Mat 8:5-13
Mat 8:5-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati Jesu si wọ̀ Kapernaumu, balogun ọrún kan tọ̀ ọ wá, o mbẹ̀ ẹ, O si nwipe, Oluwa, ọmọ-ọdọ mi dubulẹ arùn ẹ̀gba ni ile, ni irora pupọ̀. Jesu si wi fun u pe, Emi mbọ̀ wá mu u larada. Balogun ọrún na dahùn, o si wipe, Oluwa, emi ko yẹ ti iwọ iba fi wọ̀ abẹ orule mi; ṣugbọn sọ kìki ọ̀rọ kan, a o si mu ọmọ-ọdọ mi larada. Ẹniti o wà labẹ aṣẹ sá li emi, emi si li ọmọ-ogun lẹhin mi; mo wi fun ẹnikan pe, Lọ, a si lọ; ati fun ẹnikeji pe, Wá, a si wá; ati fun ọmọ-ọdọ mi pe, Ṣe eyi, a si ṣe e. Nigbati Jesu gbọ́, ẹnu yà a, o si wi fun awọn ti o ntọ̀ ọ lẹhin pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, emi ko ri igbagbọ́ nla bi irú eyi ninu awọn enia Israeli. Mo si wi fun nyin, ọ̀pọlọpọ enia ni yio ti ìha ìla-õrùn ati ìha íwọ-õrùn wá, nwọn a si ba Abrahamu, ati Isaaki, ati Jakọbu joko ni ilẹ-ọba ọrun. Ṣugbọn awọn ọmọ ilẹ-ọba li a o sọ sinu òkunkun lode, nibẹ̀ li ẹkún on ipahinkeke yio gbe wà. Jesu si wi fun balogun ọrún na pe, Mã lọ, bi iwọ si ti gbagbọ́, bẹ̃ni ki o ri fun ọ. A si mu ọmọ-ọdọ rẹ̀ larada ni wakati kanna.
Mat 8:5-13 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Jesu wọ ìlú Kapanaumu, ọ̀gágun kan tí ó ní ọgọrun-un ọmọ-ogun lábẹ́ rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó ń bẹ̀ ẹ́; ó ní, “Alàgbà, ọmọ-ọ̀dọ̀ mi kan wà ninu ilé tí àrùn ẹ̀gbà ń dà láàmú, ó sì ń joró gidigidi.” Jesu bá sọ fún un pé, “N óo wá, n óo sì wò ó sàn.” Ṣugbọn ọ̀gágun náà dáhùn pé, “Alàgbà, èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ìbá wọ inú ilé rẹ̀. Ṣá sọ gbolohun kan, ara ọmọ-ọ̀dọ̀ mi yóo sì dá. Nítorí ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ ni èmi náà, mo ní àwọn ọmọ-ogun lábẹ́ mi. Bí mo bá sọ fún ọ̀kan pé, ‘Lọ!’ yóo lọ ni. Bí mo bá sọ fún òmíràn pé, ‘Wá!’ yóo sì wá. Bí mo bá sọ fún ẹrú mi pé, ‘Ṣe èyí!’ yóo ṣe é ni.” Nígbà tí Jesu gbọ́, ẹnu yà á, ó sọ fún àwọn tí ó ń tẹ̀lé e pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, n kò rí irú igbagbọ báyìí ní Israẹli pàápàá! Mo tún ń sọ fun yín pé, ọpọlọpọ eniyan yóo wá láti ìlà oòrùn ati láti ìwọ̀ oòrùn, wọn yóo bá Abrahamu ati Isaaki ati Jakọbu jẹun ní ìjọba ọ̀run. Ṣugbọn àwọn ọmọ ìjọba ọ̀run ni a óo tì jáde sinu òkùnkùn biribiri, níbi tí ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà.” Jesu bá sọ fún ọ̀gágun náà pé, “Máa lọ, gẹ́gẹ́ bí o ti gbàgbọ́, bẹ́ẹ̀ ni kí ó rí fún ọ.” Ara ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì dá ní àkókò náà gan-an.
Mat 8:5-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Jesu sì wọ̀ Kapernaumu, balógun ọ̀rún kan tọ̀ ọ́ wá, ó bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́. O sì wí pé, “Olúwa, ọmọ ọ̀dọ̀ mi dùbúlẹ̀ ààrùn ẹ̀gbà ni ilé, tòun ti ìrora ńlá.” Jesu sì wí fún un pé, “Èmi ń bọ̀ wá mú un láradá.” Balógun ọ̀rún náà dáhùn, ó wí pé, “Olúwa, èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ń wọ̀ abẹ́ òrùlé rẹ̀, ṣùgbọ́n sọ kìkì ọ̀rọ̀ kan, a ó sì mú ọmọ ọ̀dọ̀ mi láradá. Ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ sá ni èmi, èmi sí ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi. Bí mo wí fún ẹni kan pé, ‘Lọ,’ a sì lọ, àti fún ẹni kejì pé, ‘Wá,’ a sì wá, àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ mi pé, ‘Ṣe èyí,’ a sì ṣe é.” Nígbà tí Jesu gbọ́ èyí ẹnu yà á, ó sì wí fún àwọn tí ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi kò rí ẹnìkan ni Israẹli tó ní ìgbàgbọ́ ńlá bí irú èyí. Mo sì wí fún yín, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò ti ìhà ìlà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrùn wá, wọ́n á sì bá Abrahamu àti Isaaki àti Jakọbu jẹun ní ìjọba ọ̀run. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìjọba ni a ó sọ sínú òkùnkùn lóde, níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò gbé wà.” Nítorí náà Jesu sì wí fún balógun ọ̀run náà pé, “Máa lọ ilé, ohun tí ìwọ gbàgbọ́ ti rí bẹ́ẹ̀.” A sì mú ọmọ ọ̀dọ̀ náà láradá ní wákàtí kan náà.