Mat 8:26-27
Mat 8:26-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ṣe ojo bẹ̃, ẹnyin onigbagbọ́ kekere? Nigbana li o dide, o si ba afẹfẹ ati okun wi; idakẹrọrọ si de. Ṣugbọn ẹnu yà awọn ọkunrin na, nwọn wipe, Irú enia wo li eyi, ti afẹfẹ ati omi okun gbọ tirẹ̀?
Pín
Kà Mat 8Mat 8:26-27 Yoruba Bible (YCE)
Ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ ti ṣe lójo bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin onigbagbọ kékeré wọnyi?” Ó bá dìde, ó bá afẹ́fẹ́ ati òkun wí, ìdákẹ́rọ́rọ́ ńlá bá dé. Ẹnu ya àwọn eniyan náà. Wọ́n ní, “Irú eniyan wo ni èyí, tí afẹ́fẹ́ ati òkun ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu?”
Pín
Kà Mat 8Mat 8:26-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré. Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń bẹ̀rù?” Nígbà náà ní ó dìde dúró, ó sì bá ìjì àti rírú Òkun náà wí, gbogbo rẹ̀ sì parọ́rọ́. Ṣùgbọ́n ẹnu yà àwọn ọkùnrin náà, wọ́n sì béèrè pé, “Irú ènìyàn wo ni èyí? Kódà ìjì líle àti rírú omi Òkun gbọ́ tirẹ̀?”
Pín
Kà Mat 8