Mik 1:1-2
Mik 1:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Mika ara Moraṣti wá li ọjọ Jotamu, Ahasi, ati Hesekiah, awọn ọba Juda, ti o ri niti Samaria ati Jerusalemu. Ẹ gbọ́, gbogbo ẹnyin enia; fetisilẹ, Iwọ ilẹ aiye, ati ẹkún rẹ̀: si jẹ ki Oluwa Ọlọrun ṣe ẹlẹri si nyin, Oluwa lati inu tempili mimọ́ rẹ̀ wá.
Mik 1:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ fún Mika, ará Moreṣeti nípa Jerusalẹmu ati Samaria nìyí, ní àkókò ìjọba Jotamu, ati ti Ahasi ati ti Hesekaya, àwọn ọba Juda. Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, fetí sílẹ̀, ìwọ ayé, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀. Kí OLUWA fúnrarẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́rìí tí yóo takò yín, àní OLUWA, láti inú tẹmpili rẹ̀ mímọ́.
Mik 1:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀rọ̀ OLúWA tí ó tọ Mika ará Moreṣeti wá ní àkókò ìjọba Jotamu, Ahasi, àti Hesekiah, àwọn ọba Juda nìwọ̀nyí, ìran tí ó rí nípa Samaria àti Jerusalẹmu. Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn, fetísílẹ̀, ìwọ ayé àti gbogbo ohun tó wà níbẹ̀, kí OLúWA Olódùmarè lè ṣe ẹlẹ́rìí sí yín, Olúwa láti inú tẹmpili mímọ́ rẹ̀ wá.