Mat 7:7-12
Mat 7:7-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bère, a o si fifun nyin; wá kiri, ẹnyin o si ri; kànkun, a o si ṣí i silẹ fun nyin. Nitori ẹnikẹni ti o bère nri gbà; ẹniti o ba si wá kiri nri: ẹniti o ba si nkànkun, li a o ṣí i silẹ fun. Tabi ọkunrin wo ni ti mbẹ ninu nyin, bi ọmọ rẹ̀ bère akara, ti o jẹ fi okuta fun u? Tabi bi o bère ẹja, ti o jẹ fun u li ejò? Njẹ bi ẹnyin ti iṣe enia buburu, ba mọ̀ bi ã ti fi ẹ̀bun rere fun awọn ọmọ nyin, melomelo ni Baba nyin ti mbẹ li ọrun yio fi ohun rere fun awọn ti o bère lọwọ rẹ̀? Nitorina gbogbo ohunkohun ti ẹnyin ba nfẹ ki enia ki o ṣe si nyin, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o si ṣe si wọn gẹgẹ; nitori eyi li ofin ati awọn woli.
Mat 7:7-12 Yoruba Bible (YCE)
“Ẹ bèèrè, a óo sì fi fun yín. Ẹ wá kiri, ẹ óo sì rí. Ẹ kanlẹ̀kùn, a óo sì ṣí i fun yín. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá bèèrè ni ó ń rí gbà; ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wá nǹkan kiri ni ó ń rí i; ẹnikẹ́ni tí ó bá ń kanlẹ̀kùn ni à ń ṣí i sílẹ̀ fún. Ta ni ninu yín, tí ọmọ rẹ̀ bá bèèrè àkàrà, tí ó jẹ́ fún un ní òkúta? Tabi tí ó bà bèèrè ẹja, tí ó jẹ́ fún un ní ejò? Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin tí ẹ burú báyìí bá mọ̀ bí a tií fi ohun tí ó dára fún ọmọ yín, mélòó-mélòó ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóo fi ohun rere fún àwọn tí ó bá bèèrè lọ́dọ̀ rẹ̀. “Nítorí náà, gbogbo bí ẹ bá ti fẹ́ kí eniyan ṣe si yín, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ̀yin náà ṣe sí wọn. Kókó Òfin ati ọ̀rọ̀ àwọn wolii nìyí.
Mat 7:7-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Béèrè, a ó sì fi fún yín; wá kiri, ẹ̀yin yóò sì rí; kànkùn, a ó sì ṣí i sílẹ̀ fún yín. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó béèrè ń rí gbà, ẹni tí ó bá sì wà kiri ń rí, ẹni bá sì kànkùn ni a yóò ṣi sílẹ̀ fún. “Ta ni ọkùnrin náà tí ń bẹ nínú yín, bí ọmọ rẹ̀ béèrè àkàrà, tí yóò jẹ́ fi òkúta fún un? Tàbí bí ó béèrè ẹja, tí yóò jẹ́ fún un ní ejò? Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin tí í ṣe ènìyàn búburú bá mọ̀ bí a ti í fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòó mélòó ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ohun rere fún àwọn tí ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀? Nítorí náà, nínú gbogbo ohunkóhun ti ẹ̀yin bá ń fẹ́ kí ènìyàn kí ó ṣe sí yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó ṣe sí wọn gẹ́gẹ́; nítorí èyí ni òfin àti àwọn wòlíì.