Mat 8:1-34
Mat 8:1-34 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBATI o ti ori òke sọkalẹ, ọ̀pọ enia ntọ̀ ọ lẹhin. Si wò o, adẹtẹ̀ kan wá, o tẹriba fun u, o wipe, Oluwa, bi iwọ ba fẹ, iwọ le sọ mi di mimọ́. Jesu si nà ọwọ́ rẹ̀, o fi bà a, o wipe, Mo fẹ; iwọ di mimọ́. Lojukanna ẹ̀tẹ rẹ̀ si mọ́. Jesu si wi fun u pe, Wò ó, máṣe sọ fun ẹnikan; ṣugbọn mã ba ọ̀na rẹ lọ, fi ara rẹ hàn fun awọn alufa, ki o si fi ẹ̀bun ti Mose palaṣẹ li ẹrí fun wọn. Nigbati Jesu si wọ̀ Kapernaumu, balogun ọrún kan tọ̀ ọ wá, o mbẹ̀ ẹ, O si nwipe, Oluwa, ọmọ-ọdọ mi dubulẹ arùn ẹ̀gba ni ile, ni irora pupọ̀. Jesu si wi fun u pe, Emi mbọ̀ wá mu u larada. Balogun ọrún na dahùn, o si wipe, Oluwa, emi ko yẹ ti iwọ iba fi wọ̀ abẹ orule mi; ṣugbọn sọ kìki ọ̀rọ kan, a o si mu ọmọ-ọdọ mi larada. Ẹniti o wà labẹ aṣẹ sá li emi, emi si li ọmọ-ogun lẹhin mi; mo wi fun ẹnikan pe, Lọ, a si lọ; ati fun ẹnikeji pe, Wá, a si wá; ati fun ọmọ-ọdọ mi pe, Ṣe eyi, a si ṣe e. Nigbati Jesu gbọ́, ẹnu yà a, o si wi fun awọn ti o ntọ̀ ọ lẹhin pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, emi ko ri igbagbọ́ nla bi irú eyi ninu awọn enia Israeli. Mo si wi fun nyin, ọ̀pọlọpọ enia ni yio ti ìha ìla-õrùn ati ìha íwọ-õrùn wá, nwọn a si ba Abrahamu, ati Isaaki, ati Jakọbu joko ni ilẹ-ọba ọrun. Ṣugbọn awọn ọmọ ilẹ-ọba li a o sọ sinu òkunkun lode, nibẹ̀ li ẹkún on ipahinkeke yio gbe wà. Jesu si wi fun balogun ọrún na pe, Mã lọ, bi iwọ si ti gbagbọ́, bẹ̃ni ki o ri fun ọ. A si mu ọmọ-ọdọ rẹ̀ larada ni wakati kanna. Nigbati Jesu si wọ̀ ile Peteru lọ, o ri iya aya rẹ̀ dubulẹ àisan ibà. O si fi ọwọ́ bà a li ọwọ́, ibà si fi i silẹ; on si dide, o si nṣe iranṣẹ fun wọn. Nigbati o si di aṣalẹ, nwọn gbe ọ̀pọlọpọ awọn ẹniti o ni ẹmi èṣu wá sọdọ rẹ̀: o si fi ọ̀rọ rẹ̀ lé awọn ẹmi na jade, o si mu awọn olokunrun larada: Ki eyi ti a ti sọ lati ẹnu woli Isaiah wá le ṣẹ, pe, On tikararẹ̀ gbà ailera wa, o si nrù àrun wa. Nigbati Jesu ri ọ̀pọlọpọ enia lọdọ rẹ̀, o paṣẹ fun wọn lati lọ si apa keji adagun. Akọwe kan si tọ̀ ọ wá, o wi fun u pe, Olukọni, emi ó mã tọ̀ ọ lẹhin nibikibi ti iwọ nlọ. Jesu si wi fun u pe, Awọn kọ̀lọkọlọ ni ihò, ati awọn ẹiyẹ oju ọrun ni itẹ́; ṣugbọn Ọmọ-enia kò ni ibi ti yio gbé fi ori rẹ̀ le. Ekeji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wi fun u pe, Oluwa, jẹ ki emi ki o kọ́ lọ isinkú baba mi na. Ṣugbọn Jesu wi fun u pe, Iwọ mã tọ̀ mi lẹhin, si jẹ ki awọn okú ki o mã sin okú ara wọn. Nigbati o si bọ si ọkọ̀, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tẹ̀le e. Si wò o, afẹfẹ nla dide ninu okun tobẹ̃ ti riru omi fi bò ọkọ̀ mọlẹ; ṣugbọn on sùn. