Mat 7:24-28
Mat 7:24-28 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina ẹnikẹni ti o ba gbọ́ ọ̀rọ temi wọnyi, ti o ba si ṣe wọn, emi o fi wé ọlọ́gbọn enia kan, ti o kọ́ ile rẹ̀ si ori àpata: Òjo si rọ̀, ikún omi si dé, afẹfẹ si fẹ́ nwọn si bìlu ile na; ko si wó, nitoriti a fi ipilẹ rẹ̀ sọlẹ lori àpata. Ẹnikẹni ti o ba si gbọ́ ọ̀rọ temi wọnyi, ti kò si ṣe wọn, on li emi o fi wé aṣiwere enia kan ti o kọ́ ile rẹ̀ si ori iyanrin: Òjo si rọ̀, ikún omi si de, afẹfẹ si fẹ́, nwọn si bìlu ile na, o si wó; iwó rẹ̀ si pọ̀ jọjọ. Nigbati o si ṣe ti Jesu pari gbogbo òrọ wọnyi tan, ẹnu yà gbogbo enia si ẹkọ́ rẹ̀
Mat 7:24-28 Yoruba Bible (YCE)
“Nítorí náà, gbogbo ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yìí, tí ó bá fi ṣe ìwà hù dàbí ọlọ́gbọ́n eniyan kan, tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta. Òjò rọ̀; àgbàrá dé, ẹ̀fúùfù sì kọlu ilé náà; ṣugbọn kò wó, nítorí ìpìlẹ̀ rẹ̀ wà lórí àpáta. “Ṣugbọn ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yìí, tí kò bá fi ṣe ìwà hù, ó dàbí òmùgọ̀ eniyan kan tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí iyanrìn. Òjò rọ̀, àgbàrá dé, ẹ̀fúùfù sì kọlu ilé náà. Ó bá wó! Wíwó rẹ̀ sì bani lẹ́rù lọpọlọpọ.” Nígbà tí Jesu parí àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi, ẹnu ya àwọn eniyan sí ẹ̀kọ́ rẹ̀
Mat 7:24-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí ó bá sì ṣe wọn, èmi ó fiwé ọlọ́gbọ́n ènìyàn kan, ti ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí àpáta. Òjò sì rọ̀, ìkún omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sí bì lu ilé náà; síbẹ̀síbẹ̀ náà kò sì wó, nítorí tí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí kò bá sì ṣe wọ́n, òun ni èmi yóò fiwé aṣiwèrè ènìyàn kan tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí iyanrìn. Òjò sì rọ̀, ìkún omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sì bì lu ilé náà, ilé náà sì wó; wíwó rẹ̀ sì pọ̀ jọjọ.” Nígbà tí Jesu sì parí sísọ nǹkan wọ̀nyí, ẹnu ya àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn sí ẹ̀kọ́ rẹ̀