Mik 1:2-4
Mik 1:2-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ gbọ́, gbogbo ẹnyin enia; fetisilẹ, Iwọ ilẹ aiye, ati ẹkún rẹ̀: si jẹ ki Oluwa Ọlọrun ṣe ẹlẹri si nyin, Oluwa lati inu tempili mimọ́ rẹ̀ wá. Nitori, wo o, Oluwa jade lati ipò rẹ̀ wá, yio si sọ̀kalẹ, yio si tẹ̀ awọn ibi giga aiye mọlẹ. Awọn oke nla yio si yọ́ labẹ rẹ̀, awọn afonifojì yio si pinyà, bi ida niwaju iná, bi omi ti igbálọ ni ibi gẹ̀rẹgẹ̀rẹ.
Mik 1:2-4 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, fetí sílẹ̀, ìwọ ayé, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀. Kí OLUWA fúnrarẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́rìí tí yóo takò yín, àní OLUWA, láti inú tẹmpili rẹ̀ mímọ́. Wò ó, OLUWA ń jáde bọ̀ láti inú ilé rẹ̀, yóo sọ̀kalẹ̀, yóo sì rìn lórí àwọn òkè gíga ayé. Àwọn òkè ńlá yóo yọ́ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, bí ìda tíí yọ̀ níwájú iná; àwọn àfonífojì yóo pínyà gẹ́gẹ́ bí omi tí a dà sílẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè.
Mik 1:2-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn, fetísílẹ̀, ìwọ ayé àti gbogbo ohun tó wà níbẹ̀, kí OLúWA Olódùmarè lè ṣe ẹlẹ́rìí sí yín, Olúwa láti inú tẹmpili mímọ́ rẹ̀ wá. Wò ó! OLúWA ń bọ̀ wá láti ibùgbé rẹ̀; yóò sọ̀kalẹ̀, yóò sì tẹ ibi gíga ayé mọ́lẹ̀. Àwọn òkè ńlá yóò sí yọ́ lábẹ́ rẹ̀, àwọn Àfonífojì yóò sì pínyà, bí idà níwájú iná, bí omi tí ó ń sàn lọ ni ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́.