Mik 1:2-7
Mik 1:2-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ gbọ́, gbogbo ẹnyin enia; fetisilẹ, Iwọ ilẹ aiye, ati ẹkún rẹ̀: si jẹ ki Oluwa Ọlọrun ṣe ẹlẹri si nyin, Oluwa lati inu tempili mimọ́ rẹ̀ wá. Nitori, wo o, Oluwa jade lati ipò rẹ̀ wá, yio si sọ̀kalẹ, yio si tẹ̀ awọn ibi giga aiye mọlẹ. Awọn oke nla yio si yọ́ labẹ rẹ̀, awọn afonifojì yio si pinyà, bi ida niwaju iná, bi omi ti igbálọ ni ibi gẹ̀rẹgẹ̀rẹ. Nitori irekọja Jakobu ni gbogbo eyi, ati nitori ẹ̀ṣẹ ile Israeli. Kini irekọja Jakobu? Samaria ha kọ? ki si ni awọn ibi giga Juda? Jerusalemu ha kọ? Nitorina li emi o ṣe Samaria bi òkiti pápa, ati bi gbigbin àjara: emi o si gbá awọn okuta rẹ̀ danù sinu afonifojì, emi o si ṣi awọn ipalẹ rẹ̀ silẹ. Gbogbo awọn ere fifin rẹ̀ ni a o run womu-womu, gbogbo awọn ẹbùn rẹ̀ li a o fi iná sun, gbogbo awọn oriṣà rẹ̀ li emi o sọ di ahoro: nitoriti o ko o jọ lati inu ẹbùn panṣaga wá, nwọn o si pada si ẹbùn panṣaga.
Mik 1:2-7 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, fetí sílẹ̀, ìwọ ayé, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀. Kí OLUWA fúnrarẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́rìí tí yóo takò yín, àní OLUWA, láti inú tẹmpili rẹ̀ mímọ́. Wò ó, OLUWA ń jáde bọ̀ láti inú ilé rẹ̀, yóo sọ̀kalẹ̀, yóo sì rìn lórí àwọn òkè gíga ayé. Àwọn òkè ńlá yóo yọ́ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, bí ìda tíí yọ̀ níwájú iná; àwọn àfonífojì yóo pínyà gẹ́gẹ́ bí omi tí a dà sílẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu, ati ti ilé Israẹli ni gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣe ṣẹlẹ̀. Kí ló fa ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu? Ṣebí ìlú Samaria ni. Kí sì ni ẹ̀ṣẹ̀ ilé Juda? Ṣebí ìlú Jerusalẹmu ni. OLUWA ní, “Nítorí náà, n óo sọ Samaria di àlàpà ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú, yóo di ọgbà ìgbin àjàrà sí; gbogbo òkúta tí a fi kọ́ ọ ni n óo fọ́nká, sinu àfonífojì, ìpìlẹ̀ rẹ̀ yóo sì hàn síta. Gbogbo ère oriṣa rẹ̀ ni a óo fọ́ túútúú, a óo sì jó gbogbo owó iṣẹ́ àgbèrè rẹ̀ níná. Gbogbo ère rẹ̀ ni n óo kójọ bí òkítì, a óo sì kọ̀ wọ́n tì; nítorí pé owó àgbèrè ni ó fi kó wọn jọ, ọrọ̀ rẹ̀ yóo pada sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ń bá a ṣe àgbèrè.
Mik 1:2-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn, fetísílẹ̀, ìwọ ayé àti gbogbo ohun tó wà níbẹ̀, kí OLúWA Olódùmarè lè ṣe ẹlẹ́rìí sí yín, Olúwa láti inú tẹmpili mímọ́ rẹ̀ wá. Wò ó! OLúWA ń bọ̀ wá láti ibùgbé rẹ̀; yóò sọ̀kalẹ̀, yóò sì tẹ ibi gíga ayé mọ́lẹ̀. Àwọn òkè ńlá yóò sí yọ́ lábẹ́ rẹ̀, àwọn Àfonífojì yóò sì pínyà, bí idà níwájú iná, bí omi tí ó ń sàn lọ ni ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́. Nítorí ìré-òfin-kọjá Jakọbu ni gbogbo èyí, àti nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli. Kí ni ìré-òfin-kọjá Jakọbu? Ǹjẹ́ Samaria ha kọ? Kí ni àwọn ibi gíga Juda? Ǹjẹ́ Jerusalẹmu ha kọ? “Nítorí náà, èmi yóò ṣe Samaria bí òkìtì lórí pápá, bí ibi ti à ń lò fún gbígbin ọgbà àjàrà. Èmi yóò gbá àwọn òkúta rẹ̀ dànù sínú àfonífojì. Èmi yóò sí tú ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ palẹ̀. Gbogbo àwọn ère fínfín rẹ̀ ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́ gbogbo àwọn ẹ̀bùn tẹmpili rẹ̀ ni a ó fi iná sun: Èmi yóò sì pa gbogbo àwọn òrìṣà rẹ̀ run. Nítorí tí ó ti kó àwọn ẹ̀bùn rẹ̀ jọ láti inú owó èrè panṣágà, gẹ́gẹ́ bí owó èrè panṣágà, wọn yóò sì tún padà sí owó iṣẹ́ panṣágà.”