Mat 7:26-27
Mat 7:26-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnikẹni ti o ba si gbọ́ ọ̀rọ temi wọnyi, ti kò si ṣe wọn, on li emi o fi wé aṣiwere enia kan ti o kọ́ ile rẹ̀ si ori iyanrin: Òjo si rọ̀, ikún omi si de, afẹfẹ si fẹ́, nwọn si bìlu ile na, o si wó; iwó rẹ̀ si pọ̀ jọjọ.
Pín
Kà Mat 7Mat 7:26-27 Yoruba Bible (YCE)
“Ṣugbọn ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yìí, tí kò bá fi ṣe ìwà hù, ó dàbí òmùgọ̀ eniyan kan tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí iyanrìn. Òjò rọ̀, àgbàrá dé, ẹ̀fúùfù sì kọlu ilé náà. Ó bá wó! Wíwó rẹ̀ sì bani lẹ́rù lọpọlọpọ.”
Pín
Kà Mat 7Mat 7:26-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí kò bá sì ṣe wọ́n, òun ni èmi yóò fiwé aṣiwèrè ènìyàn kan tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí iyanrìn. Òjò sì rọ̀, ìkún omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sì bì lu ilé náà, ilé náà sì wó; wíwó rẹ̀ sì pọ̀ jọjọ.”
Pín
Kà Mat 7