ kí eniyan máa waasu nípa irú nǹkan báwọ̀nyí, Ọlọrun kò ní dójútì wá. Ṣé irú ọ̀rọ̀ tí eniyan máa sọ nìyí, ẹ̀yin ará ilé Jakọbu? Ṣé OLUWA kò ní mú sùúrù mọ́ ni? Àbí ẹ rò pé òun ni ó ń ṣe àwọn nǹkan wọnyi? Àbí ọ̀rọ̀ mi kì í ṣe àwọn tí wọ́n bá ń rin ọ̀nà ẹ̀tọ́ ní rere?” OLUWA ní: “Ṣugbọn ẹ dìde sí àwọn eniyan mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá, ẹ gba ẹ̀wù lọ́rùn àwọn tí wọn ń lọ lalaafia, àwọn tí wọn ń rékọjá lọ láìronú ogun. Ẹ lé àwọn aya àwọn eniyan mi jáde kúrò ninu ilé tí wọ́n fẹ́ràn; ẹ sì gba ògo mi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn títí lae. Ẹ dìde, ẹ máa lọ, nítorí pé ìhín yìí kì í ṣe ibi ìsinmi; nítorí pé ẹ ti hùwà ìríra tí ń mú ìparun ńlá báni. “Wolii tí yóo máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ ati ẹ̀tàn ni àwọn eniyan wọnyi ń fẹ́, tí yóo sì máa waasu pé, ‘Ẹ óo ní ọpọlọpọ waini ati ọtí líle.’ “Dájúdájú, n óo kó gbogbo yín jọ, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, n óo kó àwọn ọmọ Israẹli yòókù jọ: n óo kó wọn pọ̀ bí aguntan, sinu agbo, àní bí agbo ẹran ninu pápá, ariwo yóo sì pọ̀ ninu agbo náà, nítorí ọ̀pọ̀ eniyan.” Ọlọrun tíí ṣí ọ̀nà ni yóo ṣáájú wọn; wọn yóo já irin ẹnubodè, wọn yóo sì gba ibẹ̀ jáde. Ọba wọn ni yóo ṣáájú wọn, OLUWA ni yóo sì ṣiwaju gbogbo wọn.
Mik 2:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ègbé ni fún àwọn tí ń gbèrò àìṣedéédéé tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ ibi lórí ibùsùn wọn! Nígbà tí ojúmọ́ bá mọ́, wọn yóò gbé e jáde nítorí ó wà ní agbára wọn láti ṣe é. Wọ́n sì ń ṣe ojúkòkòrò oko, wọ́n sì fi agbára wọn gbà wọ́n, àti àwọn ilé, wọ́n sì gbà wọ́n. Wọ́n sì ni ènìyàn àti ilẹ̀ rẹ̀ lára àní ènìyàn àti ohun ìní rẹ̀. Nítorí náà, OLúWA wí pé: “Èmi ń gbèrò ibi sí àwọn ìdílé wọ̀nyí, nínú èyí tí wọn kì yóò le è gba ara wọn là. Ìwọ kì yóò sì lè máa rìn ní ìgbéraga mọ́, nítorí yóò jẹ́ àkókò ibi. Ní ọjọ́ náà ni ẹnìkan yóò pa òwe kan sí yín; wọn yóò sì pohùnréré ẹkún kíkorò pé: ‘Ní kíkó a ti kó wọn tán; OLúWA ti pín ohun ìní àwọn ènìyàn mi; Ó ti mú un kúrò lọ́dọ̀ mi! Ó fi oko wa lé àwọn ọlọ̀tẹ̀ lọ́wọ́.’ ” Nítorí náà, ìwọ kò ní ní ẹnìkankan tí yóò ta okùn nínú ìjọ OLúWA, tí yóò pín ilẹ̀ nípa ìbò. “Ẹ má ṣe sọtẹ́lẹ̀,” ni àwọn Wòlíì wọn wí. “Ẹ má ṣe sọtẹ́lẹ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí; kí ìtìjú má ṣe le bá wa” Ṣé kí á sọ ọ́, ìwọ ilé Jakọbu: “Ǹjẹ́ ẹ̀mí OLúWA ha ń bínú bí? Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ ha nìwọ̀nyí?” “Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ mi kò ha ń ṣe rere fún ẹni tí ń rìn déédé bí? Láìpẹ́ àwọn ènìyàn mi dìde bí ọ̀tá sí mi. Ìwọ bọ́ aṣọ ọlọ́rọ̀ kúrò lára àwọn tí ń kọjá lọ ní àìléwu, bí àwọn ẹni tí ó padà bọ̀ láti ojú ogun. Ẹ̀yin sì lé obìnrin àwọn ènìyàn mi kúrò nínú ilé ayọ̀ wọn, ẹ̀yin sì ti gba ògo mi, kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn láéláé. Ẹ dìde, kí ẹ sì máa lọ! Nítorí èyí kì í ṣe ibi ìsinmi yín, nítorí tí a ti sọ ọ́ di àìmọ́ yóò pa yín run, àní ìparun kíkorò. Tí òpùrọ́ àti ẹlẹ́tàn bá wà tí wọ́n sì wí pé, ‘Èmi yóò sọtẹ́lẹ̀ fún ọ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ wáìnì àti ọtí líle,’ òun ni yóò tilẹ̀ ṣe wòlíì àwọn ènìyàn wọ̀nyí! “Èmi yóò kó gbogbo yín jọ, ìwọ Jakọbu; Èmi yóò gbá ìyókù Israẹli jọ. Èmi yóò kó wọn jọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nínú agbo ẹran, gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran nínú agbo wọn, ibẹ̀ yóò sì pariwo nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn. Ẹni tí ó ń fọ ọ̀nà yóò lọ sókè níwájú wọn; wọn yóò fọ láti ẹnu ibodè, wọn yóò sì jáde lọ. Àwọn ọba wọn yóò sì kọjá lọ níwájú wọn, OLúWA ni yóò sì ṣe olórí wọn.”