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tọ̀ ọ wá, nwọn ji i, nwọn wipe, Oluwa, gbà wa, awa gbé. O si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ṣe ojo bẹ̃, ẹnyin onigbagbọ́ kekere? Nigbana li o dide, o si ba afẹfẹ ati okun wi; idakẹrọrọ si de. Ṣugbọn ẹnu yà awọn ọkunrin na, nwọn wipe, Irú enia wo li eyi, ti afẹfẹ ati omi okun gbọ tirẹ̀? Nigbati o si de apa keji ni ilẹ awọn ara Gergesene, awọn ọkunrin meji ẹlẹmi èṣu pade rẹ̀, nwọn nti inu ibojì jade wá, nwọn rorò gidigidi tobẹ̃ ti ẹnikan ko le kọja li ọ̀na ibẹ̀. Si wò o, nwọn kigbe soke wipe, Kini ṣe tawa tirẹ, Jesu, iwọ Ọmọ Ọlọrun? iwọ wá lati da wa loro ki o to to akokò? Agbo ọ̀pọ ẹlẹdẹ ti njẹ mbẹ li ọ̀na jijìn si wọn. Awọn ẹmi èṣu na si bẹ̀ ẹ, wipe, Bi iwọ ba lé wa jade, jẹ ki awa ki o lọ sinu agbo ẹlẹdẹ yi. O si wi fun wọn pe, Ẹ mã lọ. Nigbati nwọn si jade, nwọn lọ sinu agbo ẹlẹdẹ na; si wò o, gbogbo agbo ẹlẹdẹ na rọ́ sinu okun li ogedengbe, nwọn si ṣegbé ninu omi. Awọn ẹniti nṣọ wọn si sá, nwọn si mu ọ̀na wọn pọ̀n lọ si ilu, nwọn ròhin ohun gbogbo, ati ohun ti a ṣe fun awọn ẹlẹmi èṣu. Si wò o, gbogbo ará ilu na si jade wá ipade Jesu; nigbati nwọn si ri i, nwọn bẹ̀ ẹ, ki o le lọ kuro li àgbegbe wọn.
Mat 8:1-34 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Jesu sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, ọ̀pọ̀ àwọn eniyan ń tẹ̀lé e. Ẹnìkan tí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ sì wá, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Alàgbà bí o bá fẹ́, o lè sọ ara mi di mímọ́.” Jesu bá na ọwọ́ rẹ̀, ó fi kàn án, ó ní, “Mo fẹ́, kí ara rẹ di mímọ́.” Lẹsẹkẹsẹ ni àrùn ẹ̀tẹ̀ náà bá kúrò lára rẹ̀. Jesu wá sọ fún un pé, “Má sọ fún ẹnikẹ́ni. Ṣugbọn, lọ, fi ara rẹ han alufaa, kí o ṣe ìrúbọ gẹ́gẹ́ bí Mose ti pa á láṣẹ, bí ẹ̀rí fún wọn pé ara rẹ ti dá.” Nígbà tí Jesu wọ ìlú Kapanaumu, ọ̀gágun kan tí ó ní ọgọrun-un ọmọ-ogun lábẹ́ rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó ń bẹ̀ ẹ́; ó ní, “Alàgbà, ọmọ-ọ̀dọ̀ mi kan wà ninu ilé tí àrùn ẹ̀gbà ń dà láàmú, ó sì ń joró gidigidi.” Jesu bá sọ fún un pé, “N óo wá, n óo sì wò ó sàn.” Ṣugbọn ọ̀gágun náà dáhùn pé, “Alàgbà, èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ìbá wọ inú ilé rẹ̀. Ṣá sọ gbolohun kan, ara ọmọ-ọ̀dọ̀ mi yóo sì dá. Nítorí ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ ni èmi náà, mo ní àwọn ọmọ-ogun lábẹ́ mi. Bí mo bá sọ fún ọ̀kan pé, ‘Lọ!’ yóo lọ ni. Bí mo bá sọ fún òmíràn pé, ‘Wá!’ yóo sì wá. Bí mo bá sọ fún ẹrú mi pé, ‘Ṣe èyí!’ yóo ṣe é ni.” Nígbà tí Jesu gbọ́, ẹnu yà á, ó sọ fún àwọn tí ó ń tẹ̀lé e pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, n kò rí irú igbagbọ báyìí ní Israẹli pàápàá! Mo tún ń sọ fun yín pé, ọpọlọpọ eniyan yóo wá láti ìlà oòrùn ati láti ìwọ̀ oòrùn, wọn yóo bá Abrahamu ati Isaaki ati Jakọbu jẹun ní ìjọba ọ̀run. Ṣugbọn àwọn ọmọ ìjọba ọ̀run ni a óo tì jáde sinu òkùnkùn biribiri, níbi tí ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà.” Jesu bá sọ fún ọ̀gágun náà pé, “Máa lọ, gẹ́gẹ́ bí o ti gbàgbọ́, bẹ́ẹ̀ ni kí ó rí fún ọ.” Ara ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì dá ní àkókò náà gan-an. Nígbà tí Jesu wọ inú ilé Peteru, ó rí ìyá iyawo Peteru tí ibà dá dùbúlẹ̀. Jesu bá fi ọwọ́ kàn án lọ́wọ́, ibà náà sì fi í sílẹ̀. Ó bá dìde, ó bá tọ́jú oúnjẹ fún un. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbé ọpọlọpọ eniyan tí wọ́n ní ẹ̀mí èṣù wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ọ̀rọ̀ ẹnu ni ó fi lé àwọn ẹ̀mí náà jáde, ó sì tún wo gbogbo àwọn tí ara wọn kò dá sàn. Báyìí ni ọ̀rọ̀ tí wolii Aisaya sọ ṣẹ, nígbà tí ó sọ pé, “Òun fúnra rẹ̀ ni ó mú àìlera wa lọ, ó sì gba àìsàn wa fún wa.” Nígbà tí Jesu rí ọ̀pọ̀ eniyan tí wọ́n yí i ká, ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọn kọjá sí òdìkejì òkun. Amòfin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sọ fún un pé, “Olùkọ́ni, mo fẹ́ máa tẹ̀lé ọ níbikíbi tí o bá ń lọ.” Jesu wí fún un pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́; ṣugbọn Ọmọ-Eniyan kò ní ibi tí yóo gbé orí rẹ̀ lé.” Ẹlòmíràn ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Alàgbà, jẹ́ kí n kọ́ lọ sìnkú baba mi.” Ṣugbọn Jesu sọ fún un pé, “Ìwọ tẹ̀lé mi, jẹ́ kí àwọn òkú máa sin òkú ara wọn.” Jesu wọ ọkọ̀ ojú omi kan, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Ìgbì líle kan sì dé lójú omi òkun; ó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé omi fẹ́rẹ̀ bo ọkọ̀; ṣugbọn Jesu sùnlọ. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá lọ jí i; wọ́n ní, “Oluwa, gbà wá là, à ń ṣègbé lọ!” Ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ ti ṣe lójo bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin onigbagbọ kékeré wọnyi?” Ó bá dìde, ó bá afẹ́fẹ́ ati òkun wí, ìdákẹ́rọ́rọ́ ńlá bá dé. Ẹnu ya àwọn eniyan náà. Wọ́n ní, “Irú eniyan wo ni èyí, tí afẹ́fẹ́ ati òkun ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu?” Nígbà tí ó dé òdìkejì òkun, ní ilẹ̀ àwọn ará Gadara, àwọn ọkunrin meji tí wọn ní ẹ̀mí èṣù jáde láti inú itẹ́ òkú, wọ́n wá pàdé rẹ̀. Wọ́n le tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé kò sí ẹni tí ó lè gba ọ̀nà ibẹ̀ kọjá. Wọ́n bá kígbe pé, “Kí ni ó pa tàwa-tìrẹ pọ̀, ìwọ Ọmọ Ọlọrun? Ṣé o dé láti wá dà wá láàmú ṣáájú àkókò wa ni?” Agbo ọpọlọpọ ẹlẹ́dẹ̀ kan wà tí wọn ń jẹ lókèèrè. Àwọn ẹ̀mí èṣù náà bá bẹ Jesu pé, “Bí o óo bá lé wa jáde, lé wa lọ sinu agbo ẹlẹ́dẹ̀ ọ̀hún nnì.” Jesu bá wí fún wọn pé, “Ẹ lọ!” Wọ́n bá jáde lọ sí inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀. Gbogbo agbo ẹlẹ́dẹ̀ bá dorí kọ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè náà, wọ́n sáré lọ, wọ́n sì rì sómi. Àwọn tí wọn ń tọ́jú agbo ẹlẹ́dẹ̀ bá sá kúrò níbẹ̀, wọ́n lọ sí ààrin ìlú, wọ́n lọ ròyìn gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ati ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Gbogbo ìlú bá jáde lọ pàdé Jesu. Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé kí ó jọ̀wọ́ kí ó kúrò ní agbègbè wọn.
Mat 8:1-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ó ti orí òkè sọ̀kalẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. Sì wò ó, adẹ́tẹ̀ kan wà, ó wá ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀ ó wí pé, “Olúwa, bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè sọ mi di mímọ́.” Jesu sì nà ọwọ́ rẹ̀, ó fi bà á, ó wí pé, “Mo fẹ́, ìwọ di mímọ́.” Lójúkan náà, ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ sì mọ́! Jesu sì wí fún pé, “Wò ó, má ṣe sọ fún ẹnìkan. Ṣùgbọ́n máa ba ọ̀nà rẹ̀ lọ, fi ara rẹ̀ hàn fún àlùfáà, kí o sì san ẹ̀bùn tí Mose pàṣẹ ní ẹ̀rí fún wọn.” Nígbà tí Jesu sì wọ̀ Kapernaumu, balógun ọ̀rún kan tọ̀ ọ́ wá, ó bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́. O sì wí pé, “Olúwa, ọmọ ọ̀dọ̀ mi dùbúlẹ̀ ààrùn ẹ̀gbà ni ilé, tòun ti ìrora ńlá.” Jesu sì wí fún un pé, “Èmi ń bọ̀ wá mú un láradá.” Balógun ọ̀rún náà dáhùn, ó wí pé, “Olúwa, èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ń wọ̀ abẹ́ òrùlé rẹ̀, ṣùgbọ́n sọ kìkì ọ̀rọ̀ kan, a ó sì mú ọmọ ọ̀dọ̀ mi láradá. Ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ sá ni èmi, èmi sí ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi. Bí mo wí fún ẹni kan pé, ‘Lọ,’ a sì lọ, àti fún ẹni kejì pé, ‘Wá,’ a sì wá, àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ mi pé, ‘Ṣe èyí,’ a sì ṣe é.” Nígbà tí Jesu gbọ́ èyí ẹnu yà á, ó sì wí fún àwọn tí ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi kò rí ẹnìkan ni Israẹli tó ní ìgbàgbọ́ ńlá bí irú èyí. Mo sì wí fún yín, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò ti ìhà ìlà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrùn wá, wọ́n á sì bá Abrahamu àti Isaaki àti Jakọbu jẹun ní ìjọba ọ̀run. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìjọba ni a ó sọ sínú òkùnkùn lóde, níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò gbé wà.” Nítorí náà Jesu sì wí fún balógun ọ̀run náà pé, “Máa lọ ilé, ohun tí ìwọ gbàgbọ́ ti rí bẹ́ẹ̀.” A sì mú ọmọ ọ̀dọ̀ náà láradá ní wákàtí kan náà. Nígbà tí Jesu sì dé ilé Peteru, ìyá ìyàwó Peteru dùbúlẹ̀ àìsàn ibà. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu fi ọwọ́ kan ọwọ́ rẹ̀, ibà náà fi í sílẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó sì dìde ó ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn. Nígbà tí ó di àṣálẹ́, ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ní ẹ̀mí èṣù ni a mú wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ lé àwọn ẹ̀mí èṣù náà jáde. A sì mú gbogbo àwọn ọlọ́kùnrùn láradá. Kí èyí tí a ti sọ láti ẹnu wòlíì Isaiah lè ṣẹ pé: “Òun tìkára rẹ̀ gbà àìlera wa, ó sì ń ru ààrùn wa.” Nígbà tí Jesu rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tó yí i ká, ó pàṣẹ pé kí wọ́n rékọjá sí òdìkejì adágún. Olùkọ́ òfin kan sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí fún un pé, “Olùkọ́, èmi ó má tọ̀ ọ́ lẹ́yìn níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ.” Jesu dá lóhùn pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ni ìtẹ́; ṣùgbọ́n Ọmọ Ènìyàn kò ní ibi tí yóò fi orí rẹ̀ lé.” Ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mìíràn sì wí fún un pé, “Olúwa, kọ́kọ́ jẹ́ kí èmi kí ó kọ́ lọ sìnkú baba mi ná.” Ṣùgbọ́n Jesu wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn, sì jẹ́ kí àwọn òkú kí ó máa sin òkú ara wọn.” Nígbà náà ni ó bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀lé e. Ní àìròtẹ́lẹ̀, ìjì líle dìde lórí Òkun tó bẹ́ẹ̀ tí rírú omi fi bò ọkọ̀ náà mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n Jesu ń sùn. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn jí i, wọ́n wí pe, “Olúwa, gbà wá! Àwa yóò rì!” Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré. Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń bẹ̀rù?” Nígbà náà ní ó dìde dúró, ó sì bá ìjì àti rírú Òkun náà wí, gbogbo rẹ̀ sì parọ́rọ́. Ṣùgbọ́n ẹnu yà àwọn ọkùnrin náà, wọ́n sì béèrè pé, “Irú ènìyàn wo ni èyí? Kódà ìjì líle àti rírú omi Òkun gbọ́ tirẹ̀?” Nígbà ti ó sì dé apá kejì ní ilẹ̀ àwọn ara Gadara, àwọn ọkùnrin méjì ẹlẹ́mìí èṣù ti inú ibojì wá pàdé rẹ̀. Wọn rorò gidigidi tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò le kọjá ní ọ̀nà ibẹ̀. Wọ́n kígbe lóhùn rara wí pé, “Kí ní ṣe tàwa tìrẹ, Ìwọ Ọmọ Ọlọ́run? Ìwọ ha wá láti dá wa lóró ṣáájú ọjọ́ tí a yàn náà?” Agbo ẹlẹ́dẹ̀ ńlá tí ń jẹ ń bẹ ní ọ̀nà jíjìn díẹ̀ sí wọn Àwọn ẹ̀mí èṣù náà bẹ̀ Jesu wí pé, “Bí ìwọ bá lé wa jáde, jẹ́ kí àwa kí ó lọ sínú agbo ẹlẹ́dẹ̀ yìí.” Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ!” Nígbà tí wọn sì jáde, wọn lọ sínú agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà; sì wò ó, gbogbo agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà sì rọ́ gììrì sọ̀kalẹ̀ bèbè odò bọ́ sínú Òkun, wọ́n sì ṣègbé nínú omi. Àwọn ẹni tí ń ṣọ wọn sì sá, wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n lọ sí ìlú, wọ́n ròyìn ohun gbogbo, àti ohun tí a ṣe fún àwọn ẹlẹ́mìí èṣù. Nígbà náà ni gbogbo ará ìlú náà sì jáde wá í pàdé Jesu. Nígbà tí wọ́n sì rí i, wọ́n bẹ̀ ẹ́, kí ó lọ kúrò ní agbègbè wọn.