Mat 8:8-10
Mat 8:8-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Balogun ọrún na dahùn, o si wipe, Oluwa, emi ko yẹ ti iwọ iba fi wọ̀ abẹ orule mi; ṣugbọn sọ kìki ọ̀rọ kan, a o si mu ọmọ-ọdọ mi larada. Ẹniti o wà labẹ aṣẹ sá li emi, emi si li ọmọ-ogun lẹhin mi; mo wi fun ẹnikan pe, Lọ, a si lọ; ati fun ẹnikeji pe, Wá, a si wá; ati fun ọmọ-ọdọ mi pe, Ṣe eyi, a si ṣe e. Nigbati Jesu gbọ́, ẹnu yà a, o si wi fun awọn ti o ntọ̀ ọ lẹhin pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, emi ko ri igbagbọ́ nla bi irú eyi ninu awọn enia Israeli.
Mat 8:8-10 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn ọ̀gágun náà dáhùn pé, “Alàgbà, èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ìbá wọ inú ilé rẹ̀. Ṣá sọ gbolohun kan, ara ọmọ-ọ̀dọ̀ mi yóo sì dá. Nítorí ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ ni èmi náà, mo ní àwọn ọmọ-ogun lábẹ́ mi. Bí mo bá sọ fún ọ̀kan pé, ‘Lọ!’ yóo lọ ni. Bí mo bá sọ fún òmíràn pé, ‘Wá!’ yóo sì wá. Bí mo bá sọ fún ẹrú mi pé, ‘Ṣe èyí!’ yóo ṣe é ni.” Nígbà tí Jesu gbọ́, ẹnu yà á, ó sọ fún àwọn tí ó ń tẹ̀lé e pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, n kò rí irú igbagbọ báyìí ní Israẹli pàápàá!
Mat 8:8-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Balógun ọ̀rún náà dáhùn, ó wí pé, “Olúwa, èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ń wọ̀ abẹ́ òrùlé rẹ̀, ṣùgbọ́n sọ kìkì ọ̀rọ̀ kan, a ó sì mú ọmọ ọ̀dọ̀ mi láradá. Ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ sá ni èmi, èmi sí ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi. Bí mo wí fún ẹni kan pé, ‘Lọ,’ a sì lọ, àti fún ẹni kejì pé, ‘Wá,’ a sì wá, àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ mi pé, ‘Ṣe èyí,’ a sì ṣe é.” Nígbà tí Jesu gbọ́ èyí ẹnu yà á, ó sì wí fún àwọn tí ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi kò rí ẹnìkan ni Israẹli tó ní ìgbàgbọ́ ńlá bí irú èyí.