Mat 9:12-13
Mat 9:12-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn nigbati Jesu gbọ́, o wi fun wọn pe, Awọn ti ara wọn le kò fẹ oniṣegun, bikoṣe awọn ti ara wọn kò da. Ṣugbọn ẹ lọ ẹ si kọ́ bi ã ti mọ̀ eyi si, Anu li emi nfẹ, kì iṣe ẹbọ: nitori emi kò wá lati pè awọn olododo, bikoṣe awọn ẹlẹṣẹ si ironupiwada.
Pín
Kà Mat 9Mat 9:12-13 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Jesu gbọ́, ó ní, “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn bíkòṣe àwọn tí ara wọn kò dá. Ẹ lọ kọ́ ìtumọ̀ gbolohun yìí: Ọlọrun sọ pé, ‘Àánú ṣíṣe ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ rírú.’ Nítorí náà kì í ṣe àwọn olódodo ni mo wá pè, bíkòṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”
Pín
Kà Mat 9Mat 9:12-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu gbọ́ èyí, ó wí fún wọn pé, “Àwọn tí ara wọ́n le kò wá oníṣègùn bí kò ṣe àwọn tí ara wọn kò dá. Ṣùgbọ́n ẹ lọ kọ́ ohun ti èyí túmọ̀ sí: ‘Àánú ni èmi ń fẹ́, kì í ṣe ẹbọ;’ nítorí èmi kò wá láti pe àwọn olódodo, bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”
Pín
Kà Mat 9