Mat 7:4-5
Mat 7:4-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Tabi iwọ o ti ṣe wi fun arakunrin rẹ pe, Jẹ ki emi yọ ẹrún igi ti mbẹ li oju rẹ, si wò o, ìti igi mbẹ li oju iwọ tikararẹ. Iwọ agabagebe, tètekọ́ yọ ìti igi jade kuro li oju ara rẹ na, nigbana ni iwọ o si to riran gbangba lati yọ ẹrún igi ti mbẹ li oju arakunrin rẹ kuro.
Mat 7:4-5 Yoruba Bible (YCE)
Tabi báwo ni o ṣe lè wí fún arakunrin rẹ pé, ‘Jẹ́ kí ń bá ọ yọ ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú rẹ,’ nígbà tí ó jẹ́ pé ìtì igi wà ní ojú tìrẹ alára? Ìwọ a-rí-tẹni-mọ̀-ọ́n-wí, kọ́kọ́ yọ ìtì igi tí ó wà lójú rẹ kúrò; nígbà náà o óo ríran kedere láti lè yọ ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú arakunrin rẹ.
Mat 7:4-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Tàbí ìwọ ó ti ṣe wí fún arákùnrin rẹ pé, ‘Jẹ́ kí èmi yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ ni ojú rẹ,’ sì wò ó ìtì igi ń bẹ ní ojú ìwọ tìkára rẹ. Ìwọ àgàbàgebè, tètè kọ́ yọ ìtì igi jáde kúrò ní ojú ara rẹ ná, nígbà náà ni ìwọ yóò sì tó ríran kedere láti yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ kúrò.