Mik 1:1-5
Mik 1:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Mika ara Moraṣti wá li ọjọ Jotamu, Ahasi, ati Hesekiah, awọn ọba Juda, ti o ri niti Samaria ati Jerusalemu. Ẹ gbọ́, gbogbo ẹnyin enia; fetisilẹ, Iwọ ilẹ aiye, ati ẹkún rẹ̀: si jẹ ki Oluwa Ọlọrun ṣe ẹlẹri si nyin, Oluwa lati inu tempili mimọ́ rẹ̀ wá. Nitori, wo o, Oluwa jade lati ipò rẹ̀ wá, yio si sọ̀kalẹ, yio si tẹ̀ awọn ibi giga aiye mọlẹ. Awọn oke nla yio si yọ́ labẹ rẹ̀, awọn afonifojì yio si pinyà, bi ida niwaju iná, bi omi ti igbálọ ni ibi gẹ̀rẹgẹ̀rẹ. Nitori irekọja Jakobu ni gbogbo eyi, ati nitori ẹ̀ṣẹ ile Israeli. Kini irekọja Jakobu? Samaria ha kọ? ki si ni awọn ibi giga Juda? Jerusalemu ha kọ?
Mik 1:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ fún Mika, ará Moreṣeti nípa Jerusalẹmu ati Samaria nìyí, ní àkókò ìjọba Jotamu, ati ti Ahasi ati ti Hesekaya, àwọn ọba Juda. Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, fetí sílẹ̀, ìwọ ayé, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀. Kí OLUWA fúnrarẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́rìí tí yóo takò yín, àní OLUWA, láti inú tẹmpili rẹ̀ mímọ́. Wò ó, OLUWA ń jáde bọ̀ láti inú ilé rẹ̀, yóo sọ̀kalẹ̀, yóo sì rìn lórí àwọn òkè gíga ayé. Àwọn òkè ńlá yóo yọ́ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, bí ìda tíí yọ̀ níwájú iná; àwọn àfonífojì yóo pínyà gẹ́gẹ́ bí omi tí a dà sílẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu, ati ti ilé Israẹli ni gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣe ṣẹlẹ̀. Kí ló fa ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu? Ṣebí ìlú Samaria ni. Kí sì ni ẹ̀ṣẹ̀ ilé Juda? Ṣebí ìlú Jerusalẹmu ni.
Mik 1:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀rọ̀ OLúWA tí ó tọ Mika ará Moreṣeti wá ní àkókò ìjọba Jotamu, Ahasi, àti Hesekiah, àwọn ọba Juda nìwọ̀nyí, ìran tí ó rí nípa Samaria àti Jerusalẹmu. Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn, fetísílẹ̀, ìwọ ayé àti gbogbo ohun tó wà níbẹ̀, kí OLúWA Olódùmarè lè ṣe ẹlẹ́rìí sí yín, Olúwa láti inú tẹmpili mímọ́ rẹ̀ wá. Wò ó! OLúWA ń bọ̀ wá láti ibùgbé rẹ̀; yóò sọ̀kalẹ̀, yóò sì tẹ ibi gíga ayé mọ́lẹ̀. Àwọn òkè ńlá yóò sí yọ́ lábẹ́ rẹ̀, àwọn Àfonífojì yóò sì pínyà, bí idà níwájú iná, bí omi tí ó ń sàn lọ ni ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́. Nítorí ìré-òfin-kọjá Jakọbu ni gbogbo èyí, àti nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli. Kí ni ìré-òfin-kọjá Jakọbu? Ǹjẹ́ Samaria ha kọ? Kí ni àwọn ibi gíga Juda? Ǹjẹ́ Jerusalẹmu ha kọ